ORÍ 8
“Èmi Yóò Yan Olùṣọ́ Àgùntàn Kan”
OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́rin tó dá lórí Mèsáyà àti bí wọ́n ṣe ṣẹ sí Kristi lára
1-3. Kí nìdí tínú Ìsíkíẹ́lì ò fi dùn rárá? Kí sì ni Jèhófà mí sí i láti kọ sílẹ̀?
Ó TI pé ọdún mẹ́fà báyìí tí Ìsíkíẹ́lì ti wà nígbèkùn. a Inú wòlíì yìí ò dùn rárá bó ṣe ń ronú nípa bí àwọn tó ń ṣàkóso Júdà ṣe sọ ilẹ̀ náà dìdàkudà, ìyẹn ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ tó wà nibi tó jìnnà réré. Oríṣiríṣi ọba ló ti jẹ ní ilẹ̀ náà.
2 Ìgbà tí olóòótọ́ Ọba Jòsáyà wà lórí ìtẹ́ ni wọ́n bí Ìsíkíẹ́lì. Ó dájú pé inú Ìsíkíẹ́lì máa dùn gan-an nígbà tó gbọ́ nípa bí Jòsáyà ṣe gbógun ti ìsìn èké, tó fọ́ àwọn ère tí wọ́n gbẹ́, tó sì mú kí wọ́n tún pa dà máa ṣe ìjọsìn mímọ́ ní Júdà. (2 Kíró. 34:1-8) Àmọ́ àwọn ìyípadà tí Jòsáyà ṣe yìí ò pẹ́ lọ títí, torí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọba tó jẹ lẹ́yìn rẹ̀ ni kò jáwọ́ nínú ìbọ̀rìṣà. Kò yà wá lẹ́nu nígbà náà láti rí i pé ṣe ni orílẹ̀-èdè náà túbọ̀ jingíri sínú ìjọsìn àìmọ́ àti ìwà ìbàjẹ́ ní gbogbo àkókò táwọn ọba búburú yẹn wà lórí ìtẹ́. Ṣé ọ̀nà àbáyọ máa wà báyìí? Ó dájú pé ó máa wà!
3 Jèhófà mí sí wòlíì rẹ̀ olóòótọ́ yìí láti kọ àsọtẹ́lẹ̀ kan sílẹ̀, èyí tó jẹ́ àkọ́kọ́ lára ohun tó ṣì máa kọ nípa Mèsáyà, Alákòóso àti Olùṣọ́ Àgùntàn tó máa mú kí ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò pátápátá, tó sì máa fìfẹ́ bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Ó yẹ ká fara balẹ̀ yẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn wò, torí pé ìmúṣẹ wọn máa nípa lórí ìwàláàyè wa títí láé lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́rin tó dá lórí Mèsáyà bó ṣe wà nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì.
“Ọ̀mùnú Múlọ́múlọ́” Di “Igi Kédárì Ńlá”
4. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Ìsíkíẹ́lì sọ? Báwo sì ni Jèhófà ṣe bẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà?
4 Ní nǹkan bí ọdún 612 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ‘Jèhófà bá Ìsíkíẹ́lì sọ̀rọ̀,’ ó sì mú kó sọ àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ́ ká mọ bí àkóso Mèsáyà ṣe máa gbòòrò tó àti ìdí tó fi yẹ ká fọkàn tán Ìjọba rẹ̀. Bí Jèhófà ṣe bẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ni pé, ó sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé kó sọ àlọ́ kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn láti ṣàpèjúwe bí àwọn alákòóso Júdà ṣe ya aláìnígbàgbọ́ tó, kí wọ́n sì lè rí i pé wọ́n nílò Àkóso Mèsáyà tó jẹ́ olódodo.—Ìsík. 17:1, 2.
5. Àlọ́ wo ni Jèhófà ní kí Ìsíkíẹ́lì pa?
5 Ka Ìsíkíẹ́lì 17:3-10. Bí àlọ́ náà ṣe lọ nìyí: “Ẹyẹ idì ńlá” kan já ọ̀mùnú tó wà lókè pátápátá lórí igi kédárì kan, ó lọ gbìn ín “sí ìlú àwọn oníṣòwò.” Ẹyẹ idì náà wá mú “lára irúgbìn ilẹ̀ náà” ó sì gbìn ín sórí ilẹ̀ tó lọ́ràá “lẹ́gbẹ̀ẹ́ alagbalúgbú omi.” Irúgbìn náà rú jáde, ó dàgbà, ó sì di ‘àjàrà tó bolẹ̀.’ Lẹ́yìn náà, “ẹyẹ idì ńlá” míì fò wá. Gbòǹgbò àjàrà náà wá ‘yára lọ’ sọ́dọ̀ ẹyẹ idì kejì yìí, ó fẹ́ kí ẹyẹ idì náà lọ gbin òun síbòmíì tó lómi dáadáa. Inú Jèhófà ò dùn rárá sí ohun tí àjàrà yìí ṣe, ó sì sọ pé wọ́n máa fa gbòǹgbò rẹ̀ tu àti pé ṣe ló máa “gbẹ dà nù.”
6. Kí ni ìtúmọ̀ àlọ́ náà?
6 Kí ni ìtúmọ̀ àlọ́ náà? (Ka Ìsíkíẹ́lì 17:11-15.) Lọ́dún 617 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Nebukadinésárì Ọba Bábílónì (ìyẹn “ẹyẹ idì ńlá” àkọ́kọ́) gbógun wá sí Jerúsálẹ́mù. Ó mú Jèhóákínì Ọba Júdà (ìyẹn ‘ọ̀mùnú tó wà lókè pátápátá’) kúrò lórí ìtẹ́, ó sì mú un wá sí Bábílónì (ìyẹn “ìlú àwọn oníṣòwò”). Nebukadinésárì fi Sedekáyà (tó jẹ́ ọ̀kan lára “irúgbìn ilẹ̀ náà” tó ń jọba) sórí ìtẹ́ ní Jerúsálẹ́mù. Wọ́n ní kí ọba tuntun tó jẹ ní Júdà yìí fi orúkọ Ọlọ́run búra pé òun á máa fi ara òun sábẹ́ ọba Bábílónì nígbà gbogbo, òun á sì jẹ́ olóòótọ́ sí i. (2 Kíró. 36:13) Àmọ́ Sedekáyà ò ka ìbúra yẹn sí; ó ṣọ̀tẹ̀ sí Bábílónì nígbà tó fẹ́ jagun, ó wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ Fáráò ní Íjíbítì (ìyẹn “ẹyẹ idì ńlá” kejì), àmọ́ pàbó ni ìsapá rẹ̀ já sí. Inú Jèhófà ò dùn rárá sí ìwà àìṣòótọ́ àti ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí Sedekáyà hù yìí. (Ìsík. 17:16-21) Nígbà tó yá, wọ́n gbàjọba lọ́wọ́ rẹ̀, inú ẹ̀wọ̀n ló sì kú sí ní Bábílónì.—Jer. 52:6-11.
7. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àlọ́ tí wọ́n fi sàsọtẹ́lẹ̀ yìí?
7 Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àlọ́ tí wọ́n fi sàsọtẹ́lẹ̀ yìí? Àkọ́kọ́ ni pé, ó yẹ kí àwa olùjọsìn tòótọ́ máa mú ìlérí wa ṣẹ. Jésù sọ pé ká jẹ́ kí, ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ wa jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ wa sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́. (Mát. 5:37) Tá a bá rí i pé ó pọn dandan pé ká fi Ọlọ́run búra pé á máa sọ òtítọ́, bóyá tọ́rọ̀ bá délẹ̀ nílè ẹjọ́, a kì í ka irú ìbúra bẹ́ẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré lásán. Ohun kejì ni pé ó yẹ ká ṣọ́ra ká má lọ gbára lé ẹni tí kò yẹ. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé àwọn olórí, tàbí lé ọmọ èèyàn, tí kò lè gbani là.”—Sm. 146:3.
8-10. Kí ni Jèhófà fi ṣàpèjúwe Mèsáyà tó máa ṣàkóso? Báwo sì ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ? (Tún wo àpótí náà, “Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà—Igi Kédárì Ńlá.”)
8 Àmọ́, alákòóso kan wà tó yẹ ká gbára lé, ká sì fọkàn tán pátápátá. Lẹ́yìn tí wòlíì yìí sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọ̀mùnú tí wọ́n lọ gbìn síbòmíì, Jèhófà lo àpèjúwe kan náà yẹn láti jẹ́ ká mọ Mèsáyà tó máa ṣàkóso lọ́jọ́ iwájú.
9 Ohun tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà. (Ka Ìsíkíẹ́lì 17:22-24.) Lọ́tẹ̀ yìí, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ṣe ohun tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, kì í ṣe ẹyẹ idì ńlá náà. Ó máa já ọ̀mùnú múlọ́múlọ́ kan ‘ní téńté orí igi kédárì tó ga fíofío, ó sì máa gbìn ín sórí òkè tó ga fíofío.’ Ọ̀mùnú náà máa dàgbà di “igi kédárì ńlá,” ó sì máa di ibùgbé fún “oríṣiríṣi ẹyẹ.” “Gbogbo igi oko” á wá mọ̀ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló mú kí igi ńlá náà gbèrú.
10 Bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ. Jèhófà mú Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, látinú ìdílé Ọba Dáfídì (ìyẹn “igi kédárì tó ga fíofío”), ó sì gbìn ín sí Òkè Síónì ti ọ̀run (ìyẹn “òkè tó ga fíofío”). (Sm. 2:6; Jer. 23:5; Ìfi. 14:1) Jèhófà tipa báyìí mú Ọmọ rẹ̀, táwọn ọ̀tá kà sí ‘ẹni tó rẹlẹ̀ jù nínú àwọn èèyàn,’ ó sì gbé e ga ní ti pé ó fi sórí “ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀.” (Dán. 4:17; Lúùkù 1:32, 33) Bíi ti igi kédárì ńlá yẹn, Jésù Kristi, Mèsáyà Ọba, máa ṣàkóso gbogbo ayé, ó sì máa mú ìbùkún wá fún gbogbo àwọn tó wà lábẹ́ ìjọba rẹ̀. Òun gan-an ni Alákòóso tá a lè fọkàn tán. Lábẹ́ òjìji Ìjọba Jésù, àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ onígbọràn ‘máa gbé lábẹ́ ààbò. Ìbẹ̀rù àjálù ò sì ní yọ wọ́n lẹ́nu’ mọ.—Òwe 1:33.
11. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ọ̀mùnú múlọ́múlọ́” tó wá di “igi kédárì ńlá”?
11 Ohun tá a rí kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà. Àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá nípa “ọ̀mùnú múlọ́múlọ́” tó wá di “igi kédárì ńlá” ti jẹ́ ká rí ìdáhùn sí ìbéèrè pàtàkì yìí pé: Ta ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé? Kò ní bọ́gbọ́n mu láti gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìjọba èèyàn àtàwọn nǹkan ìjà wọn. Tá a bá fẹ́ ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tòótọ́, àfi ká gbẹ́kẹ̀ lé Mèsáyà Ọba, ìyẹn Jésù Kristi, ká sì fọkàn tán an pátápátá. Ìjọba ọ̀run tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ nìkan ṣoṣo ni ọ̀nà àbáyọ fún gbogbo aráyé.—Ìfi. 11:15.
“Ẹni Tó Lẹ́tọ̀ọ́ sí I Lọ́nà Òfin”
12. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kó ṣe kedere pé òun ò gbàgbé májẹ̀mú tí òun bá Dáfídì dá?
12 Látinú àlàyé tí Ọlọ́run mí sí Ìsíkíẹ́lì láti ṣe nípa àlọ́ tó fi sàsọtẹ́lẹ̀ tó dá lórí ẹyẹ idì méjì náà, Ìsíkíẹ́lì lóye pé wọ́n máa rọ Sedekáyà lóye, ìyẹn ọba aláìṣòótọ́ tó wá láti ìlà ìdílé Ọba Dáfídì, ó sì máa lọ sígbèkùn ní Bábílónì. Ó ṣeé ṣe kí wòlíì náà máa ṣe kàyéfì pé, ‘Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Dáfídì dá ńkọ́? Ìyẹn ìlérí tó ṣe fún Dáfídì pé ọba kan látinú ìdílé rẹ̀ máa ṣàkóso títí láé.’ (2 Sám. 7:12, 16) Tó bá jẹ́ lóòótọ́ ni ìbéèrè yìí ń jà gùdù lọ́kàn Ìsíkíẹ́lì, kò ní pẹ́ rárá tó fi máa rí ìdáhùn. Ní nǹkan bí ọdún 611 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ọdún keje tí wọ́n ti wà nígbèkùn, tí Sedekáyà sì ń jọba ní Júdà, ‘Jèhófà bá Ìsíkíẹ́lì sọ̀rọ̀.’ (Ìsík. 20:2) Jèhófà mú kí Ìsíkíẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ míì nípa Mèsáyà, èyí tó jẹ́ kó ṣe kedere pé Ọlọ́run ò gbàgbé májẹ̀mú tó bá Dáfídì dá. Àsọtẹ́lẹ̀ náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Mèsáyà tí Ọlọ́run máa fi jọba lọ́jọ́ iwájú máa lẹ́tọ̀ọ́ lọ́nà òfin láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ Dáfídì.
13, 14. Kí ló wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìsíkíẹ́lì 21:25-27? Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ?
13 Ohun tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà. (Ka Ìsíkíẹ́lì 21:25-27.) Jèhófà tipasẹ̀ Ìsíkíẹ́lì bá “ìjòyè burúkú ti Ísírẹ́lì” sọ̀rọ̀ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, torí àsìkò tó máa jìyà ti tó. Jèhófà sọ fún alákòóso burúkú náà pé wọ́n máa ṣí “láwàní” àti “adé” tàbí dáyádémà orí rẹ̀ kúrò (ìyẹn àmì tó fi hàn pé ọba ni). Nígbà náà, àwọn alákòóso tó “rẹlẹ̀” ni a máa gbé ga, tá a sì máa rẹ àwọn “ẹni gíga” sílẹ̀. Àwọn tá a bá gbé ga yìí á wá máa ṣàkóso títí “ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí i lọ́nà òfin fi máa dé,” ẹni yẹn sì ni Jèhófà máa fún ní Ìjọba náà.
14 Bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ. Nígbà tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìjọba Júdà tó jẹ́ ìjọba “gíga” tó fìdí kalẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù ni a rẹ̀ wálẹ̀ nígbà tí àwọn ará Bábílónì pa ìlú náà run, tí wọ́n rọ Ọba Sedekáyà lóyè, tí wọ́n sì mú un lọ sígbèkùn. Ó wá di pé kò sí ọba kankan láti ìdílé Ọba Dáfídì lórí ìtẹ́ mọ́ ní Jerúsálẹ́mù. Ìjọba àwọn Kèfèrí tó jẹ́ ìjọba tó “rẹlẹ̀” ni a wá gbé ga, tí wọ́n sì ń ṣàkóso gbogbo ayé. Àmọ́ ìjọba wọn kì í ṣe títí lọ. Àkókò Àwọn Kèfèrí, tàbí “àkókò tí a yàn fún àwọn orílẹ̀-èdè,” parí ní ọdún 1914 nígbà tí Jèhófà fi Jésù Kristi jọba. (Lúùkù 21:24) Ká sòótọ́, Jésù ‘lẹ́tọ̀ọ́ lọ́nà òfin,’ láti wà lórí ìtẹ́ Ìjọba Mèsáyà torí pé àtọmọdọ́mọ Ọba Dáfídì ni. b (Jẹ́n. 49:10) Torí náà, bí Jèhófà ṣe fa ìjọba lé Jésù lọ́wọ́, ó mú ìlérí tó ṣe fún Dáfídì ṣẹ pé òun máa fún àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ní Ìjọba tó máa wà títí láé.—Lúùkù 1:32, 33.
15. Kí nìdí tó fi yẹ ká fọkàn tán Jésù Kristi Ọba?
15 Ohun tá a rí kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà. A lè fọkàn tán Jésù Kristi, Ọba wa láìṣiyèméjì rárá. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù ò dà bí àwọn alákòóso ayé, tí àwọn èèyàn máa ń dìbò yàn tàbí tí wọ́n ń fipá gbàjọba, Jèhófà ló yan Jésù sípò tó sì “fún un ní . . . ìjọba” tó lẹ́tọ̀ọ́ sí lọ́nà òfin. (Dán. 7:13, 14) Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká fọkàn tán Ọba tí Jèhófà fúnra rẹ̀ yàn sípò!
“Dáfídì Ìránṣẹ́ Mi” Yóò “Di Olùṣọ́ Àgùntàn Wọn”
16. Báwo lọ̀rọ̀ àwọn àgùntàn Jèhófà ṣe máa ń rí lára Jèhófà? Irú ọwọ́ wo ni “àwọn olùṣọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì” fi ń mú agbo nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì?
16 Jèhófà, Olùṣọ́ Àgùntàn Gíga Jù Lọ, ka àwọn àgùntàn rẹ̀ sí pàtàkì gan-an, ìyẹn àwa tá à ń jọ́sìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Sm. 100:3) Nígbà tó fa iṣẹ́ àbójútó àwọn àgùntàn rẹ̀ lé àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà lábẹ́ ìdarí rẹ̀ lọ́wọ́, ìyẹn àwọn èèyàn tó wà nípò àṣẹ, ó ń kíyè sí irú ọwọ́ tí wọ́n fi mú àwọn àgùntàn rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wá fojú inú wo bọ́rọ̀ “àwọn olùṣọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì” ṣe máa rí lára Jèhófà nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì. Àwọn aṣáájú yẹn ò nítìjú rárá, “ọwọ́ líle” ni wọ́n fi ń mú àwọn èèyàn Jèhófà, wọ́n sì ń “hùwà ìkà” sí wọn. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ fojú àwọn àgùntàn Jèhófà rí màbo, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì pa ìjọsìn mímọ́ tì.—Ìsík. 34:1-6.
17. Kí ni Jèhófà ṣe láti gba àwọn àgùntàn rẹ̀ sílẹ̀?
17 Kí ni Jèhófà wá ṣe sọ́rọ̀ náà? Ó sọ fún àwọn olórí Ísírẹ́lì tó ń ni àwọn èèyàn lára pé òun á “mú kí wọ́n jíhìn.” Ó sì ṣèlérí pé òun ‘máa gba àwọn àgùntàn òun sílẹ̀.’ (Ìsík. 34:10) Jèhófà máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nígbà gbogbo. (Jóṣ. 21:45) Lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó gba àwọn àgùntàn rẹ̀ sílẹ̀, ó lo àwọn ará Bábílónì tó wá gbógun ti ilẹ̀ náà láti gbàjọba lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí kò mọ̀ ju tara wọn lọ yẹn. Àádọ́rin (70) ọdún lẹ́yìn náà, ó gba àwọn olùjọsìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni bí àgùntàn sílẹ̀ lóko ẹrú Bábílónì, ó sì kó wọn pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, kí wọ́n lè mú kí ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò níbẹ̀. Àmọ́ àwọn àgùntàn Jèhófà ò tíì bọ́ nínú ewu, torí àwọn ìjọba ayé á ṣì máa lo agbára lórí wọn. “Àkókò tí a yàn fún àwọn orílẹ̀-èdè” ṣì máa gba ọ̀pọ̀ ọdún kó tó dópin.—Lúùkù 21:24.
18, 19. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Ìsíkíẹ́lì sọ lọ́dún 606 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)
18 Àmọ́ lọ́dún 606 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run, ìyẹn ní ọ̀pọ̀ ọdún kí Jèhófà tó gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ lóko ẹrú Bábílónì, Jèhófà mí sí Ìsíkíẹ́lì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó jẹ́ ká mọ bí Jèhófà, Olùṣọ́ Àgùntàn Gíga Jù Lọ, ṣe ka àǹfààní ayérayé tó fẹ́ kí àwọn àgùntàn rẹ̀ ní sí pàtàkì tó. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ bí Mèsáyà tó máa jẹ́ Alákòóso ṣe máa bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà.
19 Ohun tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà. (Ka Ìsíkíẹ́lì 34:22-24.) Ọlọ́run máa “yan olùṣọ́ àgùntàn kan” tó pè ní “Dáfídì ìránṣẹ́ mi.” Ọ̀rọ̀ yẹn, “olùṣọ́ àgùntàn kan,” àti bó ṣe lo “ìránṣẹ́” láti tọ́ka sí ẹnì kan pàtó fi hàn pé Alákòóso yẹn ò ní mú kí àwọn ọba tún máa jẹ tẹ̀ léra ní ìdílé Dáfídì, àmọ́ ó ń tọ́ka sí àtọmọdọ́mọ Dáfídì kan ṣoṣo tó máa wà títí lọ. Olùṣọ́ Àgùntàn àti Alákòóso yìí á máa bọ́ àwọn àgùntàn Ọlọ́run, ó sì máa di “ìjòyè láàárín wọn.” Jèhófà máa ‘bá àwọn àgùntàn rẹ̀ dá májẹ̀mú àlàáfíà.’ “Ìbùkún á rọ̀ bí òjò” lé wọn lórí, ọkàn wọn á balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, ara máa tù wọ́n, wọ́n á gbèrú, wọ́n á sì máa pọ̀ sí i. Ó dájú pé àlàáfíà máa gbilẹ̀, kì í ṣe láàárín àwọn èèyàn nìkan, àmọ́ láàárín èèyàn àti ẹranko pàápàá!—Ìsík. 34:25-28.
20, 21. (a) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa “Dáfídì ìránṣẹ́ mi,” ṣe ṣẹ? (b) Ìtumọ̀ wo ni ọ̀rọ̀ Ìsíkíẹ́lì nípa “májẹ̀mú àlàáfíà” ní fún ọjọ́ iwájú?
20 Bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ. Bí Ọlọ́run ṣe pe Alákòóso náà ní “Dáfídì ìránṣẹ́ mi,” ó fi hàn pé Jésù ló ń tọ́ka sí nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà, òun ni àtọmọdọ́mọ Dáfídì tó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin láti ṣàkóso. (Sm. 89:35, 36) Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi hàn pé òun jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà,” ní ti pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ “nítorí àwọn àgùntàn.” (Jòh. 10:14, 15) Àmọ́ ní báyìí, ó ti di Olùṣọ́ Àgùntàn tó ń bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀ látọ̀run. (Héb. 13:20) Lọ́dún 1914, Ọlọ́run fi Jésù jọba, ó sì faṣẹ́ lé e lọ́wọ́ pé kó máa bójú tó àwọn àgùntàn òun lórí ilẹ̀ ayé, kó sì máa bọ́ wọn. Kò pẹ́ sígbà yẹn, lọ́dún 1919, ni Ọba tí Jèhófà fi jẹ yìí yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pé kó máa bójú tó “àwọn ará ilé,” ìyẹn àwọn tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn tí wọ́n nírètí láti wà láàyè títí láé ní ọ̀run tàbí ní ayé. (Mát. 24:45-47) Ẹrú olóòótọ́ yìí wà lábẹ́ ìdarí Kristi, wọ́n sì ń fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ àwọn àgùntàn Ọlọ́run ní àbọ́yó. Oúnjẹ tẹ̀mí yìí ti jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀, kí àlàáfíà sì wà láàárín wọn nínú párádísè tẹ̀mí tó ń gbèrú sí i lójoojúmọ́.
21 Ìtumọ̀ wo ni ọ̀rọ̀ Ìsíkíẹ́lì nípa “májẹ̀mú àlàáfíà” àti òjò ìbùkún ní fún ọjọ́ iwájú? Nínú ayé tuntun tó ń bọ̀, àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé máa gbádùn àwọn ìbùkún “májẹ̀mú àlàáfíà” náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Nínú Párádísè tó ṣeé fojú rí tó máa kárí ayé, ogun, ìwà ọ̀daràn, ìyàn, àìsàn àtàwọn ẹran inú igbó ò ní han àwa èèyàn léèmọ̀ mọ́. (Àìsá. 11:6-9; 35:5, 6; 65:21-23) Ó dájú pé inú rẹ máa dùn sí ìrètí láti gbé títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, níbi tí ‘ààbò ti máa wà lórí àwọn àgùntàn Ọlọ́run, tí ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n’!—Ìsík. 34:28.
22. Báwo lọ̀rọ̀ àwọn àgùntàn ṣe máa ń rí lára Jésù? Kí làwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà lábẹ́ ìdarí Jésù lè ṣe láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀?
22 Ohun tá a rí kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà. Bíi ti Baba rẹ̀, ire àwọn àgùntàn jẹ Jésù lógún gan-an. Ọba àti Olùṣọ́ Àgùntàn yìí máa ń rí sí i pé àwọn àgùntàn Baba rẹ̀ jẹ oúnjẹ tẹ̀mí ní àjẹyó, wọ́n sì ń gbádùn àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ nínú párádísè tẹ̀mí. Abájọ tí ọkàn wa balẹ̀ pé abẹ́ àbójútó Alákòóso yìí la wà! Ó yẹ kí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà lábẹ́ ìdarí Jésù máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, kí wọ́n jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn àgùntàn jẹ wọ́n lógún. Ó sì yẹ kí àwọn alàgbà máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run “tinútinú,” kí wọ́n máa “fi ìtara ṣe é látọkàn wá,” kí wọ́n sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere tí àwọn àgùntàn á máa tẹ̀ lé. (1 Pét. 5:2, 3) Ó dájú pé àwọn alàgbà ò ní fẹ́ fọwọ́ líle mú èyíkéyìí lára àwọn àgùntàn Jèhófà! Ká má gbàgbé ohun tí Jèhófà sọ fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó rorò ní Ísírẹ́lì nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì pé: “Màá mú kí wọ́n jíhìn.” (Ìsík. 34:10) Jèhófà tó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn Gíga Jù Lọ ń fara balẹ̀ kíyè sí bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀, Ọmọ rẹ̀ náà sì ń ṣe bẹ́ẹ̀.
‘Dáfídì Ìránṣẹ́ Mi Yóò Jẹ́ Ìjòyè Wọn Títí Láé’
23. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe nípa bó ṣe máa mú kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wà níṣọ̀kan? Báwo ló sì ṣe mú ìlérí náà ṣẹ?
23 Jèhófà fẹ́ kí àwọn tó ń jọ́sìn òun máa sìn pa pọ̀ níṣọ̀kan. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan tó dá lórí bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa kó àwọn èèyàn òun jọ, ìyẹn àwọn tó ń ṣojú fún ìjọba ẹ̀yà méjì ti Júdà àti ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti Ísírẹ́lì, òun á sì mú kí wọ́n pa dà wà níṣọ̀kan bí “orílẹ̀-èdè kan,” bí ìgbà tóun mú kí “igi” méjì “di ọ̀kan” ní ọwọ́ òun. (Ìsík. 37:15-23) Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ, Ọlọ́run mú kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pa dà wà níṣọ̀kan ní Ilẹ̀ Ìlérí lọ́dún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. c Àmọ́ bíńtín báyìí ni ìṣọ̀kan yẹn máa jẹ́ tá a bá fi wé èyí tó máa gbilẹ̀ tó sì máa wà pẹ́ títí lọ́jọ́ iwájú. Lẹ́yìn ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa mú kí Ísírẹ́lì pa dà wà níṣọ̀kan, ó tún ní kí Ìsíkíẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa bí Alákòóso tó máa wà lọ́jọ́ iwájú ṣe máa mú kí àwọn tó ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ wà níṣọ̀kan kárí ayé, kí ìṣọ̀kan wọn sì wà títí láé.
24. Báwo ni Jèhófà ṣe ṣàpèjúwe Mèsáyà tó máa ṣàkóso? Báwo sì ni nǹkan ṣe máa rí tó bá ń ṣàkóso?
24 Ohun tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà. (Ka Ìsíkíẹ́lì 37:24-28.) Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà tún pe Mèsáyà Alákòóso yìí ní “Dáfídì ìránṣẹ́ mi,” “olùṣọ́ àgùntàn kan” àti “ìjòyè,” àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí Jèhófà tún pe Ẹni Tó Ṣèlérí yìí ní “ọba.” (Ìsík. 37:22) Báwo ni nǹkan ṣe máa rí tí Ọba yìí bá ń ṣàkóso? Àkóso rẹ̀ máa wà títí lọ. Bó ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ bí “ayérayé” àti “títí láé” fi hàn pé àwọn ìbùkún tí àkóso Ọba náà máa mú wá kò ní lópin. d Ìṣọ̀kan máa gbilẹ̀ lábẹ́ àkóso rẹ̀. Lábẹ́ àkóso “ọba kan” tó ń darí wọn, àwọn olóòótọ́ èèyàn á máa tẹ̀ lé “ìdájọ́” kan náà, wọ́n á sì ‘máa gbé pọ̀ lórí ilẹ̀’ náà. Àkóso rẹ̀ á mú kí àwọn tí Ọba náà ń darí túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run. Jèhófà máa bá àwọn tó wà lábẹ́ àkóso ọba náà dá “májẹ̀mú àlàáfíà.” Jèhófà máa jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọ́n á sì jẹ́ èèyàn rẹ̀. Ibi mímọ́ rẹ̀ sì máa wà “ní àárín wọn títí láé.”
25. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà Ọba ṣe ṣẹ?
25 Bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ. Lọ́dún 1919, àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró wà níṣọ̀kan lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan,” ìyẹn Jésù Kristi, Mèsáyà Ọba. Nígbà tó yá, “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” látinú “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èèyàn àti ahọ́n” wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run. (Ìfi. 7:9) Wọ́n jọ di “agbo kan” lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan.” (Jòh. 10:16) Bóyá wọ́n ń retí láti lọ sí ọ̀run tàbí láti wà lórí ilẹ̀ ayé, gbogbo wọn jọ ń tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ Jèhófà. Torí náà, wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ ará tó wà níṣọ̀kan kárí ayé tí wọ́n jọ ń gbé nínú Párádísè tẹ̀mí. Jèhófà fi àlàáfíà bù kún wọn, ibi mímọ́ rẹ̀ tó ṣàpẹẹrẹ ìjọsìn mímọ́ sì wà láàárín wọn. Jèhófà ni Ọlọ́run wọn, inú wọn sì ń dùn láti máa jọ́sìn rẹ̀ báyìí àti títí láé!
26. Kí lo lè ṣe láti mú kí ìṣọ̀kan túbọ̀ gbilẹ̀ nínú Párádísè tẹ̀mí?
26 Ohun tá a rí kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà. A láǹfààní láti wà níṣọ̀kan pẹ̀lú ẹgbẹ́ ará tó kárí ayé, tí wọ́n ń ṣe ìjọsìn mímọ́ sí Jèhófà. Àmọ́, ojúṣe kan wà tó bá àǹfààní yẹn rìn, ìyẹn ni pé a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá mú kí ìṣọ̀kan yẹn túbọ̀ gbilẹ̀. Torí náà, gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa ṣe ipa tiwa ká lè jọ máa wà níṣọ̀kan nínú ohun tá a gbà gbọ́ àti ìwà wa. (1 Kọ́r. 1:10) Kíyẹn lè ṣeé ṣe, à ń fìtara jẹ oúnjẹ tẹ̀mí kan náà, à ń tẹ̀ lé ìlànà Ìwé Mímọ́ kan náà nínú ìwà wa, a sì jọ ń kópa nínú iṣẹ́ kan náà tó ṣe pàtàkì, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́ ìfẹ́ ni olórí ohun tó so wá pọ̀. Bá a ṣe ń sapá láti rí i pé a ní ìfẹ́, tá a sì ń fìfẹ́ hàn lónírúurú ọ̀nà, títí kan bá a ṣe ń báni kẹ́dùn, tá à ń ṣàánú, tá a sì ń dárí jini, ṣe là ń mú kí ìṣọ̀kan àárín wa túbọ̀ gbilẹ̀. Bíbélì sọ pé, ‘Ìfẹ́ jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.’—Kól. 3:12-14; 1 Kọ́r. 13:4-7.
27. (a) Báwo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìsíkíẹ́lì nípa Mèsáyà ṣe rí lára rẹ? (b) Kí la máa jíròrò nínú àwọn orí tó kàn?
27 A dúpẹ́ a tọ́pẹ́ dá torí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìsíkíẹ́lì nípa Mèsáyà! Bá a ṣe ń ka àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà, tá a sì ń ronú lé wọn lórí, a kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ ká fọkàn tán Jésù Kristi, Ọba wa ọ̀wọ́n, òun ló lẹ́tọ̀ọ́ lọ́nà òfin láti ṣàkóso, láti fìfẹ́ bójú tó àwa àgùntàn rẹ̀, ó sì máa pa wá mọ́, ká lè jọ wà níṣọ̀kan títí láé. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní láti wà lábẹ́ àkóso Mèsáyà Ọba! Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà wà lára àwọn ọ̀rọ̀ tó dá lórí bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò bá a ṣe rí i nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì. Jèhófà ń lo Jésù láti kó àwọn èèyàn Rẹ̀ jọ, ó sì ń mú kí ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò láàárín wọn. (Ìsík. 20:41) Nínú àwọn orí tó kàn nínú ìwé yìí, a máa sọ nípa kókó ọ̀rọ̀ tó ń múnú ẹni dùn yẹn, èyí tó dá lórí bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò, a sì máa rí bí ìwé Ìsíkíẹ́lì ṣe tànmọ́lẹ̀ sí i.
a Ọdún 617 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ́kọ́ kó àwọn Júù kan lọ sígbèkùn ní Bábílónì. Torí náà, ọdún 612 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ọdún kẹfà bẹ̀rẹ̀.
b Àkọsílẹ̀ nípa bí Jésù ṣe wá láti ìlà ìdílé Dáfídì wà nínú Àwọn Ìwé Ìhìn Rere tí Ọlọ́run mí sí.—Mát. 1:1-16; Lúùkù 3:23-31.
d Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ nípa àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí “títí láé” àti “ayérayé” pé: “Ọ̀rọ̀ yìí ń sọ nípa bí nǹkan ṣe máa pẹ́ tó, ó ń tọ́ka sí ohun tó máa wà títí lọ, tó máa lálòpẹ́, tí kò ní bà jẹ́, tí kò ṣeé dá pa dà, tí kò sì ní yí pa dà.”