ÌTÀN 100
Jésù Nínú Ọgbà
LẸ́YÌN tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kúrò nínú yàrá orí òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, wọ́n lọ sínú ọgbà Gẹtisémánì. Wọ́n ti máa ń wá sínú ọgbà yìí dáadáa. Jésù wá sọ fún wọn pé kí wọ́n wà lójúfò kí wọ́n sì máa gbàdúrà. Lẹ́yìn náà, ó rìn síwájú díẹ̀, ó sì dojú bolẹ̀ láti gbàdúrà.
Láìpẹ́ Jésù padà sí ibi táwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wà. Kí lo rò pé wọ́n ń ṣe? Wọ́n ti sùn lọ fọnfọn! Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù sọ fún wọn pé kí wọ́n máa ṣọ́nà, nígbà kọ̀ọ̀kan tó bá sì padà wá ló ń bá wọn lójú oorun. Jésù sọ nígbà tó padà wá kẹ́yìn tó tún bá wọn lójú oorun pé: ‘Ṣé irú àkókò tó yẹ kẹ́ ẹ máa sùn nìyí? Wákàtí tí wọ́n á fi mí lé àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́ ti dé.’
Ní àkókò yẹn gan-an ariwo ọ̀pọ̀ èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í dún. Wò ó! Idà àti kùmọ̀ ló wà lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin wọ̀nyí! Wọ́n tiẹ̀ tún gbé ògùṣọ̀ dání kí wọ́n bàa lè ríran. Nígbà tí wọ́n sún mọ́ tòsí, ẹnì kan jáde wá láti inú ọ̀pọ̀ èèyàn yẹn ó sì wá sọ́dọ̀ Jésù ní tààràtà. Ó fẹnu kò ó lẹ́nu, bó o ṣe ń wò ó nínú àwòrán yìí. Júdásì Ísíkáríótù ni ọkùnrin náà! Kí ni ìdí rẹ̀ tó fi fẹnu ko Jésù lẹ́nu?
Jésù bi í pé: ‘Júdásì, ṣé èmi lo fi ìfẹnukonu dà?’ Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, àmì ni Júdásì fi ìfẹnukonu ṣe. Ó jẹ́ kí àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú Júdásì lè dá Jésù mọ̀ pé òun ni ẹni tí wọ́n ń wá. Làwọn ọ̀tá Jésù bá jáde wá láti gbá a mú. Ṣùgbọ́n Pétérù ò fẹ́ gbà kí wọ́n mú Jésù lọ bẹ́ẹ̀. Ó fa idà kan tó mú wá jáde ó sì fi ṣá ọkùnrin kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Idà yẹn tàsé orí ọkùnrin náà ó sì gé etí rẹ̀ sọ nù. Ṣùgbọ́n Jésù fọwọ́ kan etí ọkùnrin yẹn ó sì wò ó sàn.
Jésù sọ fún Pétérù pé: ‘Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀. Ṣó o rò pé mi ò le béèrè lọ́wọ́ Bàbá mi pé kó fún mi ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún áńgẹ́lì láti gbà mí ni?’ Dájúdájú, ó lè béèrè! Ṣùgbọ́n Jésù ò béèrè, torí ó mọ̀ pé àkókò ti dé fún àwọn ọ̀tá òun láti mú òun. Nítorí náà ó gbà kí wọ́n mú òun lọ. Jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù lẹ́yìn náà.