ORÍ 12
Jésù Kọ́ Wa Bí A Ó Ṣe Máa Gbàdúrà
ǸJẸ́ o máa ń bá Jèhófà Ọlọ́run sọ̀rọ̀?— Ó fẹ́ kó o máa bá òun sọ̀rọ̀. Tó o bá ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, ìyẹn là ń pè ní àdúrà. Jésù sábà máa ń bá Baba rẹ̀ ní ọ̀run sọ̀rọ̀. Nígbà mìíràn ó máa ń fẹ́ nìkan wà nígbà tó bá ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Nígbà kan, Bíbélì sọ pé, “Ó gun òkè ńlá lọ ní òun nìkan láti gbàdúrà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ti lọ, ó wà níbẹ̀ ní òun nìkan ṣoṣo.”—Mátíù 14:23.
Ibo lo lè lọ láti nìkan gbàdúrà sí Jèhófà?— Bóyá o lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀ ní ìwọ nìkan nígbà tó o bá fẹ́ sùn ní alẹ́. Jésù sọ pé: “Nígbà tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ àti, lẹ́yìn títi ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ.” (Mátíù 6:6) Ǹjẹ́ o máa ń gbàdúrà sí Jèhófà ní alẹ́ kó o tó sùn?— Ó yẹ kó o máa ṣe bẹ́ẹ̀.
Jòhánù 11:41, 42) Jésù tún máa ń gbàdúrà nígbà tó bá ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ǹjẹ́ o máa ń lọ sí àwọn ìpàdé níbi tí wọ́n ti máa ń gbàdúrà?— Ẹni tó dàgbà ló sábà máa ń gbàdúrà níbẹ̀. Fetí sí ohun tó ń sọ dáadáa nítorí pé ó ń bá ọ sọ nǹkan kan fún Ọlọ́run. Nígbà náà, ìwọ yóò lè sọ pé “Àmín” tó bá gbàdúrà tán.
Jésù sì tún gbàdúrà nígbà tí àwọn èèyàn mìíràn wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ Jésù kú, Jésù gbàdúrà bí àwọn èèyàn ṣe wà lọ́dọ̀ rẹ̀ níbi tí wọ́n tẹ́ òkú Lásárù sí. (Ǹjẹ́ o mọ ohun tó túmọ̀ sí láti sọ pé “Àmín” nígbà tí a bá gbàdúrà tán?— Ó fi hàn pé inú rẹ dùn sí àdúrà yẹn. Ó túmọ̀ sí pé o fara mọ́ àdúrà yẹn, o sì fẹ́ kó jẹ́ àdúrà tìrẹ pẹ̀lú.
Jésù tún máa ń gbàdúrà nígbà tó bá fẹ́ jẹun. Ó máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún oúnjẹ rẹ̀. Ǹjẹ́ o máa ń gbàdúrà ṣáájú kó o tó jẹun nígbà gbogbo?— Ó dára ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún oúnjẹ wa ká tó bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́. Ẹlòmíràn lè gbàdúrà tí ẹ bá fẹ́ jẹun pa pọ̀. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé ìwọ nìkan lo fẹ́ jẹun ńkọ́? Tàbí tí àwọn tẹ́ ẹ jọ fẹ́ jẹun kò bá dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà ńkọ́?— Nígbà náà ó yẹ kó o gbàdúrà tìrẹ.
Ṣé o ní láti máa sọ̀rọ̀ sókè ní gbogbo ìgbà tó o bá ń gbàdúrà? Tàbí ǹjẹ́ Jèhófà yóò gbọ́ ohun tó o sọ tó o bá rọra sọ ọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́?— A lè
mọ ìdáhùn rẹ̀ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Nehemáyà. Ó jẹ́ ẹni tó ń sin Jèhófà, ó sì ń ṣiṣẹ́ ní ààfin Atasásítà ọba Páṣíà. Lọ́jọ́ kan, inú Nehemáyà bà jẹ́ gan-an nítorí ó gbọ́ pé wọ́n wó odi ìlú Jerúsálẹ́mù lulẹ̀. Jerúsálẹ́mù yìí ni ìlú pàtàkì jù lọ nínú ìlú àwọn èèyàn rẹ̀.Nígbà tí ọba béèrè lọ́wọ́ Nehemáyà pé kí ló dé tí inú rẹ̀ kò dùn, Nehemáyà kọ́kọ́ rọra gbàdúrà sínú. Lẹ́yìn náà, Nehemáyà wá sọ ohun tí kò jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn fún ọba, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí òun lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ tún odi ìlú náà kọ́. Kí ló ṣẹlẹ̀?—
Ọlọ́run gbọ́ àdúrà Nehemáyà. Ọba yìí sọ pé kí Nehemáyà lọ! Ọba náà tiẹ̀ tún fún Nehemáyà ní àwọn igi ńláńlá pé kó fi tún odi yẹn ṣe. Nítorí náà, Ọlọ́run lè gbọ́ àdúrà wa dáadáa, kódà tá a bá tiẹ̀ gbà á sínú.—Nehemáyà 1:2, 3; 2:4-8.
Wàyí o, ro ọ̀rọ̀
yìí wò. Ṣé ó yẹ kó o máa tẹrí ba nígbà tó o bá ń gbàdúrà? Ṣé ó yẹ kó o kúnlẹ̀? Kí lo rò pé ó yẹ ká ṣe?— Nígbà mìíràn tí Jésù bá fẹ́ gbàdúrà ó máa ń kúnlẹ̀. Nígbà mìíràn ó máa ń dìde dúró. Ní àwọn ìgbà kan ó gbé ojú rẹ̀ sókè wo ọ̀run nígbà tó ń gbàdúrà, gẹ́gẹ́ bó ti ṣe nígbà tó gbàdúrà nítorí Lásárù.Kí ni èyí fi hàn nígbà náà?— Ó fi hàn pé ipò tó o wà nígbà tó o fẹ́ gbàdúrà kọ́ ni ohun tó ṣe pàtàkì. Nígbà mìíràn yóò dára kí o tẹrí ba kí o sì di ojú rẹ. Nígbà mìíràn o tiẹ̀ lè kúnlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe. Ṣáà rántí pé a lè gbàdúrà sí Ọlọ́run nígbà tó bá wù wá ní ọ̀sán tàbí òru, yóò sì gbọ́ àdúrà wa. Ohun tó ṣe pàtàkì nípa àdúrà ni pé kí á gbà pé Jèhófà ń gbọ́ àdúrà wa. Ǹjẹ́ o gbà pé Jèhófà ń gbọ́ àdúrà rẹ?—
Kí ló yẹ kí á sọ tí a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà?— Sọ fún mi kí n gbọ́: Nígbà tí o bá ń gbàdúrà, kí lo máa ń sọ fún Ọlọ́run?— Ohun rere tí Jèhófà ṣe fún wa pọ̀ gan-an, ó sì tọ́ pé ká dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún nǹkan wọ̀nyẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— A lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún oúnjẹ tí à ń jẹ. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o tíì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ rí fún ojú ọ̀run tó dára, àwọn igi tó ní ewé, àti àwọn òdòdó tó lẹ́wà?— Òun náà ló dá wọn.
Nígbà kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé kí Jésù kọ́ àwọn bí àwọn yóò ṣe máa gbàdúrà. Olùkọ́ Ńlá náà wá kọ́ wọn, ó sì sọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ láti sọ nínú àdúrà fún wọn. Ǹjẹ́ o mọ nǹkan wọ̀nyẹn?— Gbé Bíbélì rẹ, kí o Mátíù orí kẹfà. Ní ẹsẹ kẹsàn-án sí ìkẹtàlá, a rí ohun tí àwọn èèyàn kan ń pè ní Baba Wa Tí Ń Bẹ Lọ́run tàbí Àdúrà Olúwa. Jẹ́ kí á kà á pa pọ̀.
ṣíA rí i níbí pé Jésù sọ pé ká gbàdúrà nípa orúkọ Ọlọ́run. Ó sọ pé ká gbàdúrà pé kí orúkọ Ọlọ́run di sísọ di mímọ́ tàbí pé kí á ya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́. Kí ni orúkọ Ọlọ́run?— Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà ni, ó sì yẹ ká fẹ́ràn orúkọ yẹn.
Ìkejì, Jésù kọ́ wa pé ká gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé. Ìjọba yìí ṣe pàtàkì nítorí pé òun ni yóò mú kí àlàáfíà wà nínú ayé tí yóò sì sọ ayé di Párádísè.
Ìkẹta, Olùkọ́ Ńlá náà sọ pé ká gbàdúrà pé kí á máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn tó wà ní ọ̀run ti ń ṣe. Bí a bá ń gbàdúrà bẹ́ẹ̀, àwa náà ní láti máa ṣe ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ká ṣe.
Lẹ́yìn náà, Jésù kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà fún oúnjẹ tá a máa jẹ lóòjọ́. Ó tún sọ pé ká máa bẹ Ọlọ́run pé kó máà bínú nígbà tí a bá ṣe ohun tí kò dára. Kí á sọ pé kí Ọlọ́run dárí jì wá. Ṣùgbọ́n kí Ọlọ́run tó dárí jì wá, àwa náà ní láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn tó bá ṣe ohun tá ò fẹ́ sí wa. Ṣé o máa ń tètè dárí jini?—
Ní ìparí rẹ̀, Jésù sọ pé kí á máa gbàdúrà pé kí Jèhófà Ọlọ́run dáàbò bò wá lọ́wọ́ Sátánì Èṣù ẹni burúkú yẹn. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ló jẹ́ ohun rere tí a lè sọ tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run.
Ó yẹ ká gbà gbọ́ pé Jèhófà ń gbọ́ àdúrà wa. Yàtọ̀ sí pé ká sọ fún un pé kó ràn wá lọ́wọ́, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Inú rẹ̀ máa ń dùn tí a bá sọ òtítọ́ fún un nínú àdúrà wa, tí a sì tọrọ àwọn nǹkan tó tọ́ nínú àdúrà wa. Yóò sì fún wa ní nǹkan wọ̀nyẹn. Ǹjẹ́ o gba ọ̀rọ̀ yìí gbọ́?—
Ìmọ̀ràn dáadáa síwájú sí i nípa àdúrà wà nínú Róòmù 12:12; 1 Pétérù 3:12; àti 1 Jòhánù 5:14.