Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 5

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Bí Jésù, Ibo sì Ni Wọ́n Bí I Sí?

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Bí Jésù, Ibo sì Ni Wọ́n Bí I Sí?

LÚÙKÙ 2:1-20

  • WỌ́N BÍ JÉSÙ SÍ BẸ́TÍLẸ́HẸ́MÙ

  • ÀWỌN OLÙṢỌ́ ÀGÙNTÀN WÁ KÍ JÉSÙ NÍGBÀ TÓ WÀ LỌ́MỌ ỌWỌ́

Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì tó jẹ́ alákòóso Róòmù pàṣẹ pé kí gbogbo èèyàn lọ forúkọ sílẹ̀. Torí náà, ó di dandan kí Jósẹ́fù àti Màríà rìnrìn àjò lọ sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, ìyẹn Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ní gúúsù Jerúsálẹ́mù.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló dé sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù torí kí wọ́n lè forúkọ sílẹ̀. Jósẹ́fù àti Màríà ò rí ibi tí wọ́n lè dé sí, ibì kan ṣoṣo tí àyè wà ni ilé ẹran tí wọ́n máa ń kó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àtàwọn ẹranko míì sí. Ibẹ̀ ni Màríà bí Jésù sí. Màríà wá fi aṣọ wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran, níbi tí wọ́n máa ń bu oúnjẹ ẹran sí.

Ó ní láti jẹ́ pé Ọlọ́run ló mú kí Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì ṣe òfin pé káwọn èèyàn lọ forúkọ sílẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé òfin yẹn ló mú kí wọ́n bí Jésù sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ Ọba Dáfídì baba ńlá rẹ̀. Ọjọ́ pẹ́ tí Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìlú yìí ni wọ́n máa bí Alákòóso tí Ọlọ́run ṣèlérí sí.—Míkà 5:2.

Alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù yìí mà ṣàrà ọ̀tọ̀ o! Nínú pápá táwọn olùṣọ́ àgùntàn kan ti ń bójú tó àgùntàn wọn, iná kan tó mọ́lẹ̀ yòò tàn yí wọn ká. Ògo Jèhófà ni! Ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run yọ sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù, torí, ẹ wò ó! mò ń kéde ìhìn rere ayọ̀ ńláǹlà fún yín, èyí tí gbogbo èèyàn máa ní. Torí lónìí, a bí olùgbàlà kan fún yín ní ìlú Dáfídì, òun ni Kristi Olúwa. Àmì tí ẹ máa rí nìyí: Ẹ máa rí ọmọ jòjòló kan tí wọ́n fi ọ̀já wé, tí wọ́n tẹ́ sínú ibùjẹ ẹran.” Lójijì, àwọn áńgẹ́lì míì fara hàn, wọ́n pọ̀ gan-an, wọ́n sì sọ pé: “Ògo ni fún Ọlọ́run ní ibi gíga lókè àti àlàáfíà fún àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà ní ayé.”—Lúùkù 2:10-14.

Nígbà táwọn áńgẹ́lì náà lọ, àwọn olùṣọ́ àgùntàn yẹn sọ fúnra wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ká lọ wo ohun tó ṣẹlẹ̀, ohun tí Jèhófà jẹ́ ká mọ̀.” (Lúùkù 2:15) Wọ́n yára lọ síbẹ̀, wọ́n sì rí Jésù níbi tí áńgẹ́lì náà sọ pé wọ́n á ti rí i. Nígbà táwọn olùṣọ́ àgùntàn náà ròyìn ohun tí áńgẹ́lì yẹn sọ fún wọn, ẹnu ya gbogbo àwọn tó gbọ́. Màríà mọyì gbogbo ohun tí wọ́n sọ, ó sì ń pa àwọn ọ̀rọ̀ náà mọ́ nínú ọkàn rẹ̀.

Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé December 25 ni wọ́n bí Jésù. Àmọ́ ní agbègbè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, àsìkò òjò àti òtútù ni December máa ń jẹ́. Kódà, yìnyín máa ń já bọ́ nígbà míì. Nírú àsìkò yẹn, kò dájú pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa wà pẹ̀lú àwọn àgùntàn wọn nínú pápá láti alẹ́ mọ́jú. Yàtọ̀ síyẹn, kò dájú pé alákòóso Róòmù máa pàṣẹ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn lọ forúkọ sílẹ̀ lásìkò òjò àti òtútù, tó sì jẹ́ pé àwọn èèyàn náà ti ń wá bí wọ́n ṣe máa ṣọ̀tẹ̀ sí i tẹ́lẹ̀. Torí náà, ẹ̀rí fi hàn pé nǹkan bí oṣù October ni wọ́n bí Jésù.