Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 2

Ta Ni Ọlọ́run Tòótọ́?

Ta Ni Ọlọ́run Tòótọ́?

Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà, orúkọ rẹ̀ ni Jèhófà. (Sáàmù 83:18) Ẹ̀mí ni; a kò lè fi ojú rí i. Ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ kí àwa náà nífẹ̀ẹ́ òun. Bákan náà, ó fẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì. (Mátíù 22:35-40) Òun ni Ẹni Gíga Jù Lọ, òun sì ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.

Ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó lágbára ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, òun la wá mọ̀ sí Jésù Kristi. Jèhófà tún dá àwọn áńgẹ́lì.

Jèhófà ló dá ohun gbogbo tó wà ní ọ̀run . . . àti lórí ilẹ̀ ayé. Ìfihàn 4:11

Jèhófà Ọlọ́run ló dá àwọn ìràwọ̀ àti ayé pẹ̀lú ohun gbogbo tó wà nínú rẹ̀.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:1.

Ó fi erùpẹ̀ ilẹ̀ dá Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́.​—Jẹ́nẹ́sísì 2:7.