Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Awon Ohun Pataki To Sele Lodun To Koja

Awon Ohun Pataki To Sele Lodun To Koja

Jèhófà Ọlọ́run mí sí wòlíì Aísáyà láti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Dípò bàbà, èmi yóò mú wúrà wá, àti dípò irin, èmi yóò mú fàdákà wá, àti dípò igi, bàbà, àti dípò àwọn òkúta, irin.” (Aísá. 60:17) Ní ọdún tó kọjá, a rí ẹ̀rí tó ṣe kedere pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣì ń ní ìmúṣẹ. Bó ṣe jẹ́ pé nǹkan túbọ̀ máa ń sunwọ̀n sí i téèyàn bá fi ohun èèlò tó túbọ̀ jẹ́ ojúlówó pààrọ̀ ti tẹ́lẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé àwọn àtúnṣe tó ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run ń mú kí àwọn nǹkan sunwọ̀n sí i.—Mát. 24:3.

NÍ APÁ YÌÍ

Ise N Yara Te Siwaju Niluu Warwick

O le mo bi ara awon eeyan se n ya gaga lenu ise kiko orileese tuntun ti awa Elerii Jehofa.

Eka To N Yaworan To si N Kole Kari Aye

Eka tuntun yii ni ise bantabanta lati se, won ni lati mu ki ise ile kiko ti o to 13,000 yara kankan.

Bibeli To Maa Lalope

Iwe Mimo ni Itumo Aye Tuntun ta a tun se lodun 2013 fani mora, o si maa lalope.

Ikorajo Awa Elerii Jehofa Ti Ero Po si Ju Lo

Ero ti ko tii po to bee ri kora ju fun ipade odoodun ti Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, ikokandinlaaadoje [129] iru re.

Iyasimimo Eka Ofiisi Orile-Ede Siri Lanka

A se atagba fidio ohun to n lo nigba itoleseese naa. Awon ara si ri ara won lati ibi otooto ti won wa.

Iroyin Nipa Awon Ejo

Won si n fi eto du awon Elerii Jehofa lati maa se esin to wu won.

Iroyin​​—Nipa Awon Ara Wa

Ki nidi ti awon odobinrin meji omo ile Jojia kan se fi owo ti won fe fi ra foonu setileyin?

‘A Ti Ri Awon Ohun Agbayanu’

Ki lo n sele lode oni ta a le fi we awon ise iyanu to sele nigba ti Jesu wa laye?