ORÍ 114
Kristi Ṣèdájọ́ Àgùntàn àti Ewúrẹ́
-
JÉSÙ SỌ ÀPÈJÚWE NÍPA ÀGÙNTÀN ÀTI EWÚRẸ́
Orí Òkè Ólífì ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣì wà. Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ àpèjúwe wúńdíá mẹ́wàá àti tálẹ́ńtì láti dáhùn ìbéèrè táwọn àpọ́sítélì rẹ̀ bi í nípa àmì tó máa fi hàn pé ó ti wà níhìn-ín àti àmì ìparí ètò àwọn nǹkan. Báwo ló ṣe wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ó sọ àpèjúwe kan sí i, ìyẹn nípa àgùntàn àti ewúrẹ́.
Jésù kọ́kọ́ ṣàlàyé ohun tó fẹ́ mẹ́nu bà nínú àpèjúwe náà, ó ní: “Tí Ọmọ èèyàn bá dé nínú ògo rẹ̀, tòun ti gbogbo áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà, ó máa jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀.” (Mátíù 25:31) Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé òun gan-an ni àpèjúwe yìí dá lé, torí ó sábà máa ń pe ara rẹ̀ ní “Ọmọ èèyàn.”—Mátíù 8:20; 9:6; 20:18, 28.
Ìgbà wo ni àpèjúwe yìí máa ṣẹ? Ó máa ṣẹ nígbà tí Jésù “bá dé nínú ògo rẹ̀” tòun ti àwọn áńgẹ́lì, tó sì jókòó “sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀.” Ó ti sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa “Ọmọ èèyàn tó ń bọ̀ lórí àwọsánmà ojú ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá” tóun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀. Ìgbà wo nìyẹn máa ṣẹlẹ̀? “Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú” ni. (Mátíù 24:29-31; Máàkù 13:26, 27; Lúùkù 21:27) Torí náà, ìgbà tí Jésù bá dé nínú ògo rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni àpèjúwe yìí máa ṣẹ. Kí ni Jésù máa wá ṣe nígbà yẹn?
Jésù ṣàlàyé pé: “Tí Ọmọ èèyàn bá dé . . . , a máa kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ síwájú rẹ̀, ó sì máa ya àwọn èèyàn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń ya àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára ewúrẹ́. Ó máa kó àwọn àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àmọ́ ó máa kó àwọn ewúrẹ́ sí òsì rẹ̀.”—Mátíù 25:31-33.
Jésù wá sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn àgùntàn tó yà sọ́tọ̀, tó sì ṣojúure sí, ó ní: “Ọba máa wá sọ fún àwọn tó wà ní ọ̀tún rẹ̀ pé: ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bù kún, ẹ jogún Ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín látìgbà ìpìlẹ̀ ayé.’” (Mátíù 25:34) Kí nìdí táwọn àgùntàn fi rí ojúure Ọba yẹn?
Mátíù 25:35, 36, 40, 46) Ọ̀run kọ́ ni wọ́n ti ṣe àwọn nǹkan rere yìí, torí kò sí aláìsàn lọ́run, ebi kì í sì í pa wọ́n lọ́run. Ó dájú pé àwọn arákùnrin Kristi tó wà láyé ni wọ́n ṣe ohun rere yìí fún.
Ọba náà ṣàlàyé pé: “Ebi pa mí, ẹ sì fún mi ní oúnjẹ; òùngbẹ gbẹ mí, ẹ sì fún mi ní nǹkan mu. Mo jẹ́ àjèjì, ẹ sì gbà mí lálejò; mo wà ní ìhòòhò, ẹ sì fi aṣọ wọ̀ mí. Mo ṣàìsàn, ẹ sì tọ́jú mi. Mo wà lẹ́wọ̀n, ẹ sì wá wò mí.” Nígbà táwọn àgùntàn yẹn, ìyẹn “àwọn olódodo” béèrè pé ìgbà wo làwọn ṣe àwọn nǹkan rere yìí, ó dáhùn pé: “Torí pé ẹ ti ṣe é fún ọ̀kan lára àwọn arákùnrin mi tó kéré jù lọ yìí, ẹ ti ṣe é fún mi.” (Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sáwọn ewúrẹ́ tó wà lápá òsì? Jésù sọ pé: “[Ọba náà] máa wá sọ fún àwọn tó wà ní òsì rẹ̀ pé: ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin tí a ti gégùn-ún fún, ẹ lọ sínú iná àìnípẹ̀kun tí a ṣètò sílẹ̀ fún Èṣù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀. Nítorí ebi pa mí, àmọ́ ẹ ò fún mi ní oúnjẹ; òùngbẹ gbẹ mí, àmọ́ ẹ ò fún mi ní nǹkan kan mu. Mo jẹ́ àjèjì, àmọ́ ẹ ò gbà mí lálejò; mo wà ní ìhòòhò, àmọ́ ẹ ò fi aṣọ wọ̀ mí; mo ṣàìsàn, mo sì wà lẹ́wọ̀n, àmọ́ ẹ ò tọ́jú mi.’” (Mátíù 25:41-43) Ìdájọ́ tó tọ́ sí àwọn ewúrẹ́ yẹn nìyẹn torí pé wọn ò ṣe ohun rere sáwọn arákùnrin Kristi tó wà láyé, bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe.
Àwọn àpọ́sítélì rí i pé kò sóhun tó lè yí ìdájọ́ ọjọ́ iwájú yìí pa dà. Jésù wá sọ fún wọn pé: “[Ọba] máa [sọ pé]: ‘Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, torí pé ẹ ò ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn tó kéré jù lọ yìí, ẹ ò ṣe é fún mi.’ Àwọn yìí máa lọ sínú ìparun àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”—Mátíù 25:45, 46.
Ìdáhùn tí Jésù fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ yìí máa jẹ́ kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń hùwà àti bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan.