ORÍ 15
Pọ́ọ̀lù “Ń Fún Àwọn Ìjọ Lókun”
Àwọn òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò ń ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ kí wọ́n lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́
Ó dá lórí Ìṣe 15:36–16:5
1-3. (a) Ta ló ń bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò báyìí, kí la sì lè sọ nípa ẹ̀? (b) Kí la máa kọ́ nínú orí yìí?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù àti ọ̀dọ́kùnrin kan ń rìn gba ọ̀nà gbágungbàgun bí wọ́n ṣe ń lọ láti ìlú kan sí ìlú míì. Pọ́ọ̀lù ń ronú nípa ọ̀dọ́kùnrin náà bó ṣe ń wò ó. Tímótì lorúkọ ọ̀dọ́kùnrin yẹn. Ọ̀dọ́ tó lókun dáadáa ni, ó sì ṣeé ṣe kó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogún ọdún tàbí kó jù bẹ́ẹ̀ lọ díẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń bá ìrìn àjò wọn lọ ni wọ́n túbọ̀ ń jìnnà sílé. Díẹ̀díẹ̀, wọ́n kúrò lágbègbè Lísírà àti Íkóníónì. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí wọn? Pọ́ọ̀lù mọ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀, torí pé ìgbà kejì rèé tó máa rìnrìn àjò míṣọ́nnárì. Ó mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìṣòro àti ewu làwọn máa dojú kọ. Ṣé ọ̀dọ́kùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ yìí á lè fara da àwọn ìṣòro náà?
2 Tímótì lè máa rò pé òun kéré jù láti ṣe irú iṣẹ́ yìí, àmọ́ Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé á lè ṣe é. Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ sígbà yẹn ti jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù gbà pé òun nílò ẹnì kan táá máa bá òun rìnrìn àjò. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé iṣẹ́ táwọn ń ṣe, ìyẹn bí wọ́n ṣe ń bẹ àwọn ìjọ wò, tí wọ́n sì ń fún àwọn ará lókun máa gba pé káwọn máa fohùn ṣọ̀kan, káwọ́n sì pinnu pé àwọn ò ní juwọ́ sílẹ̀. Kí ló lè mú kí Pọ́ọ̀lù rò bẹ́ẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ èdèkòyédè tó wáyé láàárín òun àti Bánábà tó sì mú kí wọ́n pínyà ló fà á.
3 Nínú orí yìí, a máa kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà yanjú èdèkòyédè. A tún máa mọ ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi ní kí Tímótì máa bá òun rìnrìn àjò, yàtọ̀ síyẹn, a máa túbọ̀ lóye iṣẹ́ pàtàkì táwọn alábòójútó àyíká ń ṣe lónìí.
“Ní Báyìí, Jẹ́ Ká Pa Dà Lọ Bẹ Àwọn Ará Wò” (Ìṣe 15:36)
4. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn láti ṣe nígbà tó rìnrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì?
4 Nínú orí tó ṣáájú, a rí báwọn arákùnrin mẹ́rin, ìyẹn Pọ́ọ̀lù, Bánábà, Júdásì àti Sílà ṣe jẹ́ kí àwọn ará tó wà ni ìjọ Áńtíókù mọ ìpinnu tí ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́, tí wọ́n sì fún wọn níṣìírí. Kí ni Pọ́ọ̀lù wá ṣe? Ó sọ fún Bánábà bí ìrìn àjò yẹn ṣe máa rí lọ́tẹ̀ yìí, ó sọ pé: “Ní báyìí, jẹ́ ká pa dà lọ bẹ àwọn ará wò ní gbogbo ìlú tí a ti kéde ọ̀rọ̀ Jèhófà, ká lè rí bí wọ́n ṣe ń ṣe sí.” (Ìṣe 15:36) Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù sọ pé káwọn kàn lọ kí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni o. Ìwé Ìṣe jẹ́ ká mọ ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi rìnrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì. Àkọ́kọ́ ni pé, á máa fi àwọn ìpinnu tí ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe jíṣẹ́ fáwọn ìjọ. (Ìṣe 16:4) Ìkejì ni pé, bí alábòójútó arìnrìn-àjò, Pọ́ọ̀lù múra tán láti gbé àwọn ará ró, kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára sí i. (Róòmù 1:11, 12) Báwo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì yìí?
5. Báwo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ń tọ́ àwọn ará kárí ayé sọ́nà, tí wọ́n sì ń fún wọn níṣìírí lóde òní?
5 Lónìí, Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Kristi ń lò láti darí ìjọ rẹ̀. Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró yìí máa ń tọ́ àwọn ìjọ kárí ayé sọ́nà, wọ́n sì máa ń fún àwọn ará níṣìírí. Wọ́n máa ń lo lẹ́tà, àwọn ìwé, àwọn àpilẹ̀kọ tó wà lórí ìkànnì, fídíó, àwọn ìpàdé àtàwọn ọ̀nà míì. Ìgbìmọ̀ Olùdarí tún máa ń sapá láti mọ bí nǹkan ṣe rí ní ìjọ kọ̀ọ̀kan. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń rán àwọn alábòójútó àyíká pé kí wọ́n lọ bẹ ìjọ wò. Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti yan ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn alàgbà tó tóótun kárí ayé láti di alábòójútó àyíká.
6, 7. Kí ni díẹ̀ lára isẹ́ táwọn alábòójútó àyíká máa ń ṣe?
6 Lóde òní, àwọn alábòójútó àyíká máa ń fìfẹ́ hàn sí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìjọ tí wọ́n ń bẹ̀ wò, wọ́n sì tún máa ń lo Bíbélì láti fún wọn níṣìírí. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀? Wọ́n máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ bíi Pọ́ọ̀lù. Ó gba Tímótì tó jẹ́ alábòójútó bíi tiẹ̀ níyànjú pé: “Wàásù ọ̀rọ̀ náà; máa ṣe bẹ́ẹ̀ láìfi falẹ̀ ní àkókò tó rọrùn àti ní àkókò tí kò rọrùn; máa báni wí, máa fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, máa gbani níyànjú, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ sùúrù àti ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó dáa. . . . Ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere.”—2 Tím. 4:2, 5.
7 Bá a ṣe rí i nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, alábòójútó àyíká àti ìyàwó ẹ̀, ìyẹn tó bá ti gbéyàwó, máa ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ará nínú ìjọ kí wọ́n lè jọ ṣiṣẹ́ ìwàásù lóríṣirísi ọ̀nà. Àwọn alábòójútó àyíká máa ń fìtara wàásù, olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ ni wọ́n, àpẹẹrẹ wọn sì máa ń ran àwọn ará lọ́wọ́. (Róòmù 12:11; 2 Tím. 2:15) Gbogbo àwọn alábòójútó àyíká yìí ni wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará dénú. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láti ran àwọn míì lọ́wọ́, wọ́n sì máa ń rìnrìn àjò lọ sáwọn ibi tó léwu, kódà nígbà tí ojú ọjọ́ ò bá dáa. (Fílí. 2:3, 4) Àwọn alábòójútó àyíká tún máa ń fún àwọn ará ní ìjọ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ń bẹ̀ wò níṣìírí, wọ́n máa ń kọ́ wọn, wọ́n sì máa ń sọ àwọn àsọyé tó dá lórí Bíbélì kí wọ́n lè fi gbà wọ́n níyànjú. Ọ̀pọ̀ àǹfààní ni gbogbo àwọn ará nínú ìjọ máa rí tí wọ́n bá ń ṣàyẹ̀wò ìwà àwọn alábòójútó àyíká, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn.—Héb. 13:7.
Ìṣe 15:37-41)
Wọ́n “Gbaná Jẹ” (8. Kí ni Bánábà ṣe nígbà tí Pọ́ọ̀lù ní káwọn lọ bẹ àwọn ará wò?
8 Bánábà fara mọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé káwọn lọ “bẹ àwọn ará wò.” (Ìṣe 15:36) Àwọn méjèèjì ti jọ ṣiṣẹ́ dáadáa, wọ́n sì ti mọ àwọn ará nínú àwọn ìjọ tí wọ́n fẹ́ lọ bẹ̀ wò. (Ìṣe 13:2–14:28) Torí náà, ó dájú pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ní kóun àti Bánábà ṣe mọ́gbọ́n dání. Àmọ́ ohun kan ṣẹlẹ̀. Ìwé Ìṣe 15:37 sọ pé: “Bánábà pinnu láti mú Jòhánù tí wọ́n ń pè ní Máàkù dání.” Bánábà ò dá a lábàá o. Ṣe ló “pinnu” láti mú Máàkù ìbátan rẹ̀ dání kí wọ́n lè jọ rìnrìn àjò míṣọ́nnárì náà.
9. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù ò fi fara mọ́ ohun tí Bánábà sọ?
9 Pọ́ọ̀lù ò fara mọ́ ohun tí Bánábà ṣo. Kí nìdí? Bíbélì sọ pé: “Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò fara mọ́ ọn pé kí wọ́n mú [Máàkù] dání, ó wò ó pé ó fi àwọn sílẹ̀ ní Panfílíà, kò sì bá wọn lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.” (Ìṣe 15:38) Máàkù bá Pọ́ọ̀lù àti Bánábà rìnrìn àjò míṣọ́nnárì àkọ́kọ́, àmọ́ kò bá wọn parí ìrìn àjò náà. (Ìṣe 12:25; 13:13) Kò pẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò yẹn tí Máàkù fi fi wọ́n sílẹ̀ ní Panfílíà, tó kúrò nídìí iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un, tó sì pa dà sílé ní Jerúsálẹ́mù. Bíbélì ò sọ ìdí tó fi pa dà, àmọ́ ó jọ pé Pọ́ọ̀lù ò fara mọ́ bí Máàkù ṣe fi wọ́n sílẹ̀. Ó sì ṣeé ṣe kó máa wò ó pé Máàkù ò ṣeé fọkàn tán.
10. Kí ni èdèkòyédè tó wáyé láàárín Pọ́ọ̀lù àti Bánábà yọrí sí?
10 Síbẹ̀, Bánábà fi dandan lé e pé òun á mú Máàkù dání. Pọ́ọ̀lù náà yarí pé òun ò gbà kó tẹ̀ lé àwọn. Ìṣe 15:39 sọ pé: “Ni àwọn méjèèjì bá gbaná jẹ, débi pé wọ́n pínyà.” Bánábà wọ ọkọ̀ òkun lọ sí erékùṣù Sápírọ́sì tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, ó sì mú Máàkù dání. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ṣì lọ síbi tí wọ́n pinnu pé wọ́n fẹ́ lọ. Bíbélì sọ pé: “Pọ́ọ̀lù mú Sílà, ó sì lọ lẹ́yìn tí àwọn ará gbàdúrà pé kí Jèhófà fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí i.” (Ìṣe 15:40) Wọ́n jọ rìn ‘gba Síríà àti Sìlíṣíà kọjá, wọ́n sì ń fún àwọn ìjọ lókun.’—Ìṣe 15:41.
11. Ìwà wo ló pọn dandan ká ní tó máa jẹ́ ká máa tètè yanjú èdèkòyédè tó bá wáyé láàárín àwa àtẹnì kan?
11 Ìtàn yìí rán wa létí pé aláìpé ni àwa náà. Ìgbìmọ̀ olùdarí rán Pọ́ọ̀lù àti Bánábà lọ sáwọn ìjọ, kí wọ́n lè ṣojú àwọn. Ó sì jọ pé Pọ́ọ̀lù náà wá di ara ìgbìmọ̀ olùdarí. Òótọ́ ni pé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà nífẹ̀ẹ́ ara wọn, àmọ́ ìtàn yìí jẹ́ ká rí i pé ìgbà kan wà tí wọ́n bínú síra wọn gan-an. Ṣé àwọn méjèèjì wá jẹ́ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín wọn fa ìjà tí ò ní tán nílẹ̀? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, wọ́n nírẹ̀lẹ̀, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Nígbà tó yá, wọ́n yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín wọn, wọ́n sì pa dà di ọ̀rẹ́. (Éfé. 4:1-3) Kódà, Pọ́ọ̀lù àti Máàkù tún ṣiṣẹ́ pa pọ̀. a—Kól. 4:10.
12. Bíi ti Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, irú ìwà wo ló yẹ káwọn alábòójútó ní lónìí?
12 Òótọ́ ni pé Bánábà àti Pọ́ọ̀lù bínú gan-an síra wọn, àmọ́ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ kọ́ nìyẹn. Ẹni tó ṣeé sún mọ́ tó sì lawọ́ ni wọ́n mọ Bánábà sí, kódà dípò táwọn àpọ́sítélì á fi máa pè é ní Jósẹ́fù tó jẹ́ orúkọ ẹ̀, Bánábà, tó túmọ̀ sí “Ọmọ Ìtùnú” ni wọ́n ń pè é. (Ìṣe 4:36) Bákàn náà, èèyàn pẹ̀lẹ́ ni wọ́n mọ Pọ́ọ̀lù sí, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ará. (1 Tẹs. 2:7, 8) Ó yẹ káwọn alàgbà títí kan àwọn alábòójútó àyíká fìwà jọ Bánábà àti Pọ́ọ̀lù, kí wọ́n nírẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará àtàwọn alàgbà bíi tiwọn.—1 Pét. 5:2, 3.
Wọ́n “Ròyìn Rẹ̀ Dáadáa” (Ìṣe 16:1-3)
13, 14. (a) Ta ni Tímótì, ibo sì ni Pọ́ọ̀lù ti bá a pàdé? (b) Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù kíyè sí Tímótì kó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? (d) Iṣẹ́ wo làwọn alàgbà gbé fún Tímótì?
13 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì, ó dé àwọn ìjọ tó wà ní Gálátíà. Nígbà tó yá, ó ‘dé Déébè àti Lísírà.’ Bíbélì sọ pé: “Ọmọ ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀ tó ń jẹ́ Tímótì, ọmọkùnrin obìnrin Júù kan tó jẹ́ onígbàgbọ́, àmọ́ Gíríìkì ni bàbá rẹ̀.”—Ìṣe 16:1. b
14 Ẹ̀rí fi hàn pé ìgbà tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ rìnrìn àjò wá sí agbègbè yẹn lọ́dún 47 Sànmánì Kristẹni ló pàdé àwọn mọ̀lẹ́bí Tímótì. Àmọ́ lẹ́yìn nǹkan bí ọdún méjì tàbí mẹ́ta tí Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì ló kíyè sí Tímótì tó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé, “àwọn ará . . . ròyìn [Tímótì] dáadáa.” Yàtọ̀ sí pé àwọn ará ìjọ tó wà nílùú ẹ̀ fẹ́ràn ẹ̀, ó tún lórúkọ rere láwọn ìjọ míì. Bíbélì sọ pé àwọn ará ní Lísírà àti Íkóníónì, tó wà ní nǹkan bí ọgbọ̀n (30) kìlómítà sí ìlú tí Tímótì ń gbé, sọ àwọn nǹkan tó dáa nípa rẹ̀. (Ìṣe 16:2) Ẹ̀mí mímọ́ wá darí àwọn alàgbà láti gbé iṣẹ́ pàtàkì kan lé Tímótì lọ́wọ́, ìyẹn láti di òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò kó lè máa ran Pọ́ọ̀lù àti Sílà lọ́wọ́.—Ìṣe 16:3.
15, 16. Kí ló mú kí Tímótì lórúkọ rere?
15 Kí ló mú kí Tímótì lórúkọ rere bọ́jọ́ orí ẹ̀ tiẹ̀ kéré? Ṣé bórí ẹ̀ ṣe pé, tí ìrísí ẹ̀ dáa, tó sì láwọn ẹ̀bùn míì ló mú kó lórúkọ rere? Ó lè jọ bẹ́ẹ̀ tá a bá fojú èèyàn wò ó. Kódà ìgbà kan wà tó jẹ́ pé bí ẹnì kan ṣe rí ni wòlíì Sámúẹ́lì wò. Àmọ́, Jèhófà rán Sámúẹ́lì létí pé: “Ọ̀nà tí èèyàn gbà ń wo nǹkan kọ́ ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan, torí pé ohun tí ó bá hàn síta ni èèyàn ń rí, ṣùgbọ́n Jèhófà ń rí ohun tó wà nínú ọkàn.” (1 Sám. 16:7) Torí náà, ohun tó mú káwọn ará ròyìn Tímótì dáadáa ni pé ó láwọn ìwà rere, kì í ṣe torí àwọn ẹ̀bùn tó ní.
16 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀pọ̀ nǹkan tó dáa nípa Tímótì. Pọ́ọ̀lù sọ nípa bí Tímótì ṣe ní ìwà rere, tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, àti bó ṣe ń ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ, tó sì ń ran àwọn ará lọ́wọ́. (Fílí. 2:20-22) Tímótì tún ní “ìgbàgbọ́ . . . tí kò ní ẹ̀tàn.”—2 Tím. 1:5.
17. Lónìí, báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Tímótì?
17 Lónìí, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló fìwà jọ Tímótì, torí pé wọ́n ń ṣe ohun tó wu Ọlọ́run. Ìyẹn wá mú kí wọ́n lórúkọ rere lọ́dọ̀ Jèhófà àtàwọn èèyàn ẹ̀ látìgbà kékeré wọn. (Òwe 22:1; 1 Tím. 4:15) Wọ́n ní ìgbàgbọ́ tí kò ní ẹ̀tàn, wọn ò sì gbé ìgbé ayé méjì. (Sm. 26:4) Bíi Tímótì, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì nínú ìjọ. Inú gbogbo àwọn ará tó wà nínú ìjọ ló máa ń dùn bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, tí wọ́n ń ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, tí wọ́n sì ń ṣèrìbọmi!
Wọ́n “Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Nínú Ìgbàgbọ́” (Ìṣe 16:4, 5)
18. (a) Àwọn àǹfààní wo ni Pọ́ọ̀lù àti Tímótì ní bí wọ́n ṣe jẹ́ òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò? (b) Báwo làwọn ìjọ ṣe jàǹfààní?
18 Ọ̀pọ̀ ọdún ni Pọ́ọ̀lù àti Tímótì fi ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Wọ́n ń lọ láti ìlú kan sí òmíì láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì ń jẹ́ iṣẹ́ tí ìgbìmọ̀ olùdarí rán wọn. Bíbélì sọ pé: “Bí wọ́n ṣe ń rin ìrìn àjò gba àwọn ìlú náà kọjá, wọ́n ń fi àwọn àṣẹ tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù ti pinnu lé lórí jíṣẹ́ fún wọn kí wọ́n lè máa pa wọ́n mọ́.” (Ìṣe 16:4) Ó dájú pé àwọn ará tẹ̀ lé ìtọ́ni tàwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù fún wọn yìí. Torí pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, “àwọn ìjọ túbọ̀ ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́.”—Ìṣe 16:5.
19, 20. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn Kristẹni máa ṣègbọràn sáwọn “tó ń mú ipò iwájú”?
19 Bákan náà, Jèhófà máa ń bù kún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí bá a ṣe ń ṣègbọràn sáwọn “tó ń mú ipò iwájú” láàárín wa. (Héb. 13:17) Torí pé nǹkan ń yí pa dà nínú ayé, ó ṣe pàtàkì káwa Kristẹni máa fọkàn sí ìtọ́ni tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń fún wa, ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni náà. (Mát. 24:45; 1 Kọ́r. 7:29-31) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ìgbàgbọ́ wa máa lágbára, a sì máa wà láìní àbààwọ́n nínú ayé.—Jém. 1:27.
20 Bí Pọ́ọ̀lù, Bánábà, Máàkù àtàwọn alàgbà míì tó jẹ́ ẹni àmì òróró ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe jẹ́ aláìpé, bẹ́ẹ̀ náà làwọn alábòójútó nínú ìjọ Kristẹni lónìí àtàwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe jẹ́ aláìpé. (Róòmù 5:12; Jém. 3:2) Àmọ́, torí pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń ṣe ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ láìkù síbì kan, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì, wọ́n ń fi hàn pé àwọn ṣeé fọkàn tán. (2 Tím. 1:13, 14) Èyí ń fáwọn ìjọ lókun, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.
a Wo àpótí náà, “ Máàkù Ní Ọ̀pọ̀ Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn.”
b Wo àpótí náà, “ Tímótì Ṣẹrú ‘Kí Ìhìn Rere Lè Máa Tẹ̀ Síwájú.’”