Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 97

Jésù Dé Gẹ́gẹ́ Bí Ọba

Jésù Dé Gẹ́gẹ́ Bí Ọba

KÒ PẸ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí Jésù la ojú àwọn afọ́jú alágbe méjì yẹn, ó wá sí abúlé kékeré kan lẹ́bàá Jerúsálẹ́mù. Ó sọ fún méjì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: ‘Ẹ lọ sínú abúlé tí ẹ̀ ń wò yìí, ẹ ó sì rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so mọ́lẹ̀, ẹ tú u, kẹ́ ẹ sì mú un wá fún mi.’

Nígbà tí wọ́n mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yẹn wá fún un, Jésù jókòó lé e lórí. Ló bá ń gùn ún lọ sí Jerúsálẹ́mù tí kò jìnnà síbi tí wọ́n wà. Nígbà tó sún mọ́ etí ìlú náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn jáde wá láti pàdé rẹ̀. Púpọ̀ nínú wọn bọ́ ẹ̀wù wọn, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ojú ọ̀nà. Àwọn mìíràn já imọ̀ ọ̀pẹ lára igi ọ̀pẹ. Wọ́n sì kó wọn sí ojú ọ̀nà, wọ́n ń kígbe pé: ‘Kí Ọlọ́run bù kún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà!’

Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ní Ísírẹ́lì, àwọn ọba tuntun máa ń gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerúsálẹ́mù láti fi ara wọn han àwọn èèyàn. Ohun tí Jésù sì ń ṣe nìyí. Àwọn èèyàn wọ̀nyí sì ń fi hàn pé àwọn fẹ́ kí Jésù jẹ́ ọba àwọn. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo èèyàn ló fẹ́ bẹ́ẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù lọ sí inú tẹ́ńpìlì jẹ́ ká rí i bẹ́ẹ̀.

Nínú tẹ́ńpìlì, Jésù wo àwọn afọ́jú àti arọ sàn. Nígbà táwọn ọmọdé rí èyí, wọ́n ń kígbe yin Jésù. Ṣùgbọ́n èyí mú kí inú bí àwọn àlùfáà, wọ́n sì sọ fún Jésù pé: ‘Ṣó o gbọ́ ohun táwọn ọmọ wọ̀nyí ń sọ?’

Jésù dáhùn pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo gbọ́. Ṣé ẹ ò tíì ka èyí rí nínú Bíbélì ni pé, “Láti ẹnu àwọn ọmọ kéékèèké ni Ọlọ́run á ti mú ìyìn jáde?”’ Nítorí náà, àwọn ọmọdé yẹn ń yin Ọba tí Ọlọ́run yàn nìṣó.

A fẹ́ dà bí àwọn ọmọdé wọ̀nyẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àwọn kan lè fẹ́ dá wa dúró ká má bàa sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run mọ́. Ṣùgbọ́n a óò máa bá a lọ láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa àwọn ohun àgbàyanu tí Jésù máa ṣe fún àwọn èèyàn.

Àkókò kò tíì tó fún Jésù láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba nígbà tó wá sáyé. Ìgbà wo ni àkókò yìí máa dé? Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fẹ́ mọ̀. Wàá kà nípa rẹ̀ níwájú.