Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ 2017

Wo ohun tí a máa gbádùn ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àpéjọ yìí tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun tó dára, tí wàá sì lè máa fara da ìṣòro.

Friday

Kí ló máa ran àwọn Kristẹni tòótọ́ lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ tó yẹ kí wọ́n lè máa fara da ìṣòro?

Saturday

Báwo ni Ọlọ́run Olúdùmarè ṣe ń jẹ́ ká ní ìfaradà àti ìtùnú?

Sunday

Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” Kí ni wàá ṣe láti fi ọ̀rọ̀ tó sọ yìí sílò?

Ohun Tá A Fẹ́ Kí Àwọn Tó Wá Sí Àpéjọ Yìí Mọ̀

Tó o bá fẹ́, o lè lọ ṣí àwọn àkànṣe ìpàdé tá a máa ń ṣe nígbà àpéjọ. Ó tún lè ka apá yìí tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ohun tó sọ nù tá a rí he, àwọn tó ń bójú tó èrò, ìjókòó, ìrìbọmi, iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni, ìtọ́jú ráńpẹ́ tàbí ọrẹ.