Ẹ̀KỌ́ 14
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ní Ètò Kan?
1. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ṣètò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ bí àwùjọ kan?
Ọlọ́run ṣètò àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù kí wọ́n lè jẹ́ orílẹ̀-èdè kan, ó sì fún wọn ní àwọn òfin tí wọ́n á máa tẹ̀ lé. Ó pe orílẹ̀-èdè náà ní “Ísírẹ́lì,” ó sì fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ àwọn tó ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ àti ti àwọn tó ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. (Sáàmù 147:19, 20) Torí náà, àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè lè jàǹfààní látara Ísírẹ́lì.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 22:18.
Ọlọ́run yan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí òun. Ìtàn àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe fún wọn nígbà àtijọ́ jẹ́ ká mọ bí èèyàn ṣe lè jàǹfààní tó bá ń pa òfin Ọlọ́run mọ́. (Diutarónómì 4:6) Torí náà, àwọn míì lè wá mọ Ọlọ́run tòótọ́ nípasẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.—Ka Àìsáyà 43:10, 12.
2. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ṣètò àwọn Kristẹni tòótọ́?
Nígbà tó yá, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pàdánù ojú rere Ọlọ́run, Jèhófà sì fi ìjọ Kristẹni rọ́pò wọn. (Mátíù 21:43; 23:37, 38) Ní báyìí, àwọn Kristẹni tòótọ́ ló ń ṣe ẹlẹ́rìí fún Jèhófà dípò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.—Ka Ìṣe 15:14, 17.
Jésù ṣètò àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wàásù kí wọ́n sì máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 10:7, 11; 24:14; 28:19, 20) Ní báyìí, a ti wà ní ìparí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, iṣẹ́ yẹn sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé nínú ìtàn aráyé tí Jèhófà mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè wà níṣọ̀kan nínú ìsìn tòótọ́. (Ìfihàn 7:9, 10) Ọlọ́run ṣètò àwọn Kristẹni tòótọ́ kí wọ́n lè máa fún ara wọn ní ìṣírí, kí wọ́n sì máa ran ara wọn lọ́wọ́. Kárí ayé, wọ́n ń gbádùn ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan náà ní àwọn ìpàdé wọn.—Ka Hébérù 10:24, 25.
3. Báwo ni ètò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti òde òní ṣe bẹ̀rẹ̀?
Láàárín ọdún 1870 sí 1879, àwùjọ àwọn èèyàn mélòó kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàwárí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì tó ti dàwátì nínú ẹ̀sìn Kristẹni tipẹ́tipẹ́. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé Jésù ṣètò ìjọ Kristẹni láti wàásù, torí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíì. Nígbà tó di ọdún 1931, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Ka Ìṣe 1:8; 2:1, 4; 5:42.
4. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ṣètò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn ìjọ Kristẹni tó wà ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ jàǹfààní látinú ìtọ́ni tí wọ́n rí gbà látọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ olùdarí tó ń ṣojú fún Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ. (Ìṣe 16:4, 5) Bákan náà lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń jàǹfààní látinú ìtọ́ni tí à ń rí látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà tó nírìírí tí wọ́n wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Ìgbìmọ̀ yìí ló ń bójú tó àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi tá a ti ń túmọ̀ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì sí èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600), tá a ti ń tẹ̀ wọ́n, tá a sì ń pín wọn kiri. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí láti fún àwọn ìjọ tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) kárí ayé ní ìtọ́ni àti ìṣírí látinú Ìwé Mímọ́. Ní ìjọ kọ̀ọ̀kan, àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n ń ṣiṣẹ́ alàgbà tàbí alábòójútó. Àwọn ọkùnrin yìí sì ń fi ìfẹ́ bójú tó agbo Ọlọ́run.—Ka 1 Pétérù 5:2, 3.
Ọlọ́run ṣètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti wàásù ìròyìn ayọ̀ ká sì sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. A máa ń wàásù láti ilé dé ilé bíi ti àwọn àpọ́sítélì. (Ìṣe 20:20) A tún máa ń kọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ètò kan lásán. Ìdílé kan ṣoṣo ni wá, Baba wa sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Ńṣe la dà bí ọmọ ìyá, a sì nífẹ̀ẹ́ ara wa. (2 Tẹsalóníkà 1:3) Torí pé Jèhófà ṣètò àwọn èèyàn rẹ̀ kí wọ́n lè máa ṣe ohun tí òun fẹ́, kí wọ́n sì máa ran àwọn míì lọ́wọ́, àwọn ni ìdílé tó láyọ̀ jù lọ láyé.—Ka Sáàmù 33:12; Ìṣe 20:35.