ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN
Ta Ni Olori?
‘Ẹ Lé Àwọn Olórí Wọn Kúrò Nílùú’
Ní July 13, ọdún 1957, Colón tó jẹ́ ọ̀gá ọlọ́pàá kọ̀wé sí aṣojú ìjọba nínú ọ̀ràn ilẹ̀ òkèèrè, ó ní: “Àwọn àgbà máa ń pa á lówe pé: ‘Tá a bá máa pa ejò, àfi ká fọ́ ọ lórí.’ Tá a bá fẹ́ pa ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà run yán-ányán nílẹ̀ yìí, àfi ká wá bá a ṣe máa lé àwọn míṣọ́nnárì wọn kúrò nílùú. Tá a bá ti mú àwọn olórí wọn kúrò, wọn ò ní ní aṣáájú mọ́, gbogbo ìsapá wọn á sì já sásán.”
Kété lẹ́yìn náà, Arturo Espaillat tó jẹ́ Aṣojú Ìjọba Nínú Ọ̀ràn Ààbò pàṣẹ pé kí àwọn míṣọ́nnárì mẹ́wàá yòókù fi ìlú sílẹ̀. Ní July 21, ọdún 1957, Roy Brandt kọ lẹ́tà sí Trujillo pé òun fẹ́ káwọn jọ ríra kóun lè sọ bí nǹkan ṣe rí fún un. Ara ohun tó kọ sínú lẹ́tà náà ni pé, “Bí àwọn kan ṣe ń tan irọ́ kálẹ̀ lórílẹ̀-èdè yìí torí pé wọ́n kórìíra orúkọ Jèhófà Ọlọ́run kò yàtọ̀ sí ohun tí àwọn kan fi àìmọ̀kan ṣe sí àwọn àpọ́sítélì Jésù.” Lẹ́yìn náà, Arákùnrin Brandt rọ Trujillo pé kó ka Ìṣe orí 2 sí 6, ó sì sọ fún un pé, “Ìmọ̀ràn àtàtà tó ṣe kedere tí Gàmálíẹ́lì Adájọ́ fún wọn nígbà yẹn ṣì wúlò gan-an lónìí bó ṣe wúlò nígbà yẹn.” Arákùnrin Brandt wá fa ọ̀rọ̀ inú Ìṣe 5:38, 39 yọ, ó sì fi lẹ́tà gàdàgbà kọ ọ́ pé: “FI ÀWỌN ỌKÙNRIN YÌÍ SÍLẸ̀ TORÍ TÓ BÁ JẸ́ IṢẸ́ ỌLỌ́RUN NI WỌ́N Ń ṢE, O LÈ WÁ RÍ I TÓ BÁ YÁ PÉ ỌLỌ́RUN LÒ Ń BÁ JÀ.” Àmọ́, ṣe ni Trujillo kọ etí ikún sọ́rọ̀ yìí. Ní August 3, ọdún 1957, wọ́n kó àwọn míṣọ́nnárì náà lọ sí pápákọ̀ òfuurufú, wọ́n sì wà wọ́n kúrò nílùú.
‘Jésù Ni Orí’
Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sáwọn ará yòókù lẹ́yìn táwọn míṣọ́nnárì ti lọ? Ṣé òótọ́ ni pé wọn ò ní ní “olórí” mọ́ bí Colón tó jẹ́ ọ̀gá ọlọ́pàá ṣe sọ? Ọ̀nà ò gba ibi tí wọ́n fojú sí torí pé Jésù ‘ni orí fún ara, èyíinì ni ìjọ.’ (Kól. 1:18) Torí náà, àwọn èèyàn Jèhófà ní Orílẹ̀-èdè Dominican kò ṣàìní “olórí.” Kódà, ṣe ni Jèhófà àti ètò rẹ̀ ń bá a nìṣó láti máa bójú tó wọn.
Arákùnrin Donald Nowills ni wọ́n yàn pé kó máa bójú tó ẹ̀ka ọ́fíìsì lẹ́yìn tí wọ́n ti fipá kó àwọn míṣọ́nnárì kúrò nílùú, ọmọ ogún [20] ọdún péré ni nígbà yẹn, kò sì tíì ju ọdún mẹ́rin lọ tó ṣèrìbọmi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣe alábòójútó àyíká fún oṣù mélòó kan nígbà yẹn, iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣàjèjì sí i. Arákùnrin Nowills ní ọ́fíìsì kékeré kan nílé rẹ̀, igi àti páànù ni wọ́n fi kọ́ ọ, ilẹ̀ eléruku ló sì wà níbẹ̀. Ibi tó léwu gan-an ní àgbègbè Gualey nílùú Ciudad Trujillo ni ọ́fíìsì náà wà. Òun àti Félix Marte ló máa ń ṣe ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ fún àwọn ará ní gbogbo orílẹ̀-èdè náà.
Arábìnrin Mary Glass tí Enrique, ọkọ rẹ̀ wà lẹ́wọ̀n ní gbogbo ìgbà yẹn náà máa ń ran Arákùnrin Nowills lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Màá ṣíwọ́ níbiiṣẹ́ tó bá di aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́, màá lọ sí ọ́fíìsì Arákùnrin Nowills kí n lè fi ẹ̀rọ tẹ Ilé Ìṣọ́. Arákùnrin Nowills á wá fi ẹ̀rọ ṣe ẹ̀dà ìwé náà. Lẹ́yìn náà ni arábìnrin kan tó wá láti Santiago tá a máa ń pè ní ‘áńgẹ́lì,’ á wá kó àwọn ìwé ìròyìn náà sí ìsàlẹ̀ òfìfo garawa òróró. Lẹ́yìn náà, á da aṣọ bo ìwé náà, á kó pákí, ọ̀dùnkún tàbí kókò sórí aṣọ náà, kó tó wá da àpò ìdọ̀họ bò ó. Lẹ́yìn yẹn, á gbé ẹrù náà wọnú ọkọ̀ èrò lọ sí apá àríwá orílẹ̀-èdè náà, á wá fún ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀dà kan ìwé náà. Àwọn ìdílé tó wà níbẹ̀ máa ń gba ìwé náà lọ́wọ́ ara wọn kí wọ́n lè fi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́.”
Arábìnrin Mary sọ pé: “A máa ń ṣọ́ra gan-an torí pé àwọn aṣojú ìjọba wà káàkiri ìgboro tí wọ́n fẹ́ mọ ibi tá a ti ń tẹ Ilé Ìṣọ́. Àmọ́ pàbó ni ìsapá wọn já sí. Jèhófà máa ń fi ààbò rẹ̀ bò wá nígbà gbogbo.”