ÌTÀN 48
Àwọn Ará Gíbéónì Ọlọgbọ́n
Ọ̀PỌ̀ lára àwọn ìlú tó wà ní Kénáánì ti wá gbára dì báyìí láti bá Ísírẹ́lì jà. Wọ́n rò pé àwọn lè ṣẹ́gun. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn ìlú Gíbéónì tó wà nítòsí kò rò bẹ́ẹ̀. Wọ́n gbà pé Ọlọ́run ló ń ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́, wọn ò sì fẹ́ bá Ọlọ́run jà. Nítorí náà ǹjẹ́ o mọ ohun tí àwọn ará Gíbéónì ṣe?
Wọ́n díbọ́n láti ṣe bí ẹni pé ìlú kan tó jìnnà gidi gan-an ni ìlú àwọn. Nítorí náà, díẹ̀ lára wọn wọ àkísà aṣọ àti sálúbàtà tó ti gbó gan-an. Àwọn àpò tó ti gbó ni wọ́n fi di ẹrù sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì mú àkàrà gbígbẹ tó ti bu dání. Wọ́n wá tọ Jóṣúà lọ wọ́n sì wí pé: ‘Ọ̀nà jíjìn réré la ti wá nítorí tá a ti gbọ́ nípa Jèhófà, Ọlọ́run ńlá yín. A gbọ́ gbogbo ohun tó ṣe fún yín ní Íjíbítì. Nítorí náà làwọn aṣáájú wa fi sọ fún wa pé ká mú oúnjẹ díẹ̀ dání fún ìrìn àjò yìí ká sì wá sọ fún ọ pé: “Ìránṣẹ́ yín ni wá. Ṣèlérí fún wa pé ẹ ò ní bá wa jagun.” Ìwọ náà rí i pé aṣọ wa ti gbó mọ́ wa lára nítorí ọ̀nà jíjìn tá a ti rìn, àkàrà wa ti gbẹ ó sì ti bu.’
Jóṣúà àtàwọn aṣáájú yòókù gba àwọn ará Gíbéónì náà gbọ́. Nítorí náà wọ́n ṣèlérí pé àwọn ò ní bá wọn jagun. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, wọ́n gbọ́ pé itòsí gan-an ni àwọn ará Gíbéónì ń gbé.
Jóṣúà béèrè lọ́wọ́ wọn pé: ‘Kí ló dé tẹ́ ẹ fi sọ fún wa pé ọ̀nà jíjìn réré lẹ ti wá.’
Àwọn ará Gíbéónì náà dáhùn pé: ‘Àwa ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí a ti gbọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run yín ti ṣèlérí láti fi gbogbo ilẹ̀ Kénáánì yìí fún yín. Nítorí náà, ni ẹ̀rù ṣe bà wá pé ẹ̀yin yóò pa wá.’ Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa ìlérí wọn mọ́, wọn ò sì pa àwọn ará Gíbéónì. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fi wọ́n ṣe ìránṣẹ́ wọn.
Inú bí ọba Jerúsálẹ́mù gidigidi nítorí pé àwọn ará Gíbéónì ò fẹ́ bá Ísírẹ́lì jà. Nítorí náà ó wí fún àwọn ọba mẹ́rin mìíràn pé: ‘Ẹ wá ràn mí lọ́wọ́ láti bá Gíbéónì jà.’ Ohun táwọn ọba márààrún wọ̀nyí sì ṣe gan-an nìyẹn. Ǹjẹ́ àwọn ará Gíbéónì gbọ́n bí wọ́n ṣe sọ pé àwọn ò ní bá Ísírẹ́lì jà, èyí tó mú kí àwọn ọba wọ̀nyí wá bá wọn jà? A máa rí i.