Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 24

Kò Sóhun Tó Lè “Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”

Kò Sóhun Tó Lè “Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”

1. Èrò tí kò tọ́ wo ló máa ń wá sí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn, títí kan àwọn Kristẹni tòótọ́?

 ṢÉ Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ? Àwọn kan gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn lápapọ̀, bí Jòhánù 3:16 ṣe sọ. Àmọ́, wọ́n máa ń rò ó pé: ‘Ọlọ́run ò lè nífẹ̀ẹ́ èmi yìí láéláé.’ Kódà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn Kristẹni tòótọ́ náà lè máa ṣiyèméjì pé bóyá ni Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn. Ọkùnrin kan tí nǹkan tojú sú sọ pé: “Ó ṣòro fún mi gan-an láti gbà pé Ọlọ́run tiẹ̀ rí tèmi rò.” Ṣé ìwọ náà máa ń ronú bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan?

2, 3. Ta ló fẹ́ ká máa rò pé a ò wúlò àti pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa, báwo la sì ṣe lè borí èrò yẹn?

2 Ohun tí Sátánì fẹ́ ni pé ká máa rò pé Jèhófà Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ wa àti pé a ò já mọ́ nǹkan kan lójú ẹ̀. Òótọ́ ni pé Sátánì máa ń mú káwọn èèyàn gbéra ga, kí wọ́n sì jọ ara wọn lójú. (2 Kọ́ríńtì 11:3) Àmọ́ Sátánì tún máa ń jẹ́ káwọn èèyàn rò pé àwọn ò wúlò, inú ẹ̀ sì máa ń dùn téèyàn bá ń ronú bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 7:47-49; 8:13, 44) “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tí nǹkan le gan-an yìí ló tiẹ̀ máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ jù. Lóde òní, kò sí “ìfẹ́ àdámọ́ni” nínú ìdílé tí wọ́n ti tọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn. Ojoojúmọ́ làwọn ẹlòmíì ń kojú àwọn èèyàn tó burú gan-an, tí wọ́n mọ tara wọn nìkan, tí wọ́n sì jẹ́ alágídí. (2 Tímótì 3:1-5) Àwọn tí wọ́n ti hùwà àìdáa sí tàbí táwọn èèyàn ti kórìíra fún ọ̀pọ̀ ọdún lè máa ronú pé àwọn ò wúlò, kò sì sẹ́ni tó lè nífẹ̀ẹ́ àwọn.

3 Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn, má sọ̀rètí nù. Nígbà míì, ọ̀pọ̀ nínú wa la máa ń ro ara wa pin. Àmọ́, ká má gbàgbé pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká lè ‘mú nǹkan tọ́’ ká sì lè “borí àwọn nǹkan [tàbí èrò] tó ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” (2 Tímótì 3:16; 2 Kọ́ríńtì 10:4) Bíbélì sọ pé: “A . . . máa jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ níwájú rẹ̀ nínú ohunkóhun tí ọkàn wa ti lè dá wa lẹ́bi, torí Ọlọ́run ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” (1 Jòhánù 3:19, 20) Ẹ jẹ́ ká jíròrò ọ̀nà mẹ́rin tí Bíbélì ti gbà ràn wá lọ́wọ́ láti “jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀” pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa.

Jèhófà Mọyì Rẹ

4, 5. Báwo ni àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ẹyẹ ológoṣẹ́ ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà mọyì wa?

4 Àkọ́kọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà mọyì àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Ẹyọ owó kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́ méjì, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀, ìkankan nínú wọn ò lè já bọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Kódà, gbogbo irun orí yín la ti kà. Torí náà, ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” (Mátíù 10:29-31) Ẹ jẹ́ ká wo bí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí ṣe rí lára àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà yẹn.

“Ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ”

5 Tá a bá gbọ́ pé ẹnì kan fẹ́ ra ẹyẹ ológoṣẹ́, ó lè yà wá lẹ́nu pé kí ló fẹ́ fi ṣe. Ìdí ni pé nígbà ayé Jésù, ẹyẹ ológoṣẹ́ ni owó rẹ̀ kéré jù téèyàn lè rà láti pa jẹ. Tẹ́nì kan bá ní ẹyọ owó kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí, ó máa ra ẹyẹ ológoṣẹ́ méjì. Àmọ́ Jésù wá sọ pé téèyàn bá ní ẹyọ owó méjì lọ́wọ́, ẹyẹ ológoṣẹ́ márùn-ún ni wọ́n máa tà fún un dípò mẹ́rin. Ṣe ló dà bíi pé èyí tí wọ́n fi ṣe ènì yẹn ò níye lórí rárá. Òótọ́ ni pé àwọn ẹyẹ yẹn lè má já mọ́ nǹkan kan lójú àwọn èèyàn, àmọ́ ojú wo ni Ẹlẹ́dàá fi ń wò wọ́n? Jésù sọ pé: “Ọlọ́run ò gbàgbé ìkankan nínú wọn [títí kan èyí tí wọ́n fi ṣe ènì pàápàá].” (Lúùkù 12:6, 7) Ọ̀rọ̀ yìí wá jẹ́ kí ohun tí Jésù sọ túbọ̀ yé wa. Tí ẹyẹ ológoṣẹ́ kan ṣoṣo bá níye lórí tó bẹ́ẹ̀ lójú Jèhófà, mélòómélòó wá ni àwa èèyàn! Bí Jésù ṣe sọ, Jèhófà mọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa látòkè délẹ̀. Kódà, ó mọ iye irun tó wà lórí wa!

6. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jésù mọ ohun tó ń sọ nígbà tó sọ pé Ọlọ́run mọ iye irun orí wa?

6 Ṣé kò yà wá lẹ́nu pé Ọlọ́run mọ iye irun orí wa? Àwọn kan le máa rò pé bóyá Jésù ò mọ ohun tó ń sọ. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká ronú nípa ìrètí àjíǹde. Ká sọ pé ẹnì kan kú, ṣé ẹ rò pé Jèhófà máa lè tún ẹni náà dá tí kò bá mọ ẹni náà dunjú? Jèhófà mọyì wa gan-an ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa wa ló mọ̀, títí kan àwọn ìsọfúnni tó wà nínú sẹ́ẹ̀lì ara wa, gbogbo ohun tá a ti ṣe látìgbà tá a ti wà láàyè àtàwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa. a Torí náà, tá a bá sọ pé Jèhófà mọ iye irun orí wa tó jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (100,000), kékeré nìyẹn jẹ́ tá a bá fi wé ohun tó mọ̀ nípa wa kó tó lè jí wa dìde.

Ohun Tó Mú Kí Jèhófà Mọyì Rẹ

7, 8. (a) Kí ni díẹ̀ lára ànímọ́ tí Jèhófà máa ń wá nínú ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ rere tí Jèhófà mọyì?

7 Ohun kejì ni pé Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí Jèhófà mọyì lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Inú rẹ̀ máa ń dùn gan-an sí àwọn ànímọ́ rere tá a ní àtàwọn ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀. Ọba Dáfídì sọ fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Gbogbo ọkàn ni Jèhófà ń wá, ó sì ń fi òye mọ gbogbo èrò àti ìfẹ́ ọkàn.” (1 Kíróníkà 28:9) Torí náà, ohun tó dáa ni Ọlọ́run máa ń wá nínú ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé nínú ayé oníwà ipá, tó kún fún ìkórìíra yìí. Inú ẹ̀ máa ń dùn gan-an tó bá rí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà, tó jẹ́ olóòótọ́, tó sì máa ń fẹ́ ṣe ohun tó dáa nígbà gbogbo. Kí ni Ọlọ́run máa ṣe tó bá rí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀, tó sì fẹ́ sọ ohun tóun mọ̀ fáwọn ẹlòmíì? Jèhófà sọ fún wa pé òun ń kíyè sí àwọn tó ń sọ̀rọ̀ nípa òun fáwọn ẹlòmíì. Ó tiẹ̀ ní “ìwé ìrántí kan” tó ń kọ nípa gbogbo “àwọn tó ń bẹ̀rù Jèhófà àti àwọn tó ń ṣe àṣàrò lórí orúkọ rẹ̀.” (Málákì 3:16) Àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ ṣeyebíye lójú rẹ̀.

8 Kí ni díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ rere tí Jèhófà mọyì? Ó dájú pé ó mọyì gbogbo ohun tá à ń ṣe láti fara wé Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀. (1 Pétérù 2:21) Iṣẹ́ pàtàkì kan tí Ọlọ́run mọyì ni iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Róòmù 10:15 sọ pé: “Ẹsẹ̀ àwọn tó ń kéde ìhìn rere àwọn ohun rere mà rẹwà o!” Àmọ́ ó lè máa ṣe wá bíi pé, ẹsẹ̀ wa ò rẹwà. Ṣùgbọ́n ńṣe lọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí ohun táwa èèyàn Jèhófà ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Torí náà, ó dájú pé gbogbo ohun tá à ń ṣe ṣeyebíye lójú Jèhófà, ó sì mọyì ẹ̀ gan-an.​—Mátíù 24:14; 28:19, 20.

9, 10. (a) Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà mọyì bá a ṣe ń fara da onírúurú ìṣòro? (b) Kí ni Jèhófà kì í ṣe bó ṣe ń kíyè sí àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́?

9 Jèhófà tún mọyì ìfaradà wa. (Mátíù 24:13) Rántí pé, ńṣe ni Sátánì ń fẹ́ kó o kẹ̀yìn sí Jèhófà. Gbogbo ìgbà tó o bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, lò ń jẹ́ kí Sátánì mọ̀ pé òpùrọ́ ni. (Òwe 27:11) Àmọ́ nígbà míì, kì í rọrùn láti fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. Ìdí ni pé àìlera, àìrówó gbọ́ bùkátà, àníyàn àtàwọn ìṣòro míì lè mú kí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nira gan-an. Ìrẹ̀wẹ̀sì tún lè mú wa, tí ọ̀nà ò bá gba ibi tá a fojú sí. (Òwe 13:12) Jèhófà mọyì ìfaradà wa gan-an láwọn àsìkò yẹn. Ìdí nìyẹn tí Ọba Dáfídì fi sọ pé kí Jèhófà fi omijé òun sínú “ìgò awọ” rẹ̀, tó sì sọ ọ́ pẹ̀lú ìdánilójú pé: “Ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé rẹ?” (Sáàmù 56:8) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ò ní gbàgbé, kò sì ní fojú kéré gbogbo omijé àti ìyà tó ń jẹ wá bá a ṣe ń jẹ́ olóòótọ́ sí i, torí pé wọ́n ṣeyebíye lójú rẹ̀.

Jèhófà mọyì bá a ṣe ń fara da oríṣiríṣi àdánwò

10 Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo ẹ̀rí tá a rí yìí, ó ṣì lè máa ṣe wá bíi pé a ò wúlò lójú Jèhófà. A lè máa rò ó pé: ‘Ọ̀pọ̀ èèyàn míì ló wà tó dáa jù mí lọ. Tí Jèhófà bá sì fi ohun tí mò ń ṣe wé tiwọn, ó dájú pé inú ẹ̀ ò ní dùn sí mi.’ Jèhófà kì í fi wá wé àwọn míì, ó máa ń gba tiwa rò, kì í sì í retí pé ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ. (Gálátíà 6:4) Jèhófà máa ń fara balẹ̀ kíyè sí ohun tó wà lọ́kàn wa, ó sì máa ń láyọ̀ tó bá rí i pé à ń gbìyànjú láti máa ṣe rere. Kódà, tí nǹkan tá à ń ṣe ò bá tiẹ̀ tó nǹkan lójú tiwa, Jèhófà mọyì ẹ̀.

Ibi Tá A Dáa Sí Ni Jèhófà Ń Wo

11. Kí ni ìtàn Ábíjà kọ́ wa nípa Jèhófà?

11 Ìkẹta, bí Jèhófà ṣe ń yẹ̀ wá wò, ó ń fara balẹ̀ wá ibi tá a dáa sí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo ìlà ìdílé Ọba Jèróbóámù run, torí pé wọ́n ti di apẹ̀yìndà, ó ní kí wọ́n ṣe ìsìnkú ẹ̀yẹ fún Ábíjà, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọba yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì rí ohun rere nínú rẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 14:1, 10-13) Ńṣe ni Jèhófà yẹ ọkàn ọ̀dọ́kùnrin yẹn wò, ó sì rí “ohun rere nínú rẹ̀.” Bó ti wù kí ohun rere yẹn kéré tó, Jèhófà rí i dájú pé ìtàn yẹn wà nínú Bíbélì. Ó tiẹ̀ san ọ̀dọ́kùnrin yẹn lẹ́san, ó ṣojú àánú sí i, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìdílé apẹ̀yìndà ló ti wá.

12, 13. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ Ọba Jèhóṣáfátì ṣe fi hàn pé Jèhófà máa ń rí iṣẹ́ rere wa kódà nígbà tá a bá dẹ́ṣẹ̀? (b) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn iṣẹ́ àti ìwà rere wa, kí ni kò sì ní ṣe láé?

12 Àpẹẹrẹ míì tó túbọ̀ jẹ́ ká rí i pé ibi tá a dáa sí ni Jèhófà máa ń wò ni ti Ọba Jèhóṣáfátì. Ọba rere ni ọba yìí, àmọ nígbà kan ó hùwà òmùgọ̀, wòlíì Jèhófà sọ fún un pé: “Nítorí èyí, ìbínú Jèhófà ru sí ọ.” Ọ̀ràn rèé o! Àmọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà kò parí síbẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà ń bá a lọ pé: “Síbẹ̀, àwọn ohun rere kan wà tí a rí nínú rẹ.” (2 Kíróníkà 19:1-3) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ń bínú sí Jèhóṣáfátì, ó ṣì rí ibi tó dáa sí. Ẹ ò rí i pé èyí yàtọ̀ pátápátá sí ìwà ẹ̀dá aláìpé! Nígbà tí inú bá ń bí wa sáwọn èèyàn, a lè máà rí ohun rere tí wọ́n ṣe. Nígbà tí àwa fúnra wa náà bá sì dẹ́ṣẹ̀, ìjákulẹ̀, ìtìjú àti bá a ṣe máa ń dá ara wa lẹ́bi lè máà jẹ́ ká rí àwọn nǹkan rere tá a ti ṣe. Àmọ́, ká máa rántí pé tá a bá ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wa, tá a sì ń sapá láti má ṣe pa dà sídìí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa dárí jì wá.

13 Bí Jèhófà ṣe ń yẹ̀ ọ́ wò, ńṣe ló ń gbójú fo irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀, bí ẹni tó ń wá góòlù ṣe ń fọwọ́ rọ́ òkúta lásán tì sápá kan. Àwọn ànímọ́ àti iṣẹ́ rere rẹ ńkọ́? Àwọn yẹn gangan ni “góòlù” tí Jèhófà ń wá! Ṣé o ti kíyè sí báwọn òbí kan ṣe máa ń tọ́jú àwòrán tí ọmọ wọn yà tàbí iṣẹ́ kan tó ṣe níléèwé, tí wọ́n á sì wá fi hàn án lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tọ́mọ ọ̀hún lè ti gbàgbé pé òun ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀? Jèhófà ni Òbí tó fẹ́ràn àwọn ọmọ rẹ̀ jù lọ. Tá a bá ṣáà ti jẹ́ olóòótọ́ sí i, kò ní gbàgbé àwọn iṣẹ́ àti ìwà rere wa láé. Kódà, ìwà àìṣòdodo ló kà á sí láti gbàgbé wọn, a sì mọ̀ pé kì í ṣe aláìṣòdodo. (Hébérù 6:10) Jèhófà tún máa ń ṣe ohun míì kó lè rí ibi tá a dáa sí.

14, 15. (a) Kí nìdí tá a fi ṣeyebíye lójú Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá? Sọ àpèjúwe kan. (b) Kí ni Jèhófà máa ṣe sáwọn ìwà rere tá a ní, ojú wo ló sì fi ń wo àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́?

14 Dípò kí Jèhófà máa wo àṣìṣe wa, ìwà tó dáa tá a ní àtàwọn ohun tó dáa tá a lè ṣe ló máa ń wò. Àpèjúwe kan rèé: Àwọn tó fẹ́ràn iṣẹ́ ọnà máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ṣàtúnṣe àwọn àwòrán tàbí iṣẹ́ ọnà míì tó bà jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọkùnrin kan lọ sí ọ̀kan lára ibi tí wọ́n ń kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí nílùú London, tó sì ba àwòrán kan tó ṣeyebíye jẹ́, kò sẹ́ni tó sọ pé kí wọ́n ju àwòrán náà nù torí pé ó ti bà jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ojú ẹsẹ̀ làwọn tó mọ̀ nípa iṣẹ́ ọnà bẹ̀rẹ̀ sí í tún àwòrán náà ṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwòrán yẹn ṣeyebíye lójú àwọn tó fẹ́ràn iṣẹ́ ọnà. Ṣé o ò wá níye lórí ju àwòrán lásán ni? Ó dájú pé o níye lórí ju irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lójú Ọlọ́run, bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì, àìpé ẹ lè jẹ́ kó o rò pé o ò já mọ́ nǹkan kan. (Sáàmù 72:12-14) Jèhófà Ọlọ́run tó ṣẹ̀dá àwa èèyàn máa ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ láti mú kí gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tó sì ń ṣègbọràn sí i di pípé.​—Ìṣe 3:21; Róòmù 8:20-22.

15 Ó dájú pé Jèhófà ń rí àwọn ìwà tó dáa tá a ní, báwa fúnra wa ò bá tiẹ̀ rí i. Bá a sì ṣe ń sìn ín, á mú káwọn ìwà rere tá a ní máa dáa sí i títí tá a fi máa di ẹni pípé. Ohun yòówù kí ayé Sátánì ti fojú wa rí, ó dájú pé ohun iyebíye ni Jèhófà ka àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ sí.​—Hágáì 2:7.

Jèhófà Ń Fi Hàn Pé Òun Nífẹ̀ẹ́ Wa

16. Ẹ̀rí wo ló lágbára jù lọ tó fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, báwo la sì ṣe mọ̀ pé torí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni Jésù ṣe kú?

16 Ìkẹrin, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa. Ó dájú pé ẹbọ ìràpadà Kristi ni ohun pàtàkì tó fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa nígbà tó sọ pé a ò wúlò àti pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa. Ká má gbàgbé láé pé ikú tí Jésù kú lórí igi oró àti ìrora ńlá tí Jèhófà fara dà bó ṣe ń wò ó tí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ń kú jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa. Ó dunni pé ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbà pé torí wọn ni Jésù ṣe kú. Wọ́n gbà pé àwọn ò yẹ lẹ́ni tí Jésù ń kú fún. Àmọ́, rántí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ ń ṣe inúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Síbẹ̀, ó sọ pé: ‘Ọmọ Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi, ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.’​—Gálátíà 1:13; 2:20.

17. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fà wá sún mọ́ ara rẹ̀ àti Ọmọ rẹ̀?

17 Jèhófà ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa bó ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kí ẹbọ ìràpadà Kristi lè ṣe wá láǹfààní. Jésù sọ pé: “Kò sí èèyàn tó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba tó rán mi fà á.” (Jòhánù 6:44) Jèhófà fúnra rẹ̀ ló máa ń fà wá sún mọ́ Ọmọ rẹ̀, ó sì tún fún wa ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. Lọ́nà wo? Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tó ń dé ọ̀dọ̀ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ni. Bákan náà, ó máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ ká sì fi wọ́n sílò láìka àìpé wa sí. Torí náà, Jèhófà lè sọ nípa wa, bó ṣe sọ nípa Ísírẹ́lì pé: “Ìfẹ́ tí mo ní sí ọ jẹ́ ìfẹ́ ayérayé. Ìdí nìyẹn tí mo fi fà ọ́ mọ́ra pẹ̀lú ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”​—Jeremáyà 31:3.

18, 19. (a) Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ wo ni Jèhófà fún wa tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa ó sì fẹ́ ká sún mọ́ òun, kí ló sì fi hàn pé òun fúnra rẹ̀ ló ń bójú tó èyí? (b) Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń mọ ẹ̀dùn ọkàn wa lára?

18 Àdúrà ni ọ̀nà tó lágbára jù lọ tá a lè gbà sún mọ́ Jèhófà, torí pé bó ṣe fún wa láǹfààní láti gbàdúrà sí òun fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Bíbélì rọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa pé ká “máa gbàdúrà nígbà gbogbo.” (1 Tẹsalóníkà 5:17) Elétí gbáròyé ni. Òun sì ni “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Kò fún ẹlòmíì láṣẹ láti máa gbọ́ àdúrà, kódà kò fún Ọmọ rẹ̀ pàápàá láṣẹ yẹn. Rò ó wò ná: Ẹlẹ́dàá ayé àti ọ̀run rọ̀ wá pé ká máa gbàdúrà sí òun fàlàlà, ká sì sọ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn wa fóun. Tá a bá ń gbàdúrà, ṣé Jèhófà kàn máa ń gbọ́ àdúrà wa lásán ni? Rárá o. Àdúrà wa ṣe pàtàkì sí i.

19 Jèhófà máa ń fọ̀rọ̀ ro ara ẹ̀ wò. Kí ni ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò? Kristẹni olóòótọ́ kan tó jẹ́ àgbàlagbà sọ pé: “Ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò ni kẹ́nì kan mọ ìrora ẹlòmíì nínú ọkàn rẹ̀.” Ṣé ìrora wa tiẹ̀ kan Jèhófà? Wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa bó ṣe rí lára Jèhófà nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jìyà, ó ní: “Nínú gbogbo ìdààmú wọn, ìdààmú bá òun náà.” (Àìsáyà 63:9) Kì í ṣe pé Jèhófà kàn rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn rẹ̀, ó mọ̀ ọ́n lára. Ọ̀rọ̀ tó sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ ká mọ bó ṣe mọ̀ ọ́n lára tó, ó sọ pé: “Ẹni tó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.” b (Sekaráyà 2:8) Ká sòótọ́, tẹ́nì kan bá fọwọ́ kan ojú wa ó máa dùn wá gan-an. Èyí fi hàn pé tá a bá wà nínú ìṣòro, àánú wa máa ń ṣe Jèhófà gan-an. Kódà, tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn, òun náà máa ní ẹ̀dùn ọkàn.

20. Èrò wo ló yẹ ká yẹra fún tá a bá fẹ́ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà ní Róòmù 12:3?

20 Tí òtítọ́ bá jinlẹ̀ nínú Kristẹni kan, kò ní torí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ òun kó wá máa ronú pé òun sàn ju àwọn míì lọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fún mi, mo sọ fún gbogbo ẹni tó wà láàárín yín níbẹ̀ pé kó má ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, àmọ́ kó máa ronú lọ́nà tó fi hàn pé ó láròjinlẹ̀, bí Ọlọ́run ṣe fún kálukú ní ìwọ̀n ìgbàgbọ́.” (Róòmù 12:3) Nítorí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Baba wa ọ̀run ń fìfẹ́ hàn sí wa tí èyí sì ń mú kára tù wá, ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé kì í ṣe nípasẹ̀ iṣẹ́ àṣekára wa tàbí torí pé ó jẹ́ ẹ̀tọ́ wa la ṣe ní àǹfààní yìí.​—Lúùkù 17:10.

21. Àwọn irọ́ wo ni Sátánì ń pa tí kò yẹ ká gbà gbọ́, ọ̀rọ̀ wo sì ni Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ táá máa fi wá lọ́kàn balẹ̀?

21 Ẹ jẹ́ kí kálukú wa máa sa gbogbo ipá wa láti má ṣe gba irọ́ Sátánì gbọ́, títí kan irọ́ tó pa pé a ò wúlò rárá tàbí pé Ọlọ́run ò lè nífẹ̀ẹ́ wa. Ṣé àwọn ohun kan ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ tó jẹ́ kó o rò pé èèyàn burúkú ni ẹ́ àti pé Ọlọ́run ò lè nífẹ̀ẹ́ ẹ? Tàbí ò ń rò ó pé àwọn nǹkan tó dáa tó ò ń ṣe ti kéré jù fún Ọlọ́run láti kíyè sí? Àbí ńṣe lo rò pé o ti dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan tó burú gan-an débi pé ẹbọ ìràpadà Jésù ò lè ṣé ẹ láǹfààní? Máa fi sọ́kàn pé irọ́ pátápátá nìyẹn, má gbà á gbọ́ rárá! Ẹ jẹ́ ká máa rántí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ sílẹ̀, kó lè máa fi wá lọ́kàn balẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà ni pé: “Ó dá mi lójú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tó wà nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tó ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ló máa lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.”​—Róòmù 8:38, 39.

a Ọ̀pọ̀ ìgbà tí Bíbélì bá sọ̀rọ̀ nípa ìrètí àjíǹde ló máa ń rán wa létí agbára tí Jèhófà ní láti rántí nǹkan. Ọkùnrin olóòótọ́ náà Jóòbù, sọ fún Jèhófà pé: “Ká ní . . . o yan àkókò kan sílẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi!” (Jóòbù 14:13) Jésù náà sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde “gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí. Òótọ́ sì lọ̀rọ̀ yìí, torí pé gbogbo àwọn òkú tí Jèhófà ní lọ́kàn láti jí dìde ló rántí dáadáa.​—Jòhánù 5:28, 29.

b Báwọn kan ṣe túmọ̀ ẹsẹ yìí jẹ́ kó dà bíi pé ńṣe lẹni tó bá fọwọ́ kan àwọn èèyàn Ọlọ́run ń tọwọ́ bọ ara ẹ̀ lójú tàbí pé ó ń tọwọ́ bọ Ísírẹ́lì lójú, kì í ṣe pé ó ń tọwọ́ bọ Ọlọ́run lójú. Àwọn adàwékọ kan ló túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà yẹn torí wọ́n ka ọ̀rọ̀ yẹn sí àrífín. Bí wọ́n ṣe yí ẹsẹ Bíbélì yẹn pa dà kò jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé Jèhófà máa ń fọ̀rọ̀ ro ara ẹ̀ wò gan-an débi pé táwọn èèyàn ẹ̀ bá ní ẹ̀dùn ọkàn, òun náà máa ní ẹ̀dùn ọkàn.