ÌTÀN 110
Tímótì—Olùrànlọ́wọ́ Tuntun fún Pọ́ọ̀lù
TÍMÓTÌ ni ọ̀dọ́mọkùnrin tó ò ń wò tó dúró ti Pọ́ọ̀lù nínú àwòrán yìí. Tímótì ń gbé ní Lísírà lọ́dọ̀ Yùníìsì, ìyá rẹ̀, àti Lọ́ìsì, ìyá ìyá rẹ̀.
Ìgbà kẹta nìyí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bẹ Lísírà wò. Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ti kọ́kọ́ wá síbẹ̀ nígbà tí wọ́n ń rìnrìn àjò láti wàásù. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù àti Sílà ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni wọ́n jọ wá báyìí.
Ṣó o mọ ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ fún Tímótì? Ó ń béèrè pé: ‘Ṣé wàá fẹ́ láti tẹ̀ lé èmi àti Sílà? O lè ràn wá lọ́wọ́ láti wàásù fáwọn èèyàn tó wà ní ọ̀nà jíjìn.’
Tímótì dáhùn pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, màá lọ.’ Láìpẹ́ lẹ́yìn náà Tímótì fi ìdílé rẹ̀ sílẹ̀ ó sì bá Pọ́ọ̀lù àti Sílà lọ. Ṣùgbọ́n ká tó gbọ́ nípa ìrìn àjò wọn, jẹ́ ká wo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù. Ó ti tó nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlógún [17] tí Jésù ti fara hàn án lójú ọ̀nà Damásíkù.
Bó o bá rántí, Pọ́ọ̀lù wá sí Damásíkù láti pa àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lára, ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ ti di ọmọ ẹ̀yìn báyìí! Lẹ́yìn náà, àwọn kan tó jẹ́ ọ̀tá Pọ́ọ̀lù ń wá bí wọ́n á ṣe pa á torí pé inú wọn ò dùn sí bó se ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Jésù. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti sá kúrò níbẹ̀. Wọ́n gbé e sínú apẹ̀rẹ̀ kan wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sẹ́yìn odi.
Lẹ́yìn náà Pọ́ọ̀lù lọ sí Áńtíókù, ó sì ń wàásù níbẹ̀. Áńtíókù ọ̀hún ni wọ́n sì ti kọ́kọ́ pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní Kristẹni. Lẹ́yìn náà ni wọ́n rán Pọ́ọ̀lù àti Bánábà láti Áńtíókù kí wọ́n lè rìnrìn àjò lọ sáwọn ilẹ̀ tó jìn láti lọ wàásù níbẹ̀. Lára àwọn ìlú tí wọ́n bẹ̀ wò ní Lísírà, ìlú Tímótì.
Wàyí o, ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù tún padà lọ sí Lísírà nígbà ìrìn àjò ẹlẹ́ẹ̀kejì. Nígbà tí Tímótì bá Pọ́ọ̀lù àti Sílà lọ, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n lọ? Wo àwòrán ilẹ̀ yìí, kó o sì jẹ́ ká kọ́ nípa díẹ̀ lára àwọn ibi tí wọ́n lọ.
Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n lọ sí Íkóníónì tó wà nítòsí, àti sí ìlú kejì tó ń jẹ́ Áńtíókù. Lẹ́yìn yẹn ni wọ́n rìnrìn àjò lọ sí Tíróásì, wọ́n gba ibẹ̀ kọjá sí Fílípì, Tẹsalóníkà àti Bèróà. Ṣó o rí ibi tí Áténì wà nínú àwòrán ilẹ̀ yìí? Pọ́ọ̀lù wàásù débẹ̀. Lẹ́yìn náà ni wọ́n lo ọdún kan àtààbọ̀ láti fi wàásù ní Kọ́ríńtì. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n dúró díẹ̀ ní Éfésù. Kó tó di pé wọ́n wọkọ̀ ojú omi padà wá sí Kesaréà, tí wọ́n sì rìnrìn àjò dé Áńtíókù, níbi tí Pọ́ọ̀lù máa ń dé sí.
Tímótì rin ọgọ́rọ̀ọ̀rún ibùsọ̀ níbi tó ti ń ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti wàásù “ìhìn rere” àti láti dá àwọn ìjọ tuntun sílẹ̀. Bó o bá dàgbà, ṣé ìwọ náà máa di ìránṣẹ́ olóòótọ́ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi Tímótì?