ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 9E
Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìgbèkùn àti Ìmúbọ̀sípò
Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ sára àwọn Júù tí wọ́n kó nígbèkùn lọ sí Bábílónì àtijọ́ tún ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò nígbà tí Bábílónì Ńlá mú ìjọ Kristẹni nígbèkùn. Àwọn àpẹẹrẹ kan rèé.
1. ÌKÌLỌ̀ |
2. ÌGBÈKÙN |
3. ÌMÚBỌ̀SÍPÒ |
|
---|---|---|---|
ÌMÚṢẸ ÀKỌ́KỌ́ |
Ṣáájú 607 Ṣ.S.K.—Àìsáyà, Jeremáyà àti Ìsíkíẹ́lì kìlọ̀ fáwọn èèyàn Jèhófà; síbẹ̀ ìpẹ̀yìndà ń gbilẹ̀ sí i |
607 Ṣ.S.K.—Jerúsálẹ́mù pa run; wọ́n kó àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì |
537 Ṣ.S.K. síwájú—Àwọn àṣẹ́kù tó jẹ́ olóòótọ́ pa dà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n tún tẹ́ńpìlì kọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìjọsìn mímọ́ |
ÌMÚṢẸ TÓ GBÒÒRÒ |
Ọgọ́rùn-ún Ọdún Kìíní S.K.—Jésù, Pọ́ọ̀lù àti Jòhánù kìlọ̀ fún ìjọ, síbẹ̀ ìpẹ̀yìndà ń gbilẹ̀ sí i |
Láti Ọgọ́rùn-ún Ọdún Kejì S.K.—Bábílónì Ńlá mú àwọn Kristẹni tòótọ́ nígbèkùn |
1919 S.K. síwájú—Lábẹ́ àkóso Jésù, àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró kúrò nínú ìgbèkùn tẹ̀mí, ìjọsìn mímọ́ sì pa dà bọ̀ sípò |