ORÍ 72
Jésù Rán Àádọ́rin (70) Ọmọ Ẹ̀yìn Jáde Lọ Wàásù
-
JÉSÙ YAN ÀÁDỌ́RIN (70) ỌMỌ Ẹ̀YÌN Ó SÌ RÁN WỌN JÁDE LỌ WÀÁSÙ
Ó ti tó ọdún mẹ́ta báyìí tí Jésù ti ṣèrìbọmi, ọdún 32 S.K. sì ti ń parí lọ. Ṣe lòun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò ní Jerúsálẹ́mù níbi Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn. Ó jọ pé ìtòsí Jerúsálẹ́mù ni wọ́n ṣì wà. (Lúùkù 10:38; Jòhánù 11:1) Kódà, Jùdíà tàbí òdìkejì Odò Jọ́dánì lágbègbè Pèríà ló ti lo èyí tó pọ̀ jù nínú oṣù mẹ́fà tó lò kẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò sì tíì gbọ́ ìwàásù láwọn agbègbè yìí.
Ṣáájú ìgbà yẹn, lẹ́yìn Ìrékọjá ọdún 30 S.K., ọ̀pọ̀ oṣù ni Jésù fi wàásù ní Jùdíà títí dé Samáríà. Nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n ṣe Ìrékọjá ní ọdún 31 S.K., àwọn Júù fẹ́ pa á ní Jerúsálẹ́mù. Torí náà, Gálílì tó wà ní apá àríwá ni Jésù ti wàásù fún ọdún kan ààbọ̀. Láàárín àkókó yẹn, ọ̀pọ̀ ló di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Jésù wá dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ ní Gálílì, ó sì rán wọn jáde. Ó sọ pé: “Ẹ máa wàásù pé: ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’” (Mátíù 10:5-7) Ní báyìí, ohun tí Jésù ṣe ni pé ó ṣètò báwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù ní Jùdíà.
Ó yan àádọ́rin (70) ọmọ ẹ̀yìn, ó sì rán wọn jáde ní méjì-méjì. Èyí fi hàn pé àwọn tó fẹ́ wàásù ní ìpínlẹ̀ náà máa jẹ́ méjì-méjì lọ́nà márùndínlógójì (35). Ìdí sì ni pé “ìkórè pọ̀, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ò tó nǹkan.” (Lúùkù 10:2) Jésù rán àwọn àádọ́rin náà lọ síbi tí òun fúnra rẹ̀ ṣì máa dé. Ó fún wọn ní agbára láti mú àwọn aláìsàn lára dá, kí wọ́n sì máa kéde ìhìn rere tòun ti ń wàásù ṣáájú ìgbà yẹn.
Jésù ò sọ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn náà lọ máa kọ́ àwọn èèyàn nínú sínágọ́gù. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú ilé ló ti ní kí wọ́n lọ máa bá àwọn èèyàn. Jésù sọ fún wọn pé: “Ibikíbi tí ẹ bá ti wọ ilé kan, ẹ kọ́kọ́ sọ pé: ‘Àlàáfíà fún ilé yìí o.’ Tí ọ̀rẹ́ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín máa wá sórí rẹ̀.” Kí ni ìwàásù wọn máa dá lé? Jésù sọ pé: “Ẹ . . . sọ fún wọn pé: ‘Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́ ọ̀dọ̀ yín.’”—Lúùkù 10:5-9.
Ìtọ́ni tí Jésù fún àwọn àádọ́rin (70) náà ò yàtọ̀ sí èyí tó fún àwọn àpọ́sítélì méjìlá nígbà tó rán àwọn náà jáde ní nǹkan bí ọdún kan sẹ́yìn. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Àmọ́ ìsapá wọn máa jẹ́ káwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn ṣe tán láti tẹ́tí sí Jésù nígbà tó bá dé, ó sì dájú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa fẹ́ mọ Jésù tó jẹ́ Ọ̀gá wọn kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀.
Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn ọmọ ẹ̀yìn tó lọ wàásù náà pa dà sọ́dọ̀ Jésù. Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi sọ fún un pé: “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá tẹrí ba fún wa torí pé a lo orúkọ rẹ.” Ìdáhùn Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ìròyìn náà múnú rẹ̀ dùn, ó ní: “Mo rí i tí Sátánì já bọ́ bíi mànàmáná láti ọ̀run. Ẹ wò ó! Mo ti fún yín ní àṣẹ láti fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn ejò àti àkekèé mọ́lẹ̀.”—Lúùkù 10:17-19.
Jésù tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kó dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé ó máa ṣeé sé fún wọn láti borí ohunkóhun tó bá fẹ́ pa wọ́n lára, bí ìgbà tí wọ́n bá fẹsẹ̀ tẹ ejò àti àkekèé mọ́lẹ̀. Bákan náà, ó jẹ́ kó dá wọn lójú pé lọ́jọ́ iwájú Sátánì máa já bọ́ láti ọ̀run. Lẹ́yìn náà, Jésù jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Ó sọ pé: “Ẹ má yọ̀ torí pé a mú kí àwọn ẹ̀mí tẹrí ba fún yín, àmọ́ ẹ yọ̀ torí pé a ti kọ orúkọ yín sílẹ̀ ní ọ̀run.”—Inú Jésù dùn gan-an débi pé ojú gbogbo èèyàn tó wà níbẹ̀ ló ti ń yin Baba rẹ̀ fún bó ṣe ń lo àwọn ẹni rírẹlẹ̀ láti ṣe ohun ńlá bẹ́ẹ̀. Torí náà, ó yíjú sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ojú tó rí àwọn ohun tí ẹ̀ ń rí. Torí mò ń sọ fún yín pé, ó wu ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba pé kí wọ́n rí àwọn ohun tí ẹ̀ ń rí, àmọ́ wọn ò rí i, ó wù wọ́n kí wọ́n gbọ́ àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́, àmọ́ wọn ò gbọ́ ọ.”—Lúùkù 10:23, 24.