ÌTÀN 114
Òpin Gbogbo Ìwà Búburú
KI LO rí níhìn-ín? Ohun tó o rí yẹn náà ni, àwọn ọmọ ogun lórí àwọn ẹṣin funfun. Ṣùgbọ́n ṣàkíyèsí ibi tí wọ́n ti ń bọ̀. Àwọn ẹṣin yẹn ń ṣe kútúpà-kútúpà bọ̀ láti ọ̀run nínú àwọsánmà! Ṣé ẹṣin wà lọ́run ni?
Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn ẹṣin yìí kì í ṣe ẹṣin gidi. Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé ẹṣin ò lè rìn lójú òfuurufú, àbí wọ́n lè rìn níbẹ̀? Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹṣin ní ọ̀run. Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀ tó fi sọ bẹ́ẹ̀?
Ìdí ni pé láwọn ìgbà kan, wọ́n máa ń lo àwọn ẹṣin gan-an nínú ogun jíjà. Nítorí náà, Bíbélì sọ nípa àwọn èèyàn tó ń gun ẹṣin láti ọ̀run láti fi hàn pé Ọlọ́run ní ogun kan tó máa bá àwọn olùgbé ayé jà. Ǹjẹ́ o mọ orúkọ ibi tí wọ́n á ti ja ogun yìí? Amágẹ́dọ́nì ni. Ogun yìí ló máa pa gbogbo ìwà búburú run kúrò lórí ilẹ̀ ayé.
Jésù lẹni tó máa jẹ́ aṣáájú nínú jíja ogun yìí ní Amágẹ́dọ́nì. Ṣó o rántí, Jésù lẹni tí Jèhófà yàn láti jẹ́ ọba Ìjọba Rẹ̀. Ìdí nìyí tí Jésù fi dé adé ọba. Idà ọwọ́ rẹ̀ sì fi hàn pé ó máa pa gbogbo ọ̀tá Ọlọ́run. Ṣó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Ọlọ́run máa pa gbogbo àwọn èèyàn búburú run?
Wo Ìtàn 10 lẹ́ẹ̀kan sí i. Kí lo rí níbẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, Ìkún-omi ńlá tó pa àwọn èèyàn búburú run. Ta ló mú Ìkún-omi yẹn wá? Jèhófà Ọlọ́run ni. Tún wo Ìtàn 15. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀? Jèhófà rán iná láti pa Sódómù àti Gòmórà run.
Ṣí ìwé rẹ sí Ìtàn 33. Wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹṣin àtàwọn kẹ̀kẹ́ ogun àwọn ará Íjíbítì. Ta ló mú kí omi yẹn pa wọ́n run? Jèhófà ni. Ó ṣe é láti dáàbò bò àwọn èèyàn rẹ̀. Wo Ìtàn 76. Wàá rí i níbẹ̀ pé Jèhófà tiẹ̀ jẹ́ kí wọ́n pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èèyàn rẹ̀ run, nítorí ìwà búburú wọn.
Nítorí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Jèhófà máa rán àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run rẹ̀ láti fi òpin sí gbogbo ìwà búburú tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n ṣáà ronú nípa ohun tí ìyẹn á túmọ̀ sí! Ṣí ìwé yìí síwájú kó o jẹ́ ká rí i.