ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 16B
Ìgbà Wo Ni Ìkẹ́dùn, Ìkérora, Ìsàmì àti Fífọ́ Nǹkan Máa Ṣẹlẹ̀, Báwo Ló sì Ṣe Máa Ṣẹlẹ̀?
Ìran tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì orí 9 ń ṣẹ lóde òní. Òye tá a bá ní nípa bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe máa wáyé lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ bí òpin ètò àwọn nǹkan yìí ṣe ń sún mọ́lé
‘Wọ́n ń kẹ́dùn, wọ́n sì ń kérora’
ÌGBÀ WO: Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ṣáájú ìpọ́njú ńlá
BÁWO LÓ ṢE MÁA ṢẸLẸ̀: Àwọn èèyàn tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn ń fi hàn nípa ọ̀rọ̀ àti ìwà wọn pé àwọn ò fara mọ́ ìwàkiwà tó kúnnú ayé yìí. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tẹ́tí gbọ́ ìwàásù, wọ́n ṣe ohun tó yẹ, wọ́n ń fi àwọn ànímọ́ Kristi ṣèwà hù, wọ́n ṣèrìbọmi láti fi hàn pé wọ́n ti yara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn arákùnrin Kristi
‘Ìsàmì’
ÌGBÀ WO: Nígbà ìpọ́njú ńlá
BÁWO LÓ ṢE MÁA ṢẸLẸ̀: Ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé ṣàpẹẹrẹ Jésù Kristi nígbà tó bá dé gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè. Ó máa dá ogunlọ́gọ̀ èèyàn láre, lédè míì, ó máa sàmì sí wọn pé wọ́n jẹ́ àgùntàn, ìyẹn fi hàn pé wọ́n á la Amágẹ́dọ́nì já
‘Fífọ́ nǹkan’
ÌGBÀ WO: Ní Amágẹ́dọ́nì
BÁWO LÓ ṢE MÁA ṢẸLẸ̀: Jésù Kristi àtàwọn ọmọ ogun ọ̀run, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n ń jọba pẹ̀lú Jésù, máa pa ayé búburú yìí run pátápátá, wọ́n á sì gba àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́ là sínú ayé tuntun