Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 3

Ẹ̀dùn Ọkàn—Bí Ẹnì Kan Bá Ṣẹ̀ Wá

Ẹ̀dùn Ọkàn—Bí Ẹnì Kan Bá Ṣẹ̀ Wá

“Arábìnrin kan níjọ wa fẹ̀sùn kàn mí pé mo ji òun lówó. Nígbà táwọn ará gbọ́ sọ́rọ̀ yìí, wọn bẹ̀rẹ̀ sí í gbè sẹ́yìn rẹ̀ láìgbọ́ tẹnu mi. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó sọ fún mi pé òun tí wá mọ̀ pé èmi kọ́ ni mo jí owó òun. Lóòótọ́ ó bẹ̀ mí pé kí n máà bínú, àmọ́ nínú ọkàn mi, mi ò tíì dárí jì í torí pé ọ̀rọ̀ náà dùn mí gan-an.”—Linda.

ǸJẸ́ ẹnì kan nínú ìjọ ti ṣẹ ìwọ náà rí, tọ́rọ̀ náà sì dùn ọ́ dọ́kàn bíi ti Linda? Ó ṣeni láàánú pé àwọn kan ti jẹ́ kí ìwà àwọn míì nínú ìjọ bà wọ́n lọ́kàn jẹ́ débi pé wọ́n dẹwọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà nìyẹn?

Ǹjẹ́ Ẹnikẹ́ni Lè “Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”?

Ká sòótọ́, tí ẹnì tá a jọ jẹ́ ará bá ṣẹ̀ wá, ó máa ń dunni gan-an, ó sì lè máà rọrùn fún wa láti dárí ji onítọ̀hún. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó yẹ káwa Kristẹni máa nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú. (Jòhánù 13:34, 35) Torí náà, ọ̀rọ̀ náà lè ká wa lára gan-an pàápàá nítorí pé ẹni tá a jọ jẹ́ ará ló ṣẹ̀ wá.—Sáàmù 55:12.

Àmọ́ o, Bíbélì sọ pé ìgbà míì wà táwọn Kristẹni máa ń ṣẹ ara wọn tí wọ́n á sì fẹ̀sùn kan ara wọn. (Kólósè 3:13) Síbẹ̀, bí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò bá tíì ṣẹlẹ̀ síni, a kì í mọ̀ bó ṣe máa ń ṣòro tó láti dárí jini. Kí la wá lè ṣe tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo mẹ́ta nínú àwọn ìlànà Bíbélì tó máa ràn wá lọ́wọ́:

Baba wa Ọ̀run rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Kò sóhun tó pa mọ́ lójú Jèhófà. Ó mọ̀ bí wọ́n bá fìyà èyíkéyìí jẹ wá, ó sì mọ́ bí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ. (Hébérù 4:13) Àti pé, ó máa ń dun Jèhófà gan-an tá a bá ń jìyà. (Aísáyà 63:9) Jèhófà ò ní gbà kí “wàhálà tàbí inúnibíni . . . yà wá kúrò nínú ìfẹ́” rẹ̀, kódà kò ní gbà kí Kristẹni bíi tiwa mú kí òun fi wá sílẹ̀. (Róòmù 8:35, 38, 39) Ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà fìwà jọ Jèhófà, ká má jẹ́ kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni yà wá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀?

Dídárí jini kò túmọ̀ sí pé a gbàgbàkugbà. Ti pé a dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá kò túmọ̀ sí pé a fojú kéré ohun tó ṣe sí wa tàbí pé ohun tó ṣe tọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò túmọ̀ sí pé àwa la jẹ̀bi tàbí pé ọ̀rọ̀ náà kò dùn wá. Má gbàgbé pé Jèhófà kórìíra ẹ̀ṣẹ̀, àmọ́ ó máa ń dárí jini bó bá gbà pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 103:12, 13; Hábákúkù 1:13) Jèhófà fẹ́ ká fìwà jọ òun, ìdí nìyẹn tó fi ń rọ̀ wá pé ká máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá. Jèhófà kì í bínú sí wa títí láé.—Sáàmù 103:9; Mátíù 6:14.

Ó máa ṣe wá láǹfààní tá a bá ń darí jini. Lọ́nà wo? Wo àpẹẹrẹ kan. Ká sọ pé o bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ ó sì mú òkúta kékeré kan, o dì í mọ́wọ́, ó wá na apá rẹ síwájú. Bí òkúta náà kò bá pẹ́ lọ́wọ́ rẹ, apá lè má fi bẹ́ẹ̀ ro ẹ́. Àmọ́, ìṣẹ́jú mélòó ni wàá fi di òkúta náà mọ́wọ́ láìká apá kò? Ṣé wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá tàbí wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ? Ó dájú pé apá ò ní pẹ́ rò ẹ́. Kì í kú ṣe pé òkúta náà tóbi ju bó ṣe wà lọ, àmọ́ bí òkúta náà bá ṣe ń pẹ́ tó lọ́wọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni apá á ṣe túbọ̀ máa ro ẹ́. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí téèyàn bá ń gbé ìbínú sọ́kàn. Bí ohun tó ń bíni nínú bá ṣe pẹ́ lọ́kàn ẹni tó ni ọkàn èèyàn á ṣe bà jẹ́ tó, kódà bọ̀rọ̀ ọ̀hún ò bá tiẹ̀ tó nǹkan. Abájọ tí Jèhófà fí ń rọ̀ wá pé ká máa dárí jini. Ká sóòótọ́, ó máa ṣe wá láǹfààní tá a bá ń dárí jini.—Òwe 11:17.

Ó máa ṣe wá láǹfààní tá a bá ń darí jini

“Ṣe Ló Dà Bíi Pé Jèhófà Fúnra Rẹ̀ Ló Ń Bá Mi Sọ̀rọ̀”

Kí ló mú kí Linda darí ji arábìnrin tó fẹ̀sùn olè kàn án? Lára ohun tó ṣe ni pé ó ronú lórí ìdí tí Bíbélì fi ni ká máa dárí jini. (Sáàmù 130:3, 4) Linda rí i pé ó ṣe pàtàkì ká máa dárí jini torí pé tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà ò ní dárí ji àwa náà. (Éfésù 4:32–5:2) Ọ̀rọ̀ yìí mú kó ronú gan-an débi tó fi sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń bá mi sọ̀rọ̀.”

Nígbà tó yá, Linda gbọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn ó sì dárí ji arábìnrin náà. Ní báyìí, àwọn méjèèjì ti di kòríkòsùn. Èyí ti mú kí Linda máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó. Jẹ́ kó dá ìwọ náà lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè gbé ìbínú kúrò lọ́kàn kó o sì máa fayọ̀ sìn ín nìṣó.