ÌBÉÈRÈ 10
Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?
KÍ LO MÁA ṢE?
Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: David ń wa mọ́tò lọ ní ibì kan tí kò dé rí. Àwọn àkọlé àtàwọn ilé tó ń rí jẹ́ kó mọ̀ pé ibi tóun ń lọ kọ́ lòun wà yìí. À ṣé David ti ṣìnà. Ó ní láti jẹ́ pé ó ti yà níbi tí kò yẹ kó ti yà.
Tó bá jẹ́ ìwọ ni David, kí lo máa ṣe?
RÒ Ó WÒ NÁ!
Ohun mélòó kan wà tó o lè ṣe:
-
O lè ní káwọn èèyàn júwe ọ̀nà fún ẹ.
-
O lè lo máàpù tàbí ẹ̀rọ tó máa ń jẹ́ kéèyàn mọ̀nà, ìyẹn GPS.
-
O lè máa wa mọ́tò ẹ̀ lọ, lérò pé tó bá pẹ́ tó o ti ń wa mọ́tò kiri, wàá débi tó ò ń lọ.
Ó ṣe kedere pé àbá kẹta yìí ò lè ṣiṣẹ́.
Èyí èkejì ṣì dáa jú àkọ́kọ́ lọ, ó ṣe tán, máàpù tàbí ẹ̀rọ̀ ajúwe-ọ̀nà á wà lọ́wọ́ ẹ títí tó o fi máa débi tó ò ń lọ, á sì máa sọ bó o ṣe máa rìn ín fún ẹ.
Bẹ́ẹ̀ náà ni Bíbélì ṣe lè tọ́ ẹ sọ́nà.
Ìwé tó tà jù lọ láyé ni Bíbélì, ó sì máa
-
tọ́ ẹ sọ́nà kó o lè yanjú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé
-
jẹ́ kó o mọ irú ẹni tíwọ fúnra ẹ jẹ́, á sì tún ayé ẹ ṣe
-
jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dáa jù lọ
BÓ O ṢE LÈ RÍ ÌDÁHÙN SÁWỌN ÌBÉÈRÈ PÀTÀKÌ NÍPA ÌGBÉSÍ AYÉ
Àtìgbà tá a ti mọ ọ̀rọ̀ sọ la ti ń béèrè ìbéèrè.
-
Kí ló dé tójú ọ̀run fi funfun?
-
Kí ni wọ́n fi dá àwọn ìràwọ̀?
Tó bá sì yá, àá bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè ìbéèrè nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé.
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ọjọ́ pẹ́ táwọn ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí ti wà nínú Bíbélì?
Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ pé ìtàn àròsọ àti ìtàn àtẹnudẹ́nu ló kún inú Bíbélì, pé kò wúlò lóde òní tàbí pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kì í tètè yéèyàn. Àmọ́, ṣé Bíbélì fúnra rẹ̀ ló níṣòro àbí ohun táwọn èèyàn ti gbọ́ nípa Bíbélì gangan ni ìṣòro? Ṣé kì í ṣe pé ibi tí wọ́n fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀?
Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn rò pé Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ló ń darí ayé. Báwo ló ṣe lè jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ayé yìí ti dà rú! Ó kún fún ìrora àti ìyà, àìsàn àti ikú, ipò òṣì àti àjálù. Ǹjẹ́ Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa lè fa gbogbo nǹkan yìí?
Ṣé wàá fẹ́ mọ ìdáhùn? Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu tó o bá mọ ẹni tí Bíbélì sọ pé ó ń darí ayé!
Wàá ti kíyè sí i pé orí Bíbélì ni gbogbo àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé yìí dá lé. Ó dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójú pé inú Bíbélì la ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó dára jù lọ. Ìdí sì ni pé “Ọlọ́run [ló] mí sí [Bíbélì], ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́.” (2 Tímótì 3:16, 17) O ò rí i pé ó yẹ kó o ṣàyẹ̀wò ìwé àtayébáyé tọ́rọ̀ inú ẹ̀ ṣì bágbà mu yìí!