ORÍ 13
“Mo Nífẹ̀ẹ́ Baba”
1, 2. Kí ni àpọ́sítélì Jòhánù jẹ́ ká mọ̀ nípa alẹ́ táwọn àpọ́sítélì Jésù lò kẹ́yìn pẹ̀lú rẹ̀?
BÀBÁ àgbàlagbà kan ki kálàmù rẹ̀ bọnú yíǹkì, ọ̀rọ̀ pọ̀ níkùn rẹ̀ tó fẹ́ kọ sílẹ̀. Jòhánù lorúkọ bàbá náà, òun nìkan ló kù láàyè lára àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún lásìkò yìí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ lálẹ́ mánigbàgbé kan ní nǹkan tó lé ní ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn sí ìgbà yẹn, ìyẹn alẹ́ ọjọ́ tóun àtàwọn àpọ́sítélì yòókù lò kẹ́yìn pẹ̀lú Jésù kó tó kú. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tó ran Jòhánù lọ́wọ́ ló fi lè rántí kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó sì kọ wọ́n sílẹ̀.
2 Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, Jésù là á mọ́lẹ̀ pé wọ́n máa tó pa òun. Jòhánù nìkan ló sọ ìdí tí Jésù fi sọ pé òun á fara mọ́ ikú oró yẹn, ó sọ pé: “Nítorí kí ayé lè mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ Baba, àní gẹ́gẹ́ bí Baba ti fi àṣẹ fún mi láti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni mo ń ṣe. Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a lọ kúrò ní ìhín.”—Jòhánù 14:31.
3. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Bàbá òun?
3 “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba.” Kò sóhun tó ṣe pàtàkì lójú Jésù tó ìfẹ́ tó ní sí Bàbá rẹ̀. Kì í ṣe pé ó máa ń sábà sọ gbólóhùn yẹn jáde o. Kódà Jòhánù 14:31 ni ibì kan ṣoṣo tá a ti rí i nínú Bíbélì tí Jésù ti sọ ní tààràtà pé òun nífẹ̀ẹ́ Bàbá òun. Ọ̀nà tó gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀ ló fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀. Lójúmọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ló máa ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bí Jésù ṣe jẹ́ onígboyà, tó jẹ́ onígbọràn tó sì ní ìfaradà fi hàn pé lóòótọ́ ló nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Ó hàn pé ìfẹ́ ló mú kó ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀.
4, 5. Irú ìfẹ́ wo ni Bíbélì sọ nípa rẹ̀, kí la sì lè sọ nípa ìfẹ́ tí Jésù ní fún Jèhófà?
4 Lónìí ọ̀pọ̀ ló rò pé èèyàn tó bá rọ̀ ló lè ní ìfẹ́. Ó lè jẹ́ pé ohun tó ń wá sí wọn lọ́kàn ni àwọn ewì ìfẹ́ àtàwọn orin ìfẹ́, tàbí ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré kan tó dá lórí ìfẹ́. Bíbélì pẹ̀lú sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ láàárín ọkùnrin àti obìnrin, ó kàn jẹ́ pé ó sọ ọ́ lọ́nà tó níyì, tó yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́ lónìí ni. (Òwe 5:15-21) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ ìfẹ́ kan tó yàtọ̀ sí èyí tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí. Ìfẹ́ eléyìí kì í ṣe ọ̀kan tó kó séèyàn lórí tàbí ìfẹ́ tí kì í tọ́jọ́ táwọn èèyàn ń pariwo pé àwọn ní síra àwọn, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ìfẹ́ orí ahọ́n lásán. Ìfẹ́ tá à ń wí yìí kan ọkàn àti èrò inú èèyàn. Inú ọkàn lọ́hùn-un ni irú ìfẹ́ yìí ti máa ń wá, ó máa ń dá lórí ìlànà tó ga, ó sì máa ń múni ṣe ohun tí ń gbéni ró. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ìfẹ́ kì í kùnà láé.”—1 Kọ́ríńtì 13:8.
5 Nínú gbogbo ẹ̀dá tó tíì gbé lórí ilẹ̀ ayé yìí rí, kò sẹ́ni tó tíì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó Jésù. Yàtọ̀ sí Jésù fúnra rẹ̀, kò tíì sí ẹlòmíì tó tẹ̀ lé àṣẹ tí Jésù sọ pé ó ṣe pàtàkì jù, èyí tó sọ pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.” (Máàkù 12:30) Báwo ni Jésù ṣe nírú ìfẹ́ yẹn? Báwo ló ṣe ṣe é tí ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run ò fi tutù ní gbogbo ìgbà tó fi wà láyé? Báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
Ìdè Ìfẹ́ Tó Tíì Pẹ́ Jù Tó sì Lágbára Jù
6, 7. Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Òwe 8:22-31 ṣàpèjúwe rẹ̀, pé kì í kàn án ṣe ànímọ́ tó ń jẹ́ ọgbọ́n lásán?
6 Ǹjẹ́ iṣẹ́ kan ti pa ìwọ àti ọ̀rẹ́ rẹ kan pọ̀ rí tó jẹ́ pé ìgbà tẹ́ ẹ fi máa parí iṣẹ́ yẹn, ẹ ti mọwọ́ ara yín ju ti tẹ́lẹ̀ tẹ́ ẹ sì ti wá dọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́? Ìrírí yẹn á jẹ́ kó o lè lóye irú ìfẹ́ tó wà láàárín Jèhófà àti Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo. Ó ti tó bí ìgbà mélòó kan tá a ti mẹ́nu ba Òwe 8:30, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ká túbọ̀ gbé ẹsẹ yẹn yẹ̀ wò pẹ̀lú ẹsẹ tó yí i ká. Ní ẹsẹ 22 títí dé ẹsẹ 31, a rí bí òǹkọ̀wé yìí ṣe ṣàpèjúwe ọgbọ́n bíi pé ó jẹ́ ẹnì kan. Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí tọ́ka sí?
7 Ní ẹsẹ 22, ọgbọ́n sọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ni ó ṣẹ̀dá mi gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọ̀nà rẹ̀, ìbẹ̀rẹ̀pàá àwọn àṣeyọrí rẹ̀ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.” Nǹkan míì ní láti wà nínú ọ̀rọ̀ yìí, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ọgbọ́n ṣe lè wá di ohun tí Ọlọ́run “ṣẹ̀dá.” Ọgbọ́n ò níbẹ̀rẹ̀ torí Jèhófà fúnra rẹ̀ ò níbẹ̀rẹ̀ kò sí sígbà tí Jèhófà ò gbọ́n. (Sáàmù 90:2) Àmọ́, Ọmọ Ọlọ́run ni “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” Dídá ni Ọlọ́run dá a; òun ni ìbẹ̀rẹ̀pàá àwọn àṣeyọrí rẹ̀. (Kólósè 1:15) Ọmọ ti wà ṣáájú ayé àti ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Òwe inú Bíbélì ṣe sọ. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òun ni Agbẹnusọ fún Ọlọ́run, àní òun lẹni tó jẹ́ ká rí bí ọgbọ́n Jèhófà ṣe pé pérépéré tó.—Jòhánù 1:1.
8. Kí ni Ọmọ ṣe kó tó wá sáyé bí èèyàn, kí la sì lè ronú nípa rẹ̀ bá a bá rí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá kan tó jọ wá lójú?
8 Kí ni Ọmọ Ọlọ́run ń ṣe ni gbogbo àìlóǹkà ọdún tó fi wà lọ́run kó tó wá sáyé? Ẹsẹ 30 sọ fún wa pé ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́.” Kí nìyẹn wá túmọ̀ sí? Kólósè 1:16 ṣàlàyé pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé . . . Gbogbo ohun mìíràn ni a dá nípasẹ̀ rẹ̀ àti fún un.” Nípa báyìí, Jèhófà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá lo Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ Àgbà Òṣìṣẹ́ láti dá gbogbo ohun mìíràn, látorí àwọn áńgẹ́lì tó wà lájùlé ọ̀run dórí àgbáyé wa tó lọ salalu, títí kan orí ilẹ̀ ayé wa tó kún fún onírúurú ewéko àti ẹranko tó ń ṣeni ní kàyéfì, kó tó wá kan ti olúborí gbogbo ìṣẹ̀dá lórí ilẹ̀ ayé ńbí, ìyẹn àwa èèyàn. Láwọn ọ̀nà kan, a lè fi ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó wà láàárín Bàbá àti Ọmọ yìí wé ọ̀rọ̀ àárín ayàwòrán ilé kan tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú mọlémọlé tàbí agbaṣẹ́ṣe kan tó mọ béèyàn ṣe ń sọ àwòrán tí ayàwòrán ilé kan fi ọpọlọ pípé yà di ilé àrímáleèlọ. Bá a bá rí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá kan tó jọ wá lójú gan-an, Jèhófà tó jẹ́ Ayàwòrán tó ju ayàwòrán lọ là ń fìyìn fún. (Sáàmù 19:1) Bákan náà, èyí tún lè rán wa létí pé tipẹ́tipẹ́ ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀ aláyọ̀ ti wà láàárín Ẹlẹ́dàá àti “àgbà òṣìṣẹ́” rẹ̀.
9, 10. (a) Kí ló jẹ́ kí ìdè ìfẹ́ tó wà láàárín Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ lágbára? (b) Kí ló lè mú ìdè ìfẹ́ tó wà láàárín ìwọ àti Bàbá rẹ ọ̀run lágbára sí i?
9 Báwọn èèyàn aláìpé méjì bá jọ ṣiṣẹ́ pọ̀, kì í rọrùn láti jọ wà lálàáfíà nígbà míì. Kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀! Àìmọye ọdún ni Ọmọ fi bá Bàbá rẹ̀ ṣiṣẹ́, ńṣe ló sì “ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.” (Òwe 8:30) Bó ṣe rí nìyẹn, inú rẹ̀ máa ń dùn láti máa wà pẹ̀lú Bàbá rẹ̀, ńṣe ni inú Bàbá náà sì máa ń dùn láti wà pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bá a ti lè retí, ńṣe ni Ọmọ yìí ń dà bíi Bàbá rẹ̀ sí i, ó sì ń kọ́ bó ṣe lè máa fi ànímọ́ Ọlọ́run ṣèwà hù. Abájọ tí okùn ìfẹ́ àárín Ọmọ àti Bàbá ṣe yi tó bẹ́ẹ̀! Ó tọ́ nígbà náà ká sọ pé ìdè yẹn ni ìdè ìfẹ́ tó tíì pẹ́ jù lọ tó sì lágbára ju lọ ní gbogbo ayé àtọ̀run.
10 Kí nìyẹn wá túmọ̀ sí fún wa? O lè máa rò pé ìwọ ò lè nírú àjọṣe yẹn pẹ̀lú Jèhófà. Òótọ́ ni pé kò sẹ́ni tó lè dépò gíga tí Ọmọ wà. Síbẹ̀ a ṣì ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ kan. Rántí pé ohun tó mú kí Jésù sún mọ́ Bàbá rẹ̀ ni ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú Rẹ̀. Jèhófà ti fìfẹ́ pe àwa náà pé ká wá di “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” òun. (1 Kọ́ríńtì 3:9) Bá a ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lóde ẹ̀rí, a gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn pé alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Ọlọ́run ni wá. Nípa báyìí, ìdè ìfẹ́ tó wà láàárín àwa àti Jèhófà á lè máa lágbára sí i. Ǹjẹ́ àǹfààní míì wà tá a lè ní tó jùyẹn lọ?
Bí Jésù Ṣe Mú Kí Ìfẹ́ Tó Ní fún Jèhófà Lágbára
11-13. (a) Kí nìdí tó fi dáa ká wo ìfẹ́ bí ohun alààyè, báwo sì ni Jésù ṣe mú kí ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà lágbára nígbà tó wà lọ́mọdé? (b) Ọ̀nà wo ni Ọmọ Ọlọ́run gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ sí gbígba ìdálẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà kó tó wá sáyé àti nígbà tó wà láyé?
11 Lọ́pọ̀ ọ̀nà, ó máa ń dáa láti máa wo ìfẹ́ tó wà lọ́kàn wa bí ohun alààyè. Ó pọn dandan kéèyàn máa ṣìkẹ́ ìfẹ́, kéèyàn sì máa ṣe ohun tó máa mú kó lè dàgbà dáadáa kó sì lágbára gẹ́gẹ́ bí òdòdó téèyàn ń bomi rin téèyàn sì ń tọ́jú dáadáa. Béèyàn ò bá ṣú já a, téèyàn ò jẹ́ kó rí omi tó tó, ńṣe ló máa rọ jọwọrọ tó sì máa kú. Jésù ò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìfẹ́ tó ní sí Jèhófà. Nígbà tó wà láyé, ó rí i dájú pé ìfẹ́ náà ń lágbára, ó sì ń jinlẹ̀ sí i. Jẹ́ ká wo bó ṣe rí bẹ́ẹ̀.
12 Tún rántí ohun kan tó ṣẹlẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù nígbà tí Jésù sọ bí àárín òun àti Jèhófà ṣe rí. Nígbà táwọn òbí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dààmú, ó sọ fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ní láti máa wá mi? Ṣé ẹ kò mọ̀ pé èmi gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?” (Lúùkù 2:49) Ó hàn gbangba pé ní gbogbo ìgbà tí Jésù fi wà lọ́mọdé, kò rántí pé òun ti wà lọ́run rí. Síbẹ̀ ìfẹ́ tó ní sí Jèhófà lágbára gan-an. Ó mọ̀ pé béèyàn ṣe ń jọ́sìn Ọlọ́run máa ń fi bí ìfẹ́ yẹn ṣe lágbára tó hàn. Nítorí náà, kò sí ibòmíì láyé tó wu Jésù bí ilé Bàbá rẹ̀, ìyẹn ibi ìjọsìn mímọ́. Ńṣe ló máa ń wù ú láti wà níbẹ̀ kì í sì í wù ú láti fibẹ̀ sílẹ̀. Kì í lọ síbẹ̀ lọ wòran. Ní gbogbo ìgbà ló máa ń wù ú láti mọ̀ sí i nípa Jèhófà, ó sì máa ń fẹ́ sọ ohun tó mọ̀ nípa rẹ̀ fáwọn ẹlòmíì. Kì í ṣe ìgbà tó di ẹni ọdún méjìlá ló tó bẹ̀rẹ̀ sí í wù ú, kò sì yéé wù ú bó ṣe ń dàgbà sí i.
13 Kí Ọmọ Ọlọ́run tó wá sáyé bí èèyàn ló ti fìtara kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Aísáyà 50:4-6, jẹ́ ká mọ̀ pé àkànṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ ni Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀ nípa iṣẹ́ tó máa ṣe gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ní nínú mímọ̀ nípa ìṣòro tó máa bá Ẹni Àmì Òróró Jèhófà, Ọmọ náà gbẹ̀kọ́ láìjáfara. Nígbà tó sì yá tí Jésù wá sáyé, tó dàgbà di géńdé, kò jáfara láti lọ sínú ilé Bàbá rẹ̀ kó bàa lè jọ́sìn kó sì lọ́wọ́ nínú fífi ẹ̀kọ́ tí Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn gbà nílé òun kọ́ni. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi ròyìn nípa bí Jésù kì í ṣe pa lílọ sí tẹ́ńpìlì àti sínágọ́gù jẹ. (Lúùkù 4:16; 19:47) Báwa náà ò bá fẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà kú tá a sì fẹ́ kó máa jinlẹ̀ sí i, a ò gbọ́dọ̀ ṣọ̀lẹ tó bá dọ̀rọ̀ lílọ sáwọn ìpàdé ìjọ níbi tá a ti ń jọ́sìn Jèhófà, tá a ti ń gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ tá a sì ti ń fi hàn pé a moore.
14, 15. (a) Kí nìdí tí Jésù fi máa ń fẹ́ dá wà nígbà míì? (b) Báwo ni àwọn àdúrà tí Jésù gbà ṣe fi hàn pé ó ní ọ̀wọ̀ fún Bàbá rẹ̀ àti pé àárín àwọn méjèèjì gún?
14 Jésù tún jẹ́ kí ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà lágbára nípa gbígbàdúrà déédéé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni bí ọ̀rẹ́ ni àti pé ara rẹ̀ yọ̀ mọ́ èèyàn, ó yẹ ká kíyè sí i pé ó fọwọ́ pàtàkì mú wíwá àkókò láti dá wà. Bí àpẹẹrẹ, Lúùkù 5:16 sọ pé: “Ó ń bá a lọ ní wíwà ní ipò àdádó ní àwọn aṣálẹ̀, ó sì ń gbàdúrà.” Bákan náà, Mátíù 14:23 sọ pé: “Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, lẹ́yìn rírán àwọn ogunlọ́gọ̀ náà lọ, ó gun òkè ńlá lọ ní òun nìkan láti gbàdúrà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ti lọ, ó wà níbẹ̀ ní òun nìkan ṣoṣo.” Láwọn àsìkò táwọn ẹsẹ Bíbélì yìí mẹ́nu bà àti làwọn àkókò mìíràn, Jésù fẹ́ láti dá wà lóun nìkan kì í ṣe nítorí pé ó ya àṣo tí kì í bá èèyàn ṣe tàbí ẹni tó kórìíra àtiwà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nítorí pé ó fẹ́ dá wà lóun nìkan pẹ̀lú Jèhófà kó bàa lè ráyè sọ̀rọ̀ fàlàlà pẹ̀lú Bàbá rẹ̀ nínú àdúrà.
15 Bí Jésù bá ń gbàdúrà, nígbà míì ó máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “Ábà, Baba.” (Máàkù 14:36) Lọ́jọ́ Jésù, ọ̀rọ̀ tí ọmọ kan máa ń fi pe “baba” rẹ̀ ni “Ábà,” ó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n máa ń lò nínú ìdílé. Ó wà lára ọ̀rọ̀ tọ́mọ kan máa kọ́kọ́ mọ̀-ọ́n pè. Síbẹ̀ kì í ṣe ọ̀rọ̀ agọ̀, gbólóhùn tó fi ọ̀wọ̀ hàn ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ká rí bí àárín Ọmọ àti Bàbá rẹ̀ ọ̀wọ́n ṣe gún régé tó, ó tún fi hàn wá pé Ọmọ ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún àṣẹ Jèhófà bàbá rẹ̀. Gbogbo àdúrà tí Jésù gbà tó wà lákọọ́lẹ̀ ló fi bí àárín òun àti Bàbá rẹ̀ ṣe gún régé tó hàn, ó sì jẹ́ ká rí bí ọ̀wọ̀ tó ní fún un ṣe jinlẹ̀ tó. Bí àpẹẹrẹ, nínú Jòhánù orí 17, àpọ́sítélì Jòhánù ṣàkọsílẹ̀ àdúrà àtọkànwá tí ò tíì séyìí tó gùn tó o, tí Jésù gbà ní òru ọjọ́ tó lò kẹ́yìn. Ká sòótọ́, kóríyá ló máa ń jẹ́ fún wa láti gbé àdúrà yẹn yẹ̀ wò, ó sì ṣe pàtàkì ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bí Jésù ṣe gba àdúrà yẹn—kì í ṣe pé ká wá máa ṣàtúnsọ àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù lò là ń sọ o, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ká wo bá a ṣe lè gbàdúrà sí Bàbá wa ọ̀run látọkànwá nígbà yòówù tá a bá lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run wà láàyè kó sì lágbára.
16, 17. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu pé òun nífẹ̀ẹ́ Bàbá òun? (b) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà ṣàpèjúwe ìwà ọ̀làwọ́ Bàbá rẹ̀?
16 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, Jésù ò máa tún gbólóhùn náà, “Mo nífẹ̀ẹ́ Bàbá” sọ lásọtúnsọ. Ṣùgbọ́n ṣá, lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń jẹ́ kó hàn nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ Bàbá òun. Lọ́nà wo? Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 11:25) Nígbà tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ ìsọ̀rí 2 nínú ìwé yìí, a rí i pé Jésù fẹ́ràn láti máa yin Bàbá rẹ̀ nípa bó ṣe máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ó fi Jèhófà wé bàbá kan tó ti ń wọ̀nà láti dárí ji ọmọ rẹ̀ tó ti yàyàkuyà, bó ṣe ń dúró de ọ̀dọ́kùnrin tó ti ronú pìwà dà yẹn, tó tajú kánrí i lókèèrè, ó sáré lọ pàdé rẹ̀ ó sì fọwọ́ gbá a mọ́ra. (Lúùkù 15:20) Ta ni orí rẹ̀ ò ní wú bó bá ka àkọsílẹ̀ yẹn, níbi tí Jésù ti ṣàpèjúwe bí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ṣe jinlẹ̀ tó àti bó ṣe múra tán láti dárí jì wá?
17 Lóòrèkóòrè ni Jésù máa ń yin Bàbá rẹ̀ nítorí bó ṣe jẹ́ ọ̀làwọ́. Ó fi àwọn òbí ṣàpẹẹrẹ, pé bí àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìpé bá lè fúnni ní nǹkan, ó dájú pé Bàbá wa ọ̀run á fún wa ní ìwọ̀n ẹ̀mí mímọ́ tá a nílò. (Lúùkù 11:13) Jésù sì tún sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tí ìwà ọ̀làwọ́ mú kí Bàbá nawọ́ rẹ̀ sí wa. Ó sì sọ bóun ṣe ń retí àkókò tí Bàbá òun máa dá òun padà sí àyè tóun wà tẹ́lẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́run. (Jòhánù 14:28; 17:5) Ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa ìrètí tí Jèhófà fún “agbo kékeré” ti Kristi, ìyẹn gbígbé lọ́run àti ṣíṣàkóso pẹ̀lú Mèsáyà Ọba. (Lúùkù 12:32; Jòhánù 14:2) Ó sì fi ìrètí gbígbé nínú Párádísè tu ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ń kú lọ nínú. (Lúùkù 23:43) Ó dájú pé bí Jésù ṣe máa ń sọ̀rọ̀ ìwà ọ̀làwọ́ Bàbá rẹ̀ láwọn ọ̀nà tá a mẹ́nu bà yìí mú kí ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà lágbára gan-an. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ló ti wá rí i pé kò sí nǹkan míì tó lè mú kí ìfẹ́ téèyàn ní sí Jèhófà tàbí ìgbàgbọ́ téèyàn ní nínú rẹ̀ jinlẹ̀ sí i ju pé kéèyàn máa sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, kéèyàn sì máa sọ nípa àwọn ìrètí tó fi síwájú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Ṣé Ìwọ Náà Á Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bíi ti Jésù?
18. Ọ̀nà wo ló ṣe pàtàkì jù lọ tá a lè máa gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kí sì nìdí?
18 Nínú gbogbo ọ̀nà tó yẹ ká máa gbà tọ Jésù lẹ́yìn, kò sí ìkankan tó ṣe pàtàkì tó èyí pé: Ká fi gbogbo ọkàn-àyà wa, gbogbo ọkàn wa, gbogbo èrò inú wa àti gbogbo okun wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Lúùkù 10:27) Kì í ṣe bí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ṣe lágbára lọ́kàn wa tó nìkan la fi ń díwọ̀n ìfẹ́ ọ̀hún, ohun tá a tún fi ń díwọ̀n rẹ̀ ni bó bá ṣe ń hàn nínú ìṣe wa tó. Jésù ò kàn jókòó gẹlẹtẹ kó wá máa sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ Bàbá òun, bẹ́ẹ̀ ni kò kàn máa sọ pé, “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba.” Ohun tó sọ ni pé: “Nítorí kí ayé lè mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ Baba, àní gẹ́gẹ́ bí Baba ti fi àṣẹ fún mi láti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni mo ń ṣe.” (Jòhánù 14:31) Ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan gbogbo ẹ̀dá èèyàn ni pé bí kì í bá ṣe pé wọ́n ń rí nǹkan kan gbà lọ́wọ́ Jèhófà, wọn ò ní sìn ín. (Jóòbù 2:4, 5) Kí Jésù lè pa Sátánì lẹ́nu mọ́ lórí gbogbo ìbàjẹ́ tó ń ṣe, Jésù ṣe ohun tó máa jẹ́ kí gbogbo ayé mọ̀ pé ìfẹ́ tí òun ní sí Bàbá òun ò láfiwé. Ó ṣègbọràn títí dópin, kódà ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ dí i. Ṣé wàá tẹ̀ lé Jésù? Ṣé wàá jẹ́ kí gbogbo ayé mọ̀ pé lóòótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run?
19, 20. (a) Nítorí àwọn ìdí pàtàkì wo la ṣe ní láti máa lọ sípàdé déédéé? (b) Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ìdákẹ́kọ̀ọ́, àṣàrò àti àdúrà?
19 Ká tó lè bá Jèhófà rẹ́, ó pọn dandan pé ká nírú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀. Torí náà, Jèhófà ti ṣètò pé ká sin òun lọ́nà tó jẹ́ pé ìfẹ́ tá a ní fún Un á fi lè máa jinlẹ̀ sí i, táá sì lè máa lágbára sí i. Nígbà tó o bá lọ sípàdé, gbìyànjú láti máa rántí pé torí àtilọ jọ́sìn Ọlọ́run lo ṣe wà níbẹ̀. Ara ìjọsìn náà ni dídarapọ̀ nínú àdúrà àtọkànwá, jíjùmọ̀ kọ orin ìyìn, fífetísílẹ̀ dáadáa àti lílóhùn sí apá tó bá yẹ kí àwùjọ lóhùn sí. Irú àwọn ìpàdé yìí sì máa ń jẹ́ ká lè gba àwọn ará wa níyànjú. (Hébérù 10:24, 25) Bó o bá ń jọ́sìn Jèhófà déédéé láwọn ìpàdé wa, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run máa jinlẹ̀ sí i.
20 Bákan náà, ó yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú ìdákẹ́kọ̀ọ́, ṣíṣàṣàrò àti gbígbàdúrà. Ṣe ló yẹ kó o máa rí àwọn ọ̀nà wọ̀nyí bí àkókò tó yẹ kó o fi dá wà pẹ̀lú Jèhófà. Ńṣe ni Jèhófà ń bá ọ sọ̀rọ̀ nígbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà lákọọ́lẹ̀ tó o sì ń ṣàṣàrò lé e lórí. Ńṣe lò ń sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún un nígbàkigbà tó o bá ń gbàdúrà. Má ṣe gbàgbé pé àdúrà ju kéèyàn kàn máa béèrè nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run lọ o. Àdúrà tún jẹ́ àǹfààní tó o ní láti sọ fún Jèhófà pé ó ṣeun nítorí àwọn ìbùkún tó o ti rí gbà látọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì tún jẹ́ àkókò láti yìn ín nítorí àwọn iṣẹ́ àrà ọwọ́ rẹ̀. (Sáàmù 146:1) Láfikún sí i, ọ̀nà tó dáa jù lọ láti sọ fún Jèhófà pé ó ṣeun àti láti jẹ́ kó mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni nípa fífi ìtara àti ayọ̀ yìn ín ní gbangba.
21. Báwo ni nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà ti ṣe kókó tó, kí la sì máa jíròrò ní àwọn orí tó wà níwájú?
21 Àfi bó o bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run nìkan lo máa tó lè ní ayọ̀ tó máa bá ọ kalẹ́. Ohun tí Ádámù àti Éfà nílò nìyẹn tí wọ́n á fi lè jẹ́ onígbọràn, àmọ́ wọn ò ní in. Bó o bá máa borí àdánwò ìgbàgbọ́ èyíkéyìí, bó o bá máa kọ ìdẹwò èyíkéyìí tàbí bó o bá máa lè fara da ìṣòro yòówù kó yọjú, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Nínífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù lára ohun téèyàn fi ń di ẹni tó ń tẹ̀ lé Jésù. Ó tún yẹ ká mọ̀ pé nínífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tan mọ́ nínífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa. (1 Jòhánù 4:20) Ní àwọn orí tó wà níwájú, a máa ṣàgbéyẹ̀wò bí Jésù ṣe jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn. Àmọ́ ní orí tó kàn, a óò jíròrò ohun tó mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn rí Jésù bí ẹni tó ṣeé sún mọ́.