Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KẸRÌNLÁ

Ó Kọ́ Ìdí Tó Fi Yẹ Kó Jẹ́ Aláàánú

Ó Kọ́ Ìdí Tó Fi Yẹ Kó Jẹ́ Aláàánú

1. Báwo ni ìrìn àjò Jónà ṣe máa rí? Èrò wo ló ní nípa ibi tó ń lọ?

JÓNÀ máa ní àkókò tó pọ̀ tó láti ronú. Ó ní láti fi ẹsẹ̀ rìnrìn àjò tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] kìlómítà. Ó máa tó oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kó tó débẹ̀. Àmọ́, ó ní láti kọ́kọ́ pinnu ọ̀nà tó máa gbà débẹ̀. Yálà kó gba ọ̀nà tó yá, àmọ́ tó léwu tàbí kó gba ọ̀nà tó jìn, àmọ́ tí kò léwu. Èyí ó wù kó gbà nínú ọ̀nà méjèèjì, bó ṣe ń la ọ̀pọ̀ àfonífojì kọjá lá máa pọ́nkè tó bá dé ibi àpáta. Ó ṣeé ṣe kó gba eteetí aṣálẹ̀ tó fẹ̀ lọ salalu lágbègbè Síríà, kó la apá ibi tí kò jìn lára àwọn odò ńláńlá bí odò Yúfírétì kọjá, kó sì wá ibi sùn sí láàárín àwọn àjèjì láwọn ìlú àtàwọn abúlé tó wà ní ilẹ̀ Síríà, Mesopotámíà àti Ásíríà. Bó ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìrìn àjò rẹ̀, ó túbọ̀ ń ronú nípa ibi tó ń lọ, ìyẹn ìlú Nínéfè. Bó sì ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rù tó ń bà á ń pọ̀ sí i.

2. Kí ló mú kí Jónà mọ̀ pé òun ò lè sá kúrò nídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán òun?

2 Ohun kan wà tó dá Jónà lójú: Ó mọ̀ pé òun ò lè sá kúrò nídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán òun. Ìdí sì ni pé ó ti ṣe bẹ́ẹ̀ rí. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i ní Orí Kẹtàlá, Jèhófà fi sùúrù kọ́ Jónà lẹ́kọ̀ọ́. Ó mú kí ìjì líle kan jà lójú òkun, ó sì gba Jónà sílẹ̀ lọ́nà ìyanu nígbà tó mú kí ẹja ńlá kan gbé e mì. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, ẹja náà pọ Jónà láàyè sí etí òkun. Ẹ̀rù tó ba Jónà mú kó túbọ̀ bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run kó sì fẹ́ láti ṣègbọràn.—Jónà, orí 1 àti 2.

3. Kí ni Jèhófà ṣe fún Jónà lẹ́yìn tó ti bá a wí, síbẹ̀ ìbéèrè wo ló jẹ yọ?

3 Nígbà tí Jèhófà pàṣẹ fún Jónà lẹ́ẹ̀kejì pé kó lọ sí ìlú Nínéfè, ó ṣègbọràn. Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò gígùn náà, ó sì forí lé apá ìlà oòrùn. (Ka Jónà 3:1-3.) Àmọ́, ní báyìí tí Jèhófà ti bá Jónà wí, ǹjẹ́ ó ṣe tán láti yí irú ẹni tó jẹ́ pa dà pátápátá? Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ti ṣàánú rẹ̀, kò jẹ́ kí omi gbé e lọ, kò fìyà jẹ ẹ́ torí pé ó ṣe ìfẹ́ inú ara rẹ̀, ó sì pa dà rán an níṣẹ́ lẹ́ẹ̀kejì. Ṣé gbogbo èyí ti wá mú kí Jónà máa ṣàánú àwọn èèyàn? Kì í sábà rọrùn fún àwa ẹ̀dá aláìpé láti jẹ́ aláàánú. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ nínú ìtàn Jónà.

Ó Kéde Ìdájọ́ Ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ Ò Rí Bó Ṣe Rò

4, 5. Kí nìdí tí Jèhófà fi pe ìlú Nínéfè ní “ìlú ńlá tí ó tóbi”? Ẹ̀kọ́ wo ni èyí kọ́ wa nípa Jèhófà?

4 Ojú tí Jèhófà fi wo àwọn ará Nínéfè kọ́ ni Jónà fi wò wọ́n. Bíbélì sọ pé: “Wàyí o, Nínéfè jẹ́ ìlú ńlá tí ó tóbi lójú Ọlọ́run.” (Jónà 3:3) Nínú ìwé Jónà, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà pe Nínéfè ní “ìlú ńlá títóbi.” (Jónà 1:2; 3:2; 4:11) Kí nìdí tí ìlú yìí fi tóbi tàbí tó fi ṣe pàtàkì lójú Jèhófà?

5 Ọjọ́ pẹ́ tí ìlú Nínéfè ti wà. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tí Nímírọ́dù kọ́kọ́ tẹ̀ dó lẹ́yìn Ìkún-omi. Ìlú ńlá tó fẹ̀ ní ìlú Nínéfè, àwọn ìlú kéékèèké míì sì yí i ká. Odindi ọjọ́ mẹ́ta lèèyàn máa fi rìn láti ìpẹ̀kun kan ìlú náà sí ìpẹ̀kun kejì. (Jẹ́n. 10:11; Jónà 3:3) Ìlú tó fani mọ́ra ni ìlú Nínéfè. Ó ní àwọn tẹ́ńpìlì ńláńlá, àwọn ògiri gìrìwò àti àwọn ilé ńlá míì ní ọ̀kan-ò-jọ̀kan. Àmọ́ kì í ṣe èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan yìí ló mú kí ìlú náà ṣe pàtàkì lójú Jèhófà Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ ló jẹ ẹ́ lógún. Àwọn èèyàn tó ń gbé nílùú Nínéfè pọ̀ fíìfíì ju àwọn tó ń gbé ní àwọn ìlú mìíràn tó wà nígbà yẹn lọ. Láìka ìwà ibi tó kún ọwọ́ àwọn èèyàn náà sí, Jèhófà bìkítà nípa wọn. Ẹ̀mí àwọn èèyàn jọ ọ́ lójú, ó sì mọ̀ pé olúkúlùkù wọn lè fẹ́ láti ronú pìwà dà, kí wọ́n sì kọ́ láti máa ṣe rere.

Jónà rí i pé ìlú Nínéfè tóbi, ó sì kún fún ìwà àìtọ́

6. (a) Kí ló lè mú kí ìlú Nínéfè máa ba Jónà lẹ́rù? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Kí la rí kọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù tí Jónà ṣe?

6 Nígbà tí Jónà wá dé ìlú Nínéfè, ó rí i pé èrò kún inú rẹ̀ fọ́fọ́. Àwọn tó ń gbé níbẹ̀ lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́fà [120,000], ìyẹn sì tún lè dá kún ẹ̀rù tó ń bà á. * Ó rin ìrìn odindi ọjọ́ kan wọnú ìlú náà lọ. Bóyá ohun tó mú kó ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó ń wá ibi tó lè dúró sí tí ọ̀pọ̀ èèyàn á fi gbọ́ iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an. Èdè wo ló máa fi bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀? Ṣé ó ti kọ́ èdè àwọn ará Ásíríà ni? Àbí ńṣe ni Jèhófà mú kó máa sọ èdè náà lọ́nà ìyanu? A kò mọ̀. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni Jónà lo èdè àbínibí rẹ̀, ìyẹn èdè Hébérù, láti bá wọn sọ̀rọ̀ tí ẹnì kan sì bá a túmọ̀ rẹ̀ sí èdè àwọn ará Nínéfè. Àmọ́, ó dájú pé iṣẹ́ tó jẹ́ ò ṣòro láti lóye, kò sì jọ pé inú àwọn èèyàn náà á dùn sí i nígbà tó sọ fún wọn pé: “Kìkì ogójì ọjọ́ sí i, a ó sì bi Nínéfè ṣubú.” (Jónà 3:4) Ó sọ̀rọ̀ láìṣojo àti ní àsọtúnsọ. Lọ́nà yìí, Jónà fi hàn pé òun ní ìgboyà àti ìgbàgbọ́ tó ta yọ. Àwa tá a jẹ́ Kristẹni lóde òní náà nílò irú ìgboyà àti ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ.

Iṣẹ́ tí Jónà jẹ́ ò ṣòro láti lóye, kò sì jọ pé inú àwọn èèyàn náà á dùn sí i

7, 8. (a) Kí ni àwọn ará Nínéfè ṣe lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Jónà? (b) Kí ni ọba ìlú Nínéfè ṣe lẹ́yìn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jónà?

7 Àwọn ará ìlú Nínéfè dúró gbọ́ ọ̀rọ̀ Jónà. Ó ṣeé ṣe kí Jónà ti ronú pé àwọn èèyàn náà á bínú wọ́n á sì gbéjà ko òun. Àmọ́, ohun tó yàtọ̀ síyẹn ló ṣẹlẹ̀. Àwọn ará Nínéfè tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ Jónà wọ́n sì ṣègbọràn! Kíá ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti dé etígbọ̀ọ́ gbogbo ará ìlú. Kò sì pẹ́ tí gbogbo wọn fi bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn sọ̀rọ̀ nípa ìparun tí Jónà sọ pé Ọlọ́run ń mú bọ̀ wá sórí ìlú náà. (Ka Jónà 3:5.) Gbogbo wọn pátá, àti ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti àgbàlagbà, ni wọ́n ronú pìwà dà. Wọn kò jẹun. Kò sì pẹ́ rárá tí ọ̀rọ̀ tá à ń wí yìí fi dé etígbọ̀ọ́ ọba.

Ó gba ìgboyà àti ìgbàgbọ́ kí Jónà tó lè wàásù ní ìlú Nínéfè

8 Ọba pàápàá ronú pìwà dà nígbà tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jónà. Nítorí pé ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó dìde lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó bọ́ aṣọ ìgúnwà olówó iyebíye, ó sì wọ aṣọ àpò ìdọ̀họ bíi tàwọn aráàlú, kódà ó “jókòó nínú eérú.” Lẹ́yìn tí ọba àti àwọn “ẹni ńlá” rẹ̀, ìyẹn àwọn ìjòyè rẹ̀, ti fikùn lukùn, ọba pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn ará ìlú Nínéfè gbààwẹ̀. Bí ọba ṣe sọ ààwẹ̀ téèyàn lè gbà nígbà tó bá wù ú di ọ̀ranyàn fún gbogbo aráàlú nìyẹn o! Ọba pàṣẹ pé kí gbogbo aráàlú wọ aṣọ àpò ìdọ̀họ, kí wọ́n sì tún wọ̀ ọ́ fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn. * Ó gbà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé òótọ́ làwọn èèyàn òun máa ń hùwà ibi àti ìwà ipá. Níwọ̀n bí ọba sì ti rò pé Ọlọ́run tòótọ́ máa ṣàánú àwọn tó bá rí bí àwọn ṣe ronú pìwà dà, ó ní: ‘Ọlọ́run lè yí padà kúrò nínú ìbínú rẹ̀ jíjófòfò, kí a má bàa ṣègbé.’—Jónà 3:6-9.

9. Kí ni àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ kò gbà gbọ́ nípa àwọn ará Nínéfè? Báwo la ṣe mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀?

9 Àwọn kan tó máa ń ṣe lámèyítọ́ sọ pé àwọn ò gbà gbọ́ pé àwọn ará Nínéfè lè yára ronú pìwà dà bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì ti sọ pé èrò àti ìmọ̀lára àwọn èèyàn ìgbà yẹn máa ń tètè yí pa dà torí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán. Ní àfikún sí èyí, a mọ̀ pé èrò àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ náà kò tọ̀nà torí pé Jésù Kristi pàápàá sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ará Nínéfè ṣe ronú pìwà dà. (Ka Mátíù 12:41.) Ó sì dájú pé ohun tí Jésù sọ dá a lójú, torí pé ọ̀run ló wà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn fi wáyé, gbogbo wọn ló sì ṣojú rẹ̀. (Jòh. 8:57, 58) Òótọ́ tí kò ṣeé já ní koro ni pé bó ti wù ká rò pé àwọn èèyàn kan ya ẹhànnà tó, a kò gbọ́dọ̀ ronú láé pé wọn kò lè ronú pìwà dà. Jèhófà nìkan ló lè mọ ohun tó wà nínú ọkàn àwọn èèyàn.

Àánú Tí Ọlọ́run Ní Mú Kó Yàtọ̀ sí Àwa Ẹ̀dá

10, 11. (a) Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tí àwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà? (b) Kí ló mú kó dá wa lójú pé kò sí àṣìṣe nínú ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe fún àwọn ará Nínéfè?

10 Kí ni Jèhófà wá ṣe nígbà tí àwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà? Jónà sọ pé: “Ọlọ́run tòótọ́ sì wá rí àwọn iṣẹ́ wọn, pé wọ́n ti yí padà kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn; nítorí náà, Ọlọ́run tòótọ́ pèrò dà lórí ìyọnu àjálù tí ó ti sọ pé òun yóò mú bá wọn; kò sì mú un wá.”—Jónà 3:10.

11 Ṣé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé Jèhófà gbà pé òun ti ṣe àṣìṣe nínú ìdájọ́ tí òun ṣe fún àwọn ará Nínéfè? Rárá o. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé pípé ni ìdájọ́ òdodo Jèhófà. (Ka Diutarónómì 32:4.) Ńṣe ni inú tó ń bí Jèhófà sí àwọn ará Nínéfè torí ìwà búburú wọn rọlẹ̀. Ó rí i pé àwọn èèyàn náà ti yí pa dà, torí náà kò sí ìdí tó fi ní láti jẹ wọ́n níyà mọ́. Látàrí ìyẹn, Ọlọ́run pinnu láti ṣàánú àwọn ará Nínéfè.

12, 13. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé òun máa ń fòye báni lò, pé òun lè pèrò dà àti pé òun jẹ́ aláàánú? (b) Kí nìdí tá ò fi lè sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni Jónà sọ?

12 Ohun tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn fi ń kọ́ni lè mú kéèyàn rò pé Ọlọ́run kì í pèrò dà, pé kò láàánú tàbí pé ó jẹ́ òǹrorò. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run máa ń fòye báni lò, ó máa ń pèrò dà, ó sì tún jẹ́ aláàánú. Tó bá fẹ́ fìyà jẹ àwọn èèyàn burúkú, á kọ́kọ́ rán àwọn aṣojú rẹ̀ tó wà láyé pé kí wọ́n lọ kìlọ̀ fún wọn. Ìdí sì ni pé ó ń fẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣe bíi tàwọn ará Nínéfè, ìyẹn ni pé kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yí pa dà. (Ìsík. 33:11) Jèhófà sọ fún Jeremáyà wòlíì rẹ̀ pé: “Ní ìṣẹ́jú èyíkéyìí tí mo bá sọ̀rọ̀ lòdì sí orílẹ̀-èdè kan àti lòdì sí ìjọba kan láti fà á tu àti láti bì í wó àti láti pa á run, tí orílẹ̀-èdè yẹn bá sì yí padà ní ti gidi kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀ èyí tí mo sọ̀rọ̀ lòdì sí, èmi pẹ̀lú yóò pèrò dà dájúdájú ní ti ìyọnu àjálù tí mo ti rò láti mú ṣẹ ní kíkún sórí rẹ̀.”—Jer. 18:7, 8.

Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn èèyàn búburú ronú pìwà dà, kí wọ́n sì kọ ìwàkiwà sílẹ̀ bíi tàwọn ará Nínéfè

13 Ṣé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni Jónà sọ fáwọn èèyàn yẹn? Rárá o! Ìkìlọ̀ ni àsọtẹ́lẹ̀ náà jẹ́. Ìwàkíwà tó kún ọwọ́ àwọn ará Nínéfè ló mú kí ìkìlọ̀ yẹn wáyé, àmọ́ wọ́n yí pa dà. Tí àwọn ará Nínéfè bá tún bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà burúkú, Ọlọ́run ṣì máa mú ìdájọ́ yẹn ṣẹ sórí wọn. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn nìyẹn.—Sef. 2:13-15.

14. Kí ni Jónà ṣe torí pé Jèhófà ṣàánú àwọn ará Nínéfè?

14 Kí ni Jónà ṣe nígbà tó rí i pé Ọlọ́run ò pa àwọn èèyàn yẹn run nígbà tí òun fọkàn sí? Bíbélì sọ pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, kò dùn mọ́ Jónà nínú rárá, inú rẹ̀ sì ru fún ìbínú.” (Jónà 4:1) Jónà tiẹ̀ gbàdúrà kan tó jọ pé ó fi dá Ọlọ́run lẹ́bi! Ó sọ nínú àdúrà náà pé òun ì bá ti dúró sí ìlú òun jẹ́jẹ́. Ó ní òun ti mọ̀ pé Jèhófà ò ní pa ìlú Nínéfè run, àti pé ìyẹn gan-an ló fà á tí òun fi kọ́kọ́ sá lọ sí ìlú Táṣíṣì. Lẹ́yìn yẹn ló wá sọ pé kí Jèhófà kúkú gbẹ̀mí òun, torí pé ó sàn kí òun kú ju kí òun wà láàyè lọ.—Ka Jónà 4:2, 3.

15. (a) Kí ló fà á tí Jónà fi bínú tó sì bọkàn jẹ́? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ran Jónà lọ́wọ́?

15 Kí ló ba Jónà lọ́kàn jẹ́? A ò lè mọ gbogbo nǹkan tó wà lọ́kàn Jónà. Ṣùgbọ́n, a mọ̀ pé ó ti kéde fún àwọn ará Nínéfè pé Ọlọ́run máa pa ìlú wọn run, wọ́n sì gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́. Àmọ́ ní báyìí, Ọlọ́run ò ní pa ìlú náà run mọ́. Àbí ńṣe ni ẹ̀rù ń ba Jónà pé wọ́n á máa fi òun ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí wọ́n máa pe òun ní wòlíì èké? Èyí tó wù kó jẹ́, ó dájú pé inú rẹ̀ ò dùn pé àwọn èèyàn náà ronú pìwà dà tàbí pé Jèhófà ṣàánú wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni inú túbọ̀ bí i, ó kábàámọ̀, ó sì ń ṣàníyàn nípa ojú táwọn èèyàn á fi máa wo òun. Síbẹ̀, ó dájú pé Ọlọ́run aláàánú tí Jónà ń sìn ṣì rí i pé wòlíì dáadáa ni. Dípò tí Ọlọ́run ì bá fi fìyà jẹ Jónà torí ìwà àfojúdi tó hù yìí, ńṣe ló wulẹ̀ bi í ní ìbéèrè kan ṣoṣo tó máa pe orí rẹ̀ wálé, ó ní: “Ǹjẹ́ ríru tí inú rẹ ru fún ìbínú ha jẹ́ lọ́nà ẹ̀tọ́ bí?” (Jónà 4:4) Ṣé Jónà tiẹ̀ dáhùn ìbéèrè yìí? Bíbélì ò sọ fún wa.

16. Báwo ni àwọn kan ṣe lè fi hàn pé àwọn kò fara mọ́ èrò Ọlọ́run? Ẹ̀kọ́ wo ni ìtàn Jónà kọ́ wa?

16 Ó rọrùn láti dá Jónà lẹ́bi torí ohun tó ṣe. Àmọ́, ó yẹ ká rántí pé kì í ṣe nǹkan àjèjì pé kí èèyàn aláìpé má fara mọ́ èrò Ọlọ́run. Àwọn kan lè gbà pé kò yẹ kí Jèhófà jẹ́ kí àjálù kan ṣẹlẹ̀. Àwọn míì lè sọ pé ó ti yẹ kí Ọlọ́run yára ṣe ìdájọ́ àwọn ẹni ibi. Wọ́n tilẹ̀ lè sọ pé ó ti yẹ kó fi òpin sí gbogbo ètò àwọn nǹkan ayé yìí tipẹ́tipẹ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jónà rán wa létí pé bí èrò wa bá yàtọ̀ sí ti Jèhófà Ọlọ́run lórí ọ̀ràn kan, èrò tiwa ló máa nílò àtúnṣe. Kò ṣẹlẹ̀ rí pé èrò ti Jèhófà ni kò tọ́!

Bí Jèhófà Ṣe Kọ́ Jónà Lẹ́kọ̀ọ́

17, 18. (a) Kí ni Jónà ṣe lẹ́yìn tó kúrò ní ìlú Nínéfè? (b) Ipa wo ni bí Jèhófà ṣe mú kí ìtàkùn kan tó máa ń so akèrègbè hù kó sì tún gbẹ́ lọ́nà ìyanu ní lórí Jónà?

17 Ìbànújẹ́ ni Jónà bá kúrò nílùú Nínéfè, àmọ́ kò gba ìlú rẹ̀ lọ. Ńṣe ló forí lé apá ìlà oòrùn, níbi àwọn òkè ńlá kan téèyàn ti lè máa wo ìlú Nínéfè lọ́ọ̀ọ́kán. Ó pa àtíbàbà kékeré kan, ó jókòó sábẹ́ rẹ̀, ó wá ń retí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ìlú Nínéfè. Ó ṣeé ṣe kó ṣì máa retí pé kí Ọlọ́run pa ìlú náà run. Báwo ni Jèhófà ṣe máa kọ́ ọkùnrin olórí kunkun yìí láti jẹ́ aláàánú?

18 Kí ilẹ̀ ọjọ́ kejì tó mọ́, Jèhófà mú kí ìtàkùn kan tó máa ń so akèrègbè hù. Nígbà tí Jónà jí, ó rí i ti ewé ìtàkùn náà ti gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, àwọn ewé rẹ̀ tó rí fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ sì ṣẹ́ ibòji lé e lórí ju àtíbàbà gẹrẹjẹ tó pa lọ. Inú rẹ̀ dùn gan-an. “Jónà sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ gidigidi” torí ìtàkùn náà. Ó tiẹ̀ lè máa ronú pé bó ṣe hù lọ́nà ìyanu yẹn jẹ́ àmì pé inú Ọlọ́run dùn sí òun àti pé Ọlọ́run bù kún òun. Àmọ́, kì í wulẹ̀ ṣe pé Jèhófà fẹ́ dáàbò bo Jónà lọ́wọ́ oòrùn tàbí pé ó kàn fẹ́ kí inú tó ń bí i láìnídìí rọlẹ̀, ńṣe ló fẹ́ kó ronú jinlẹ̀. Torí náà, Ọlọ́run tún ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mìíràn. Ó mú kí kòkòrò mùkúlú kan jẹ ìtàkùn náà, kó lè gbẹ dà nù. Lẹ́yìn náà, ó mú kí “ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn amóhungbẹ hán-ún hán-ún” fẹ́ lu Jónà débi pé Jónà bẹ̀rẹ̀ sí í “dákú lọ” torí oòrùn tó ń pa á. Ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá Jónà, ó sì tún sọ pé kí Ọlọ́run kúkú gbẹ̀mí òun.—Jónà 4:6-8.

19, 20. Báwo ni Jèhófà ṣe mú kí Jónà ronú jinlẹ̀ lẹ́yìn tí ìtàkùn náà gbẹ?

19 Jèhófà tún bi Jónà bóyá ó tọ́ pé kó bínú torí pé ìtàkùn náà gbẹ. Dípò kí Jónà ronú pìwà dà, ńṣe ló dá ara rẹ̀ láre, ó ní: “Ríru tí inú mi ru fún ìbínú jẹ́ lọ́nà ẹ̀tọ́, títí dé ojú ikú.” Ìgbà yẹn gan-an ni Jèhófà wá lo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí láti kọ́ Jónà lẹ́kọ̀ọ́.—Jónà 4:9.

Ọlọ́run fi ìtàkùn tó máa ń so akèrègbè kọ́ Jónà lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdí tó fi yẹ kó jẹ́ aláàánú

20 Ọlọ́run ṣe àlàyé tó mú kí wòlíì rẹ̀ yìí ronú jinlẹ̀. Ó sọ fún un pé ó ń banú jẹ́ torí pé ìtàkùn lásán làsàn gbẹ, ìtàkùn tó ṣàdédé lalẹ̀ hù láìṣe pé òun ló gbìn ín, tí kò sì mọ nǹkan kan nípa bó ṣe dàgbà. Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wá sọ pé: “Ní tèmi, kò ha sì yẹ kí n káàánú fún Nínéfè ìlú ńlá títóbi nì, inú èyí tí àwọn ènìyàn tí ó ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà wà, tí wọn kò mọ ìyàtọ̀ rárá láàárín ọwọ́ ọ̀tún wọn àti òsì wọn, yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹran agbéléjẹ̀?”—Jónà 4:10, 11. *

21. (a) Kí ni Jèhófà fi ìtàkùn tó gbẹ náà kọ́ Jónà? (b) Báwo ni ìtàn Jónà ṣe lè mú ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò irú ẹni tá a jẹ́ gan-an?

21 Ǹjẹ́ o lóye ẹ̀kọ́ tí Jèhófà fẹ́ fi ìtàkùn tó gbẹ náà kọ́ Jónà? Jónà ò mọ nǹkan kan nípa bí ìtàkùn yẹn ṣe lalẹ̀ hù. Àmọ́ Jèhófà ló dá àwọn ará Nínéfè, òun ló sì ń pèsè fún wọn bó ti ń ṣe fún gbogbo ohun alààyè orí ilẹ̀ ayé. Kí wá ló fà á tí ìtàkùn kan ṣoṣo tó gbẹ dà nù á fi ká Jónà lára ju ẹ̀mí ọ̀kẹ́ mẹ́fà [120,000] èèyàn lọ, tó fi mọ́ gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn? Ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí pé Jónà ti fàyè gba ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan? Ó ṣe tán, àǹfààní tó rí lára ìtàkùn yẹn ló jẹ́ kó dùn ún nígbà tí ìtàkùn náà gbẹ. Bó bá rí bẹ́ẹ̀ kí ló wá mú kí Jónà bínú torí àwọn ará Nínéfè? Ó ní láti jẹ́ pé ìmọtara-ẹni-nìkan ló fà á. Kò fẹ́ kí òun sọ̀rọ̀ káwọn èèyàn má bá a bẹ́ẹ̀, kò sì fẹ́ kí wọ́n mú òun ní onírọ́. Ìtàn Jónà lè mú ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. Ta ni ìmọtara-ẹni-nìkan ò lè mú kó ronú bíi ti Jónà nínú wa? Àfi ká máa dúpẹ́ pé Jèhófà ń fi sùúrù kọ́ wa ká lè túbọ̀ máa ro tàwọn ẹlòmíì mọ́ tiwa, ká sì túbọ̀ jẹ́ aláàánú bíi tirẹ̀.

22. (a) Báwo ni ìtọ́ni tó bọ́gbọ́n mu tí Jèhófà fún Jónà nípa àánú ṣe ràn án lọ́wọ́? (b) Ẹ̀kọ́ wo ló pọn dandan pé kí gbogbo wa kọ́?

22 Ìbéèrè tó yẹ ká wá ìdáhùn sí ni pé, Ǹjẹ́ Jónà kẹ́kọ̀ọ́ látinú gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i? Ìbéèrè tí Jèhófà bi Jónà yẹn ló parí ìwé Jónà nínú Bíbélì. Kódà, ó ṣì wà bẹ́ẹ̀ títí di òní. Àwọn kan tó ń ṣe lámèyítọ́ lè máa sọ pé Jónà ò dáhùn ìbéèrè yẹn. Àmọ́ ìdáhùn Jónà wà níbẹ̀. Ìwé tí Jónà kọ yẹn ló fi dáhùn ìbéèrè náà. Ẹ̀rí fi hàn pé Jónà fúnra rẹ̀ ló kọ ìwé náà. Ìwọ náà fi ojú inú wo bí wòlíì yẹn ṣe ń fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ ìtàn yẹn sílẹ̀ lẹ́yìn tó pa dà dé ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ láyọ̀ àti àlàáfíà. Kó o sì tún wò ó pé ó ti dàgbà sí i, ó ti gbọ́n sí i, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sì ti pọ̀ sí i. Bó ṣe ń kọ àwọn àṣìṣe tó ṣe sílẹ̀, á máa mi orí á sì máa kábàámọ̀ pé òun ṣe irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀, pé òun ya aláìgbọràn àti pé òun kò láàánú. Ó dájú pé Jónà rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ látinú àwọn ìtọ́ni tó bọ́gbọ́n mu tí Jèhófà fún un. Ó kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ kí òun jẹ́ aláàánú. Ṣé àwa náà máa jẹ́ aláàánú?—Ka Mátíù 5:7.

^ ìpínrọ̀ 6 Àwọn tó ń ṣèwádìí ti fojú bù ú pé, ó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn tó ń gbé ní ìlú Samáríà, tó jẹ́ olú ìlú ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì, nígbà ayé Jónà tó ọ̀kẹ́ kan [20,000] sí ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000]. Ìyẹn ò tó ìdámẹ́rin àwọn tó ń gbé ní ìlú Nínéfè. Nígbà tí ìlú Nínéfè ṣì wà lójú ọpọ́n, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ni ìlú tó tóbi jù lọ láyé.

^ ìpínrọ̀ 8 Ó lè dà bíi pé ohun tí wọ́n ṣe yìí ṣàjèjì, àmọ́ tiwọn kọ́ làkọ́kọ́ láyé ìgbà yẹn. Òpìtàn Herodotus tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì sọ pé nígbà tí àwọn ará Páṣíà àtijọ́ ń ṣọ̀fọ̀ ikú olórí ogun kan tí wọ́n fẹ́ràn dáadáa, àwọn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ni wọ́n jọ ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àṣà wọn.

^ ìpínrọ̀ 20 Ọlọ́run sọ pé àwọn èèyàn wọ̀nyẹn ò mọ ìyàtọ̀ láàárín ọwọ́ ọ̀tún àti òsì. Èyí tó túmọ̀ sí pé wọn ò mọ àwọn ìlànà Ọlọ́run.