APÁ 7
Ta Ni Jésù?
Jèhófà rán Jésù wá sí ayé. 1 Jòhánù 4:9
Ká tó lè múnú Jèhófà dùn, a gbọ́dọ̀ tẹ́tí sí ẹnì kan tó tún ṣe pàtàkì. Tipẹ́tipẹ́ kí Jèhófà tó dá Ádámù ló ti dá áńgẹ́lì kan tó lágbára sí ọ̀run.
Nígbà tó yá, Jèhófà mú kí wúńdíá kan tó ń jẹ́ Màríà bí ẹni yìí sí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Wọ́n sọ orúkọ ọmọ náà ní Jésù.—Jòhánù 6:38.
Nígbà tí Jésù jẹ́ èèyàn ní ayé, ó gbé àwọn ìwà Ọlọ́run yọ láìkù síbì kan. Ó jẹ́ onínúure, ó nífẹ̀ẹ́, ó sì ṣeé sún mọ́. Ó kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa Jèhófà láìbẹ̀rù.
1 Pétérù 2:21-24
Ohun rere ni Jésù ṣe, àmọ́ àwọn èèyàn kórìíra rẹ̀.Àwọn aṣáájú ìsìn kórìíra Jésù torí pé ó tú àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ èké àti ìwà ibi wọn.
Jésù tún mú àwọn aláìsàn lára dá, ó sì jí àwọn kan tó ti kú dìde.
Àwọn aṣáájú ìsìn mú kí àwọn ará Róòmù na Jésù kí wọ́n sì pa á.