ÌTÀN 106
Ìdáǹdè Kúrò Nínú Túbú
WO BÍ áńgẹ́lì yìí ṣe ṣí ilẹ̀kùn túbú sílẹ̀. Àpọ́sítélì Jésù làwọn ọkùnrin tí áńgẹ́lì yìí ń dá nídè. Jẹ́ ká wádìí ohun tó gbé wọn dénú ẹ̀wọ̀n.
Kò pẹ́ púpọ̀ sígbà tí Jésù tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyí: Pétérù àti Jòhánù ń wọnú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ lọ́sàn-án ọjọ́ kan. Wọ́n rí ọkùnrin kan tó ti yarọ láti kékeré lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà. Ojoojúmọ́ làwọn èèyàn máa ń gbé e wá síbẹ̀ kó bàa lè máa tọrọ owó lọ́wọ́ àwọn tó bá ń lọ sínú tẹ́ńpìlì. Nígbà tó rí Pétérù àti Jòhánù, ó bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n fún òun ní nǹkan. Kí ni àwọn àpọ́sítélì náà ṣe?
Wọ́n dúró, wọ́n sì wojú ọkùnrin tálákà náà. Pétérù sọ pé: ‘Kò sí owó lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n màá fún ọ ní ohun tí mo ní. Ní orúkọ Jésù, dìde kó o sì máa rìn!’ Pétérù di ọwọ́ ọ̀tún ọkùnrin náà mú, lójú ẹsẹ̀, ọkùnrin náà fò dìde ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn. Nígbà táwọn èèyàn rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ẹnu yà wọ́n, inú wọn sì dùn fún iṣẹ́ ìyanu yìí.
Pétérù sọ pé: ‘Nípa agbára Ọlọ́run, tó jí Jésù dìde kúrò nínú òkú la fi ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí.’ Níbi tí òun àti Jòhánù ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọn aṣáájú ìsìn kan dé. Inú bí wọn nítorí pé Pétérù àti Jòhánù ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde Jésù. Nítorí náà, wọ́n gbá wọn mú, wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n.
Lọ́jọ́ kejì àwọn aṣáájú ìsìn pe ìpàdé ńlá kan. Wọ́n mú Pétérù àti Jòhánù, pẹ̀lú ọkùnrin tí wọ́n wò sàn náà wọlé wá. Àwọn aṣáájú ìsìn wá bi wọ́n pé: ‘Nípa agbára wo lẹ fi ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí?’
Pétérù sọ fún wọn pé nípa agbára Ọlọ́run tó jí Jésù dìde kúrò nínú òkú ni. Àwọn àlùfáà náà ò mọ èyí tí wọn ì bá ṣe. Nítorí náà wọ́n kìlọ̀ fún àwọn àpọ́sítélì náà pé kí wọ́n má ṣe tún sọ̀rọ̀ nípa Jésù mọ́, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n lọ.
Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ àwọn àpọ́sítélì ń bá a nìṣó láti máa wàásù nípa Jésù, wọ́n sì ń mú àwọn aláìsàn lára dá. Ìròyìn nípa iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí sì ń tàn kálẹ̀. Nítorí náà, àwọn èèyàn láti ìlú tó wà láyìíká Jerúsálẹ́mù bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn aláìsàn wá sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì kí wọ́n lè wò wọ́n sàn. Èyí mú kí àwọn aṣáájú ìsìn náà máa jowú, nítorí náà wọ́n gbá àwọn àpọ́sítélì mú, wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Ṣùgbọ́n wọn ò pẹ́ níbẹ̀.
Lóru, áńgẹ́lì Ọlọ́run ṣí ilẹ̀kùn túbú yẹn, bó o ṣe ń wò ó nínú àwòrán yìí. Áńgẹ́lì náà sọ pé: ‘Ẹ lọ dúró nínú tẹ́ńpìlì, kẹ́ ẹ sì máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nìṣó.’ Lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì, nígbà táwọn aṣáájú ìsìn rán àwọn èèyàn lọ láti lọ mú àwọn àpọ́sítélì wá nínú ẹ̀wọ̀n, wọn ò bá wọn níbẹ̀. Lẹ́yìn náà ni wọn rí i tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n sì mú wọn wá sí gbọ̀ngàn Sànhẹ́dírìn.
Àwọn aṣáájú ìsìn sọ fún wọn pé: ‘A pàṣẹ fún yín gidigidi pé kí ẹ má ṣe kọ́ àwọn èèyàn nípa Jésù mọ́. Ṣùgbọ́n ẹ ti fi ẹ̀kọ́ yín kún Jerúsálẹ́mù.’ Àwọn àpọ́sítélì sì dáhùn pé: ‘Àwa gbọ́dọ̀ gbọ́ ti Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ ju ti ènìyàn lọ.’ Wọn ò dẹ́kun kíkọ́ àwọn èèyàn nípa “ìhìn rere.” Ǹjẹ́ àpẹẹrẹ rere tó yẹ ká tẹ̀ lé kọ́ lèyí bí?