ORÍ 22
Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Mẹ́rin Di Apẹja Èèyàn
MÁTÍÙ 4:13-22 MÁÀKÙ 1:16-20 LÚÙKÙ 5:1-11
-
JÉSÙ NÍ KÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN ÒUN MÁA TẸ̀ LÉ ÒUN NÍGBÀ GBOGBO
-
ÀWỌN APẸJA DI APẸJA ÈÈYÀN
Lẹ́yìn tí àwọn ará Násárẹ́tì gbìyànjú láti pa Jésù, ó lọ sí ìlú Kápánáúmù tó wà nítòsí Òkun Gálílì tí wọ́n tún ń pè ní “adágún omi Jẹ́nẹ́sárẹ́tì.” (Lúùkù 5:1) Ìyẹn mú àsọtẹ́lẹ̀ ìwé Àìsáyà ṣẹ tó sọ pé àwọn ará Gálílì tó ń gbé nítòsí òkun máa rí ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò.—Àìsáyà 9:1, 2.
Nígbà tí Jésù dé Gálílì, ó ń bá a lọ láti polongo pé: “Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.” (Mátíù 4:17) Jésù rí mẹ́rin lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Àwọn àti Jésù ti jọ rìnrìn àjò tẹ́lẹ̀, àmọ́ nígbà tí wọ́n dé láti Jùdíà, ṣe ni wọ́n pa dà sídìí òwò ẹja pípa wọn. (Jòhánù 1:35-42) Àmọ́ ní báyìí, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n dúró ti Jésù kó lè dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lẹ́yìn tóun bá lọ.
Bí Jésù ṣe ń rìn ní etíkun, ó rí Símónì Pétérù, Áńdérù arákùnrin rẹ̀ àtàwọn tí wọ́n jọ ń pẹja bí wọ́n ṣe ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Ni Jésù bá wọnú ọkọ̀ Pétérù, ó sì ní kó wa ọkọ̀ náà kúrò létíkun lọ sójú omi. Nígbà tí Pétérù ṣe bẹ́ẹ̀, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èrò tó wà létíkun.
Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù sọ fún Pétérù pé: “Wa ọkọ̀ lọ síbi tí omi ti jìn, kí ẹ sì rọ àwọ̀n yín sísàlẹ̀ láti kó ẹja.” Pétérù dáhùn pé: “Olùkọ́, gbogbo òru la fi ṣiṣẹ́ kára, a ò sì rí nǹkan kan mú, ṣùgbọ́n torí ohun tí o sọ, màá rọ àwọ̀n náà sísàlẹ̀.”—Lúùkù 5:4, 5.
Nígbà tí wọ́n ju àwọ̀n wọn sínú omi, wọ́n kó ẹja tó pọ̀ débi pé àwọ̀n wọn bẹ̀rẹ̀ sí í ya! Kíá ni wọ́n ṣẹ́wọ́ sí àwọn tó wà nínú ọkọ̀ kejì pé kí wọ́n wá ran àwọn lọ́wọ́. Ni wọ́n bá rọ́ ẹja kún inú ọkọ̀ méjèèjì débi pé àwọn ọkọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Nígbà tí Pétérù rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó wólẹ̀ níwájú Jésù, ó sì sọ pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Olúwa, torí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.” Jésù wá sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù mọ́. Láti ìsinsìnyí lọ, wàá máa mú àwọn èèyàn láàyè.”—Lúùkù 5:8, 10.
Jésù sọ fún Pétérù àti Áńdérù pé: “Ẹ máa tẹ̀ lé mi, màá sì sọ yín di apẹja èèyàn.” (Mátíù 4:19) Ó tún pe àwọn apẹja méjì míì tó jẹ́ ọmọ Sébédè, ìyẹn Jémíìsì àti Jòhánù. Àwọn náà sì tẹ̀ lé e lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àwọn mẹ́rin yìí pa òwò ẹja pípa tì, wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn Jésù. Àwọn ló kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn Jésù tó ń wà pẹ̀lú rẹ̀ nígbà gbogbo.