Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
Ìwé pẹlẹbẹ yìí ṣàlàyé bí àwọn èèyàn láti onírúurú ilẹ̀ ṣe lè láyọ̀ tí wọ́n bá lè mú kí ìgbàgbọ́ wọn jinlẹ̀.
Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ti rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè tó ti ń da ọkàn wọ́n láàmú.
APÁ 1
Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Wa Jẹ Ọlọ́run Lógún?
Ìṣòro pọ̀ láyé lónìí. Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ní àwọn nǹkan tí ò ń ṣe àníyàn lé lórí. Ta ló lè ràn wá lọ́wọ́? Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ wa tiẹ̀ jẹ ẹnì kankan lógún?
APÁ 2
Kí Ni Ìgbàgbọ́ Òdodo?
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé Ọlọ́run wà, àmọ́ tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ń hùwà láabi. Èyí fí hàn pé kéèyàn ní ìgbàgbọ́ òdodo ju pé kó ṣáà ti gbà pé Ọlọ́run wà.
APÁ 3
Ìtọ́sọ́nà Rere Tó Ń Mú Kí Ayé Ẹni Dára
Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n wà nínú Ìwé Mímọ́ tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro àárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ, kó o kápá ìbínú, kó o jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró, kó o borí ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, kó o sì jáwọ́ nínú ìwà ipá àtàwọn ìṣòro míì.
APÁ 4
Ta Ni Ọlọ́run?
Oríṣiríṣi òrìṣà ni àwọn èèyàn ń jọ́sìn, àmọ́ Ìwé Mímọ kọ́ wa pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà.
APÁ 5
Mọyì Àwọn Ìwà Dáadáa tí Ọlọ́run Ní
Ìwé Mímọ́ sọ púpọ̀ nínú ìwà tó dáa gan-an tí Ọlọ́run ní, èyí tó jẹ́ ká lè mọ Ọlọ́run.
APÁ 6
Torí Kí Ni Ọlọ́run Ṣe Dá Ilẹ̀ Ayé??
Ìwé Mímọ́ sọ pé Ọlọ́run “kò wulẹ̀ dá [ayé] lásán, [ṣe ni] ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” Àmọ́ ṣe bí ayé ṣe rí lónìí ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí lóòótọ́?
APÁ 9
Ẹ̀kọ́ tí A Lè Rí Kọ́ Lára Mèsáyà Tó Jẹ́ Aṣáájú
Ọlọ́run mọ irú aṣáájú tó máa ṣe wá láǹfààní gan-an, Aṣáájú tí kò lẹ́gbẹ́ ló sì fún wa.
APÁ 11
Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́ Òdodo Lóde Òní
Jésù sọ pé àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo máa ń so “èso àtàtà”, tàbí ìwà rere. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìwà náà?