ORÍ 14
Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dárí Jini
ǸJẸ́ ẹnì kan ti ṣe ohun tó dùn ẹ́ gan-an sí ẹ rí?— Ṣé ó pa ọ́ lára ni àbí ó sọ̀rọ̀ tó dùn ẹ́?— Ǹjẹ́ ó yẹ kí ìwọ náà ṣe ohun tó máa dun òun náà padà fún un?—
lú máa ń ṣe ohun tó máa dun onítọ̀hún padà fún un láti fi gbẹ̀san. Ṣùgbọ́n Jésù sọ pé ká máa dárí ji àwọn tó bá ṣe ohun tí kò dára sí wa. (Mátíù 6:12) Tó bá jẹ́ pé ìgbà púpọ̀ ni ẹnì kan ń ṣe ohun tó dùn wá ńkọ́? Ìgbà mélòó ni ká dárí jì í?—
Ohun tí Pétérù fẹ́ mọ̀ nìyẹn nígbà kan. Nítorí náà, lọ́jọ́ kan ó béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: ‘Ẹni tó ń ṣe nǹkan tí kò dára sí mi léraléra, ṣé ó yẹ kí n dárí jì í tó ìgbà méje?’ Ìgbà méje kò tó. Nítorí Jésù sọ pé: ‘Kí o dárí jini tó ìgbà àádọ́rin ó lé méje’ bí iye ìgbà tí ẹnì kan ṣe ohun tó dùn ọ́ bá pọ̀ tó bẹ́ẹ̀.
Iye ìgbà yẹn pọ̀ gan-an o! Tí ẹnì kan bá ń ṣe nǹkan búburú sí wa tí a sì ń kà á, a ò tiẹ̀ ní lè ka iye tó pọ̀ tó àádọ́rin ó lé méje ká tó máa gbàgbé wọn, àbí? Ẹ̀kọ́ tí Jésù sì fẹ́ kí á kọ́ nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yìí ni pé: Ká má ṣe gbìyànjú láti rántí iye ìgbà tí ẹnì kan ṣẹ̀ wá rárá. Tí wọ́n bá bẹ̀ wá pé ká dárí jì àwọn, ká dárí jì wọ́n.
Jésù fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa dárí
jini. Nítorí náà lẹ́yìn tó dáhùn ìbéèrè Pétérù tán, ó sọ ìtàn kan fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ṣé wàá fẹ́ gbọ́ ìtàn yẹn?—Ní ìgbà kan, ọba rere kan wà. Onínúrere ni. Kódà ó máa ń yá àwọn ẹrú rẹ̀ lówó tí wọ́n bá nílò owó. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé ọjọ́ tí ọba yìí fẹ́ kí àwọn ẹrú òun san owó tí wọ́n yá padà pé. Àmọ́, wọ́n mú ẹrú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó yá iye tó pọ̀ tó ọgọ́ta mílíọ̀nù owó. Owó tó pọ̀ rẹpẹtẹ nìyẹn o!
Ṣùgbọ́n ẹrú yìí ti ná
gbogbo owó tó yá lọ́wọ́ ọba pátá, kò sì rí owó ọba san padà. Ọba wá sọ pé kí wọ́n ta ẹrú náà. Ọba yìí tún sọ pé kí wọ́n ta ìyàwó ẹrú yìí àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo nǹkan tó ní. Kí wọ́n fi owó tí wọ́n rí látinú gbogbo nǹkan tí wọ́n tà yìí san owó ọba. Ǹjẹ́ o rò pé inú ẹrú yìí yóò dùn nígbà tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba yìí?—Ó kúnlẹ̀ síwájú ọba yìí ó bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ pé: ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fún mi láyè díẹ̀ sí i kí n fi ṣiṣẹ́, èmi yóò san gbogbo owó tí mo jẹ yín.’ Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni ọba yìí, kí lo máa ṣe sí ẹrú náà?— Àánú ẹrú yìí ṣe ọba. Nítorí náà, ọba dárí jì í. Ó sọ fún ẹrú rẹ̀ yìí pé kó má san owó kankan padà mọ́, kó má tiẹ̀ san kọ́bọ̀ padà nínú gbogbo ọgọ́ta mílíọ̀nù owó tó yá náà. Inú ẹrú yìí mà dùn gan-an o!
Ṣùgbọ́n kí ni ẹrú yìí ṣe lẹ́yìn náà? Ẹrú yìí jáde lọ, ó sì rí ẹrú mìíràn tó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún owó péré. Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í fún ẹrú ẹgbẹ́ ẹ̀ tó jẹ ẹ́ lówó lọ́rùn, ó ń sọ pé: ‘San ọgọ́rùn-ún owó tí o jẹ mí fún mi!’ Ǹjẹ́ o rò pé ó yẹ kí ẹrú yìí fún ẹnì kejì rẹ̀ lọ́rùn bẹ́ẹ̀, pàápàá lẹ́yìn tí ọba ti dárí jì í nítorí owó púpọ̀ rẹpẹtẹ tó jẹ ọba?—
Ṣé o rí i, ẹrú tó jẹ ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún owó yìí jẹ́ òtòṣì tí kò ní nǹkan kan rárá. Kò lè san owó náà padà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Nítorí náà, ó dọ̀bálẹ̀ síwájú ẹrú tí ó ni owó náà, ó sì ń bẹ̀ ẹ́ pé: ‘Jọ̀wọ́, fún mi láyè díẹ̀ sí i kí n fi ṣiṣẹ́, èmi yóò san owó tí mo jẹ ọ́.’ Ǹjẹ́ ó yẹ kí ẹrú yìí fún ẹrú bíi tirẹ̀ yìí láyè sí i kó fi ṣiṣẹ́?— Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni ẹrú tí wọ́n jẹ lówó yìí kí lo máa ṣe?—
Ọkùnrin yìí kò ní inú rere gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe ní inú rere. Ó fẹ́ fi ipá gba owó rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Nígbà tí ẹrú tó jẹ ẹ́ lówó yìí kò rí owó rẹ̀ san, ó sọ pé kí wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n. Àwọn ẹrú mìíràn rí gbogbo ohun tí ẹrú yìí ṣe, inú wọn kò sì dùn. Àánú ẹrú tó jù sí ẹ̀wọ̀n yìí ṣe wọ́n gan-an. Nítorí náà wọ́n lọ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọba.
Inú ọba pàápàá kò dùn sí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Ó wá bínú gan-an sí ẹrú tí kò dárí jini yìí. Nítorí náà, ó pe ẹrú náà ó sọ fún un pé: ‘Ìwọ ẹrú burúkú yìí, ǹjẹ́ mi ò dárí jì ọ́ pé kí o má ṣe san owó tí o jẹ mí? Ǹjẹ́ kò yẹ kí ìwọ náà dárí ji ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ?’
Ó yẹ kí ẹrú tí kò dárí jini yìí ti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ ọba rere yìí. Ṣùgbọ́n kò kẹ́kọ̀ọ́. Nítorí náà, ọba yìí ní kí wọ́n gbé ẹrú yìí jù sí ẹ̀wọ̀n títí di ìgbà tí òun náà bá san ọgọ́ta mílíọ̀nù owó tí ó jẹ padà. Nígbà tó sì ti wà nínú ẹ̀wọ̀n, kò lè rí owó ọba san padà láé. Ìyẹn fi hàn pé inú ẹ̀wọ̀n ni yóò kú sí.
Nígbà tí Jésù sọ ìtàn náà parí, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: ‘Bákan náà ni Baba mi ọ̀run yóò ṣe ṣe sí yín bí olúkúlùkù yín kò bá dárí ji arákùnrin rẹ̀ láti inú ọkàn-àyà yín wá.’—Mátíù 18:21-35.
Ṣé o mọ̀, gbogbo wa ló jẹ Ọlọ́run ní gbèsè gan-an. Kódà, ẹ̀mí
wa pàápàá Ọlọ́run ló fún wa! Nítorí náà, tí a bá fi gbèsè tí àwọn èèyàn ń jẹ wá wéra pẹ̀lú gbèsè tí àwa jẹ Ọlọ́run, gbèsè tí àwọn ẹlòmíràn ń jẹ wá kéré gan-an. Gbèsè tí àwọn mìíràn ń jẹ wá dà bí ọgọ́rùn-ún owó tí ẹrú kan jẹ ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n gbèsè tí a jẹ Ọlọ́run nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa dà bí ọgọ́ta mílíọ̀nù owó tí ẹrú yẹn jẹ ọba náà.Onínúrere ni Ọlọ́run. Lóòótọ́ a máa ń ṣe nǹkan tó burú, àmọ́ ó máa ń dárí jì wá. Kò ní mú ká san gbèsè wa tipátipá nípa gbígba ẹ̀mí wa kúrò lọ́wọ́ wa títí láé. Ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ tí a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé ni pé: Kí Ọlọ́run tó lè dárí jì wá, a ní láti kọ́kọ́ dárí ji àwọn èèyàn tó ṣẹ̀ wá. Ẹ̀kọ́ pàtàkì tó yẹ ká ronú lé lórí nìyẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?—
Torí náà, tí ẹnì kan bá ṣe ohun kan tó dùn ọ́, ṣùgbọ́n tó wá bẹ̀ ọ́ pé kí o máà bínú, kí lo máa ṣe? Ṣé o máa dárí jì í?— Tó bá jẹ́ pé ìgbà púpọ̀ ló ti ṣe ohun tó dùn ọ́ ńkọ́? Ṣé ìwọ yóò ṣì dárí jì í?—
Tó bá jẹ́ pé àwa ló ń bẹ ẹnì kan pé kí ó dárí jì wá, a máa fẹ́ kí ẹni náà dárí jì wá, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Nítorí náà, ó yẹ kí àwa náà dárí ji òun pẹ̀lú. Yàtọ̀ sí pé ká sọ ọ́ lẹ́nu pé a dárí jì í, a óò tún dárí jì í látinú ọkàn wá. Tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a fi hàn pé ní tòótọ́ a fẹ́ jẹ́ ọmọlẹ́yìn Olùkọ́ Ńlá náà.
Láti lè lóye ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa dárí jini, jẹ́ kí á ka Òwe 19:11; Mátíù 6:14, 15; àti Lúùkù 17:3, 4 pẹ̀lú.