APA 1
Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Wa Jẹ Ọlọ́run Lógún?
ÌṢÒRO pọ̀ ní ayé òde òní. Ogun, onírúurú ìjábá, àìsàn, àìrí owó gbọ́ bùkátà, ìwà ìbàjẹ́ àtàwọn nǹkan láabi mìíràn ń han àìmọye èèyàn léèmọ̀. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ pàápàá ní àwọn nǹkan tí o ń ṣe àníyàn lé lórí. Ta ló máa ràn wá lọ́wọ́? Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ wa tiẹ̀ jẹ ẹnì kankan lógún?
Ó dájú pé ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún gan-an. Ó sọ nínú Ìwé Mímọ́ rẹ̀ pé: “Aya ha lè gbàgbé ọmọ ẹnu ọmú rẹ̀ tí kì yóò fi ṣe ojú àánú sí ọmọ ikùn rẹ̀? Àní àwọn obìnrin wọ̀nyí lè gbàgbé, síbẹ̀, èmi kì yóò gbàgbé [rẹ].” a
Ǹjẹ́ o ò rí i pé ọ̀rọ̀ yìí fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an? Àní, ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa pọ̀ gan-an ju ìfẹ́ tó ń mú kí abiyamọ máa ṣìkẹ́ ọmọ ọwọ́ rẹ̀ lójú méjèèjì, bẹ́ẹ̀ sì rèé, abiyamọ kì í fi ọ̀rọ̀ ọmọ rẹ̀ ṣeré. Ọlọ́run kò ní pa wá tì láé! Kódà, ó tiẹ̀ ti ṣèrànlọ́wọ́ kan fún wa lọ́nà ìyanu. Ìrànlọ́wọ́ wo nìyẹn? Ó ti jẹ́ ká mọ ohun tí yóò máa fún wa ní ayọ̀, ìyẹn sì ni ìgbàgbọ́ òdodo.
Tó o bá ní ojúlówó ìgbàgbọ́, ìyẹn á máa fún ọ ní ayọ̀. Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ kó o lè yàgò fún ọ̀pọ̀ ìṣòro, yóò sì jẹ́ kó o lè borí àwọn ìṣòro tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Ó tún máa jẹ́ kó o sún mọ́ Ọlọ́run, ọkàn rẹ yóò sì máa balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Ìgbàgbọ́ òdodo sì máa gbé ọ dé ọgbà ìdẹ̀ra, ìyẹn Párádísè (Alujanna), níbi tó o ti máa ní ìyè ayérayé!
Àmọ́, kí ni ìgbàgbọ́ òdodo? Báwo lo ṣe lè ní irú ìgbàgbọ́ yìí?
a Wo Aísáyà 49:15 nínú Ìwé Mímọ́.