Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 9

“Ẹ Máa Sá fún Àgbèrè”

“Ẹ Máa Sá fún Àgbèrè”

“Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.”—KÓLÓSÈ 3:5.

1, 2. Báwo ni Báláámù ṣe pète láti dẹkùn mú àwọn èèyàn Jèhófà?

APẸJA kan lọ síbi tó fẹ́ràn láti máa dẹdò. Ó ní irú ẹja pàtó kan tó fẹ́ láti fi ìwọ̀ gbé. Ó fi ìdẹ tí ẹja náà kúndùn sẹ́nu ìwọ̀, ó sì ju ìwọ̀ náà sódò. Kò pẹ́ tí ìwọ̀ náà fi gbé ẹja, ló bá yáa fà á sókè. Pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ lẹ́nu ẹ̀, ó mí kanlẹ̀ pé irú ìdẹ tó yẹ gan-an lòun lò.

2 Bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn lọ́dún 1473 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Báláámù ń ronú nípa ohun tó máa fi dẹkùn mú àwọn èèyàn kan. Àmọ́, àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n pàgọ́ sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lẹ́nu bodè Ilẹ̀ Ìlérí, ló ń fojú sùn. Báláámù sọ pé wòlíì Jèhófà lòun, àmọ́ oníwọra èèyàn tí wọ́n gbéṣẹ́ fún pé kó wá fàwọn ọmọ Ísírẹ́lì gégùn-ún ni. Torí náà, Jèhófà dá sí ọ̀ràn yìí, Báláámù ò sì lè ṣe ju pé kó súre fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. Níwọ̀n bí ojú Báláámù ò ti kúrò nínú ohun tó máa rí gbà, ó ronú pé òun ì bá kúkú tan àwọn èèyàn náà tí wọ́n á fi dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ á sì wá fi wọ́n gégùn-ún. Ohun tó wà lọ́kàn Báláámù nìyẹn tó fi lo àwọn ọmọge Móábù tí wọ́n jẹ́ àrímáleèlọ láti dẹkùn mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.—Númérì 22:1-7; 31:15, 16; Ìṣípayá 2:14.

3. Kí lọgbọ́n tí Báláámù dá yọrí sí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

3 Ǹjẹ́ ọgbọ́n tó dá yìí ṣiṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣiṣẹ́ dé ìwọ̀n àyè kan. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó sínú ìdẹkùn yìí nípa níní “ìbálòpọ̀ oníṣekúṣe pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Móábù.” Wọ́n tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn òrìṣà ilẹ̀ Móábù, tó fi mọ́ Báálì Péórù, òrìṣà ẹlẹ́gbin tí wọ́n sọ pó jẹ́ òrìṣà ìbímọlémọ, tàbí ti ìbálòpọ̀. Nítorí ìyẹn, ẹgbàá méjìlá [24,000] ló ṣègbé lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọ́n tó dé Ilẹ̀ Ìlérí. Àdánù ńláǹlà mà lèyí o!—Númérì 25:1-9.

4. Kí nìdí tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ṣàgbèrè?

4 Kí ló fa àdánù yìí gan-an? Ìdí ni pé lílọ tí ọ̀pọ̀ lára wọn lọ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà ti mú kí ọkàn wọn dìdàkudà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Ọlọ́run yìí ló dá wọn nídè kúrò ní Íjíbítì, òun ló bọ́ wọn nígbà tí wọ́n wà ní aginjù, òun ló sì pa wọ́n mọ́ títí tí wọ́n fi dé bèbè Ilẹ̀ Ìlérí. (Hébérù 3:12) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún, ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe fi àgbèrè ṣe ìwà hù, bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe àgbèrè, kìkì láti ṣubú, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún nínú wọn ní ọjọ́ kan ṣoṣo.” *1 Kọ́ríńtì 10:8.

5, 6. Kí nìdí tóhun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù fi ṣe pàtàkì fún wa lónìí?

5 Lóde òní, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ làwọn èèyàn Ọlọ́run lè rí kọ́ nínú ìwé Númérì, torí pé àwọn náà ti wà ní bèbè ilẹ̀ ìlérí tó ju ilẹ̀ ìlérí lọ báyìí. (1 Kọ́ríńtì 10:11) Bí àpẹẹrẹ, bí ìbálòpọ̀ ṣe jàrábà àwọn ará Móábù ìgbàanì, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jàrábà aráyé lákòókò tá à ń gbé yìí, àmọ́ tòde òní tún wá légbá kan. Abájọ tó fi jẹ́ pé lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristẹni ló ń kó sí pàkúté ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè, ìyẹn pàkúté kan náà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó sí. (2 Kọ́ríńtì 2:11) A sì ráwọn kan tí wọ́n fìwà jọ Símírì, ẹni tí àyà kò débi tó fi gbé obìnrin ará Mídíánì kan wá sí ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kó lè lọ bá a sùn nínú àgọ́ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn wọ̀nyí ń dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí, wọ́n máa ń kó èèràn ìṣekúṣe tó ti jàrábà wọn ran àwọn ará nínú ìjọ.—Númérì 25:6, 14; Júdà 4.

6 Ṣé ìwọ náà ń wo ara rẹ bíi pé ó wà ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù òde òní? Ṣé o sì ń wo ayé tuntun Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí èrè tí kò ní í pẹ́ tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run nípa ṣíṣègbọràn sí àṣẹ náà pé: “Ẹ máa sá fún àgbèrè.”—1 Kọ́ríńtì 6:18.

Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù tó tẹ́ rẹrẹ

KÍ NI ÀGBÈRÈ?

7, 8. Kí ni “àgbèrè,” báwo sì làwọn tó ń ṣe é ṣe ń kórè ohun tí wọ́n gbìn?

7 Bó ṣe wà nínú Bíbélì, “àgbèrè” (ìyẹn por·neiʹa lédè Gíríìkì) jẹ́ ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kò ṣègbéyàwó lọ́nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Lára àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ́ àgbèrè ni panṣágà, ṣíṣe aṣẹ́wó, àti ìbálòpọ̀ láàárín ẹni méjì tí kò bára wọn ṣègbéyàwó, títí kan kéèyàn máa fi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíràn, kéèyàn máa ti ihò ìdí báni lò pọ̀, àti fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíràn tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni. Ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin méjì ló bára wọn lò pọ̀ láwọn ọ̀nà yìí, tàbí kó jẹ́ pé ẹranko ni wọ́n bá lò pọ̀, àgbèrè náà ṣì ni. *

8 Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí ọ̀ràn yìí ṣe kedere: Ìjọ Kristẹni ò ní gba àwọn tó bá ń ṣe àgbèrè láyè, wọn ò sì ní jogún ìyè ayérayé. (1 Kọ́ríńtì 6:9; Ìṣípayá 22:15) Ó ṣe tán, kékeré kọ́ ni ìpalára táwọn alágbèrè ń ṣe fúnra wọn báyìí, torí pé wọn kì í ṣeé gbára lé, wọ́n máa ń dẹni ẹ̀tẹ́, àlàáfíà kì í sí nínú ìgbéyàwó wọn, ọkàn wọn máa ń dá wọn lẹ́bi, wọn máa ń gboyún, wọ́n máa ń kárùn, àní wọ́n máa ń kú pàápàá. (Ka Gálátíà 6:7, 8) Àbí èwo ni kéèyàn rí oko lóko ikún, kó wá máa gbin ẹ̀pà sí i? Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í ronú jinlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ dáwọ́ lé ohun tó sábà máa ń yọrí sí ṣíṣe àgbèrè, ìyẹn ni ṣíṣe àwọn ohun tó máa ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe.

IBI ṢÍṢE ÀWỌN OHUN TÓ Ń MỌ́KÀN FÀ SÍ ÌṢEKÚṢE NI ÀGBÈRÈ TI Ń BẸ̀RẸ̀

9. Ṣóòótọ́ ni pé báwọn kan ṣe máa ń sọ, àwọn ohun tó ń mọ́kàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe kò léwu? Ṣàlàyé.

9 Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ó fẹ̀rẹ̀ẹ́ máà sí ibi téèyàn ò ti lè rí àwọn ohun tó ń mọ́kàn fà sí ìṣekúṣe, ó wà níbi tí wọ́n ń pàtẹ ìwé ìròyìn sí, èèyàn lè fetí gbọ́ ọ, tàbí kéèyàn wò ó lórí tẹlifíṣọ̀n; torí Íńtánẹ́ẹ̀tì tiẹ̀ wá kọyọyọ. * Ṣóòótọ́ ni pé kò léwu báwọn kan ṣe máa ń sọ? Ó léwu mọ̀nàkàì! Àwọn tó ń ṣe ohun tó ń mọ́kàn èèyàn fà sí ìṣékuṣé lè sọ fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni dàṣà kí wọ́n máa ní “ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo tí ń dójú tini,” èyí tó lè yọrí sí kíkúndùn ìbálòpọ̀, níní èrò òdì nípa ìbálòpọ̀, àìfohùnṣọ̀kan láàárín tọkọtaya, àti ìkọ̀sílẹ̀ pàápàá. * (Róòmù 1:24-27; Éfésù 4:19) Olùṣèwádìí kan fi kíkùndún ìbálòpọ̀ wé àrùn jẹjẹrẹ. Ó sọ pé: “Ńṣe ni àrùn náà máa ń pọ̀ sí i nínú ara, tó sì máa ń gbèèràn. Kì í lọ bọ̀rọ̀, ó sì máa ń ṣòro wò sàn pátápátá.”

Ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn máa lo Íńtánẹ́ẹ̀tì níbi táwọn aráalé yòókù ti lè rí i

10. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi ìlànà tó wà nínú Jákọ́bù 1:14, 15 sílò? (Tún wo “ Ohun Tó Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Jáwọ́ Nínú Ìṣekúṣe.”)

10 Gbé àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jákọ́bù 1:14, 15, yẹ̀ wò, èyí tó kà pé: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀; ẹ̀wẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti ṣàṣeparí rẹ̀, a mú ikú wá.” Nítorí náà, bí èrò búburú bá wá sí ẹ lọ́kàn, kíá ni kó o yáa gbé e kúrò lọ́kàn! Bí àpẹẹrẹ, bó o bá ṣèèṣì já lu àwòrán ìbálòpọ̀ tàbí ti oníhòòhò, yára gbé ojú ẹ kúrò níbẹ̀, tàbí kó o pa kọ̀ǹpútà ẹ, tàbí kó o yí tẹlifíṣọ̀n rẹ sí ìkànnì míì. Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe, kó o má bàa gba èròkérò láyè, bó bá wọ̀ ẹ́ lọ́kàn, ó lè dohun tápá ò ká mọ́, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í darí ìgbésí ayé rẹ!—Ka Mátíù 5:29, 30.

11. Bí èrò búburú bá ń gbà wá lọ́kàn, báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà?

11 Abájọ nígbà náà tí Ẹni tó mọ̀ wá ju bá a ti mọ ara wa lọ fi gbà wá níyànjú pé: “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.” (Kólósè 3:5) Ká sòótọ́, èyí kì í ṣe ohun tó rọrùn láti ṣe. Àmọ́, rántí pé a ní Baba tá a lè ké pè, baba wa ọ̀run tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti onísùúrù. (Sáàmù 68:19) Torí náà, tètè máa ké pè é bí èrò búburú bá wá sí ẹ lọ́kàn. Gbàdúrà sí i pé kó fún ẹ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” kó o sì darí ọkàn ẹ síbòmíràn.—2 Kọ́ríńtì 4:7; 1 Kọ́ríńtì 9:27; wo àpótí náà, “ Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Àṣà Búburú?

12. Kí ni “ọkàn-àyà” wa, kí sì nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ pa á mọ́?

12 Ọkùnrin ọlọgbọ́n náà, Sólómọ́nì, kọ̀wé pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.” (Òwe 4:23) “Ọkàn-àyà” wa ni ohun tá a jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún, irú ẹni tí Ọlọ́run gbà pé àwa gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan jẹ́. Àti pé, ojú tí Ọlọ́run bá fi wo “ọkàn-àyà” wa ló máa pinnu bóyá a máa jogún ìyè àìnípẹ̀kun tàbí a ò ní jogún ẹ̀, kì í wulẹ̀ ṣe ojú táwọn èèyàn fi ń wò wá. Kò jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀rọ̀ náà tún wá níbi tó le sí ṣáá o. Nítorí kí èrò òdì má bàa mú kí Jóòbù tẹjú mọ́ wúńdíá, ó bá ojú rẹ̀ dá májẹ̀mú tàbí ṣe àdéhùn. (Jóòbù 31:1) Àpẹẹrẹ rere mà lèyí jẹ́ fún wa o! Onísáàmù kan tí èrò rẹ̀ jọ ti Jóòbù gbàdúrà pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.”—Sáàmù 119:37.

DÍNÀ YAN OHUN TÍ KÒ MỌ́GBỌ́N DÁNÍ

13. Ta ni Dínà, kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́ ló yàn?

13 Bá a ṣe rí i nínú Orí 3, àwọn ọ̀rẹ́ wa lè nípa lórí wa sí rere tàbí búburú. (Òwe 13:20; ka 1 Kọ́ríńtì 15:33) Gbé àpẹẹrẹ ti Dínà tó jẹ́ ọmọbìnrin baba ńlá náà Jékọ́bù, yẹ̀ wò. (Jẹ́nẹ́sísì 34:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé rere ni wọ́n ti tọ́ Dínà dàgbà, ó hùwà tí kò mọ́gbọ́n dání nípa yíyan àwọn ọmọbìnrin Kénáánì lọ́rẹ̀ẹ́. Bí àwọn ará Móábù làwọn ará Kénáánì náà ṣe rí, ìwà ìbàjẹ́ wọn gogò nínú ìlú náà. (Léfítíkù 18:6-25) Lójú àwọn ọkùnrin Kénáánì, tó fi mọ́ Ṣékémù, tó “ní ọlá jù lọ” nínú gbogbo ilé baba rẹ, Dínà ò ṣilé wọ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 34:18, 19.

14. Ìyọnu wo làwọn ọ̀rẹ́ tí Dínà yàn dá sílẹ̀?

14 Ó ṣeé ṣe kí Dínà máà ní ìbálòpọ̀ lọ́kàn nígbà tó rí Ṣékémù. Ńṣe ni Ṣékémù náà sì ṣe ohun tí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ará Kénáánì máa ṣe bí ara wọn bá béèrè fún ìbálòpọ̀. Ẹ̀pa ò bóró mọ́ fún Dínà torí pé Ṣékémù “mú un” ó sì bá a “sùn.” Ó dà bíi pé lẹ́yìn náà ni Ṣékémù “kó sínú ìfẹ́ fún” Dínà, àmọ́ ìyẹn ò yí ohun tó ti ṣe fún un pa dà. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 34:1-4) Nígbà tí gbogbo ẹ̀ sì pàpà já síbi tó máa já sí, Dínà nìkan kọ́ ló fara gbá a. Àwọn tó yàn láti bá ṣọ̀rẹ́ ló ṣokùnfà ohun tó kó ẹ̀gàn àti ìtìjú bá àwọn ara ilé rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 34:7, 25-31; Gálátíà 6:7, 8.

15, 16. Báwo la ṣe lè ní ọgbọ́n tòótọ́? (Tún wo  Àwọn Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Tó Yẹ Kó O Rónú Lé Lórí.)

15 Bí Dínà bá tiẹ̀ rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kankan kọ́ lára ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó dájú pé lẹ́yìn tọ́ràn ti bẹ́yìn yọ ló tó rí ẹ̀kọ́ náà kọ́. Kò dìgbà tọ́ràn bá bẹ́yìn yọ káwọn tó fẹ́ràn Jèhófà tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i tó kẹ́kọ̀ọ́ tó bá yẹ. Torí pé wọ́n ń tẹ́tí sí Ọlọ́run, wọ́n ti yàn láti máa “bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn.” (Òwe 13:20a) Wọ́n wá tipa bẹ́ẹ̀ lóye “gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere pátá,” ìyẹn sì ń pa wọ́n mọ́ nínú ìṣòro àti ìrora tí wọn ì bá ti mú wá sórí ara wọn.—Òwe 2:6-9; Sáàmù 1:1-3.

16 Gbogbo àwọn tó bá ń wá ọgbọ́n Ọlọ́run, tí wọn ò sì yéé sapá láti rí i nípa gbígbàdúrà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìwé tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ náà ń mú jáde déédéé, ló dájú pé wọ́n máa rí i. (Mátíù 24:45; Jákọ́bù 1:5) Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ táá mú ká máa fínnú fíndọ̀ ṣègbọràn sáwọn ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ tún ṣe pàtàkì. (2 Àwọn Ọba 22:18, 19) Bí àpẹẹrẹ, Kristẹni kan lè gbà ní tòótọ́ pé ọkàn òun kún fún àdàkàdekè ó sì ń gbékú tà. (Jeremáyà 17:9) Àmọ́, bọ́ràn bá délẹ̀, ṣó níwà ìrẹ̀lẹ̀ tó láti gba ìrànlọ́wọ́ àti ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n bá fún un lórí ohun kan tó ṣe?

17. Ṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣeé ṣe kó wáyé láàárín bàbá kan àtọmọ ẹ̀, kó o sì ṣàlàyé bí bàbá náà ṣe lè fòye ronú pẹ̀lú ọmọbìnrin rẹ̀.

17 Jẹ́ ká ro ọ̀ràn yìí wò ná. Bàbá kan ní kọ́mọ rẹ̀ obìnrin má ṣe bá ọ̀dọ́kùnrin kan jáde àyàfi bí ẹnì kan bá máa ṣìkẹta wọn. Ọ̀dọ́mọbìnrin náà sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Dádì, ṣẹ́ ò fọkàn tán mi ni? A ò ní ṣe ohun máà-jẹ́-á-gbọ́ kankan!” Irú ọ̀dọ́mọbìnrin bẹ́ẹ̀ lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lóòótọ́, kó má sì ní in lọ́kàn láti hùwà tí ò dáa, síbẹ̀, ṣé a lè sọ pé ó “ń fi ọgbọ́n [Ọlọ́run] rìn”? Ṣé ó ń “sá fún àgbèrè”? Àbí ó ń hùwà òmùgọ̀ nípa ‘gbígbẹ́kẹ̀lé ọkàn-àyà ara rẹ̀’? (Òwe 28:26) Bóyá o lè ronú lórí àwọn ìlànà míì tó máa ran irú bàbá bẹ́ẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ́ nípa ọ̀ràn yìí.—Wo Òwe 22:3; Mátíù 6:13; 26:41.

JÓSẸ́FÙ SÁ FÚN ÀGBÈRÈ

18, 19. Ìdẹwò wo ni Jósẹ́fù dojú kọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ọ̀nà wo ló sì gbà kojú ẹ̀?

18 Ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà kan tó fẹ́ràn Ọlọ́run tó sì sá fún àgbèrè ni Jósẹ́fù, tó jẹ́ ọbàkan Dínà. (Jẹ́nẹ́sísì 30:20-24) Nígbà tí Jósẹ́fù wà lọ́mọdé, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dínà ṣojú ẹ̀, ó sì mọ ibi tí ìwà òmùgọ̀ Dínà yọrí sí. Kò sí iyè méjì nígbà náà pé àwọn ohun tí Jósẹ́fù rántí yìí àti bó ṣe fẹ́ láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run ló dáàbò bò ó lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ nílùú Íjíbítì ń rọ̀ ọ́ ní “ọjọ́ dé ọjọ́” pé kó bá òun sùn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹrú ni Jósẹ́fù, kò sí bó ṣe lè kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ kó sì bá tiẹ̀ lọ! Ọgbọ́n àti ìgboyà ló gbọ́dọ̀ fi yanjú ọ̀ràn náà. Ọ̀nà tó sì gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó ń kọ̀ fún ìyàwó Pọ́tífárì ní gbogbo ìgbà tó bá ti fi ìbálòpọ̀ lọ̀ ọ́, débí pé nígbà tó yá, ńṣe ló kúkú sá jáde fún obìnrin náà.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 39:7-12.

19 Rò ó wò ná: Ká sọ pé Jósẹ́fù ti ń fọkàn ronú lórí bó ṣe máa bá obìnrin náà lò pọ̀ tàbí kó ti máa ronú ṣáá nípa ìbálòpọ̀, ǹjẹ́ ì bá ti ṣeé ṣe fún un láti pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́? Bóyá ni. Dípò tí Jósẹ́fù ì bá fi máa ro èrò tó lè mú un dẹ́ṣẹ̀ lọ́kàn, ó ka àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà sí ohun tó ṣeyebíye bá a ti lè rí i nínú ọ̀rọ̀ tóun fúnra rẹ̀ sọ fún ìyàwó Pọ́tífárì. Ó máa ń sọ pé, “ọ̀gá mi . . . kò sì tíì fawọ́ ohunkóhun sẹ́yìn fún mi, bí kò ṣe ìwọ, nítorí pé aya rẹ̀ ni ọ́. Nítorí náà, báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?”—Jẹ́nẹ́sísì 39:8, 9.

20. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà dá sí ọ̀ràn Jósẹ́fù?

20 Wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó bó ṣe ń wo Jósẹ́fù, ọ̀dọ́ tó ń gbé níbi tó jìnnà sáwọn èèyàn ẹ̀, síbẹ̀ tí kò dẹ́kun láti máa ṣe ohun tó tọ́ láti ọjọ́ dé ọjọ́. (Òwe 27:11) Nígbà tó ṣe, Jèhófà dá sí ọ̀ràn Jósẹ́fù, èyí tó mú kí wọ́n dá a sílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n, tó sì tún wá di igbá kejì Fáráò àti alábòójútó oúnjẹ nílẹ̀ Íjíbítì! (Jẹ́nẹ́sísì 41:39-49) Òótọ́ gbáà lọ̀rọ̀ inú Sáàmù 97:10 tó sọ pé: “Ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ kórìíra ohun búburú. Ó ń ṣọ́ ọkàn àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀; ó ń dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú”!

21. Báwo ni ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan nílẹ̀ Áfíríkà ṣe fìgboyà ṣe ohun tó tọ́?

21 Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló ń fi hàn pé àwọn “kórìíra ohun búburú,” àwọn sì “nífẹ̀ẹ́ ohun rere.” (Ámósì 5:15) Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan nílẹ̀ Áfíríkà rántí pé ọmọ iléèwé òun kan tó jẹ́ obìnrin sọ fóun pé òun á jẹ́ kó bá òun lò pọ̀ bó bá ran òun lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ń ṣe ìdánwò lórí ìṣirò. Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí náà sọ pé: “Kíá ni mo kọ ohun tó fi lọ̀ mí. Gbígbà tí mi ò gbàgbàkugbà láyè yìí ti sọ mi dẹni àpọ́nlé, àwọn èèyàn ń fọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí, èyí sì ṣeyebíye fún mi ju wúrà àti fàdákà lọ.” Òótọ́ ni pé èèyàn lè jẹ “ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀,” àmọ́ ìgbádùn ráńpẹ́ bẹ́ẹ̀ sábà máa ń mú ìrora wá. (Hébérù 11:25) Àti pé, wọn kò já mọ́ nǹkan kan báa bá fi wọ́n wé ayọ̀ ayérayé tó ń dúró dé ẹni tó bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà.—Òwe 10:22.

JẸ́ KÍ ỌLỌ́RUN ÀÁNÚ RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́

22, 23. (a) Bí Kristẹni kan bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, kí nìdí tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò fi kọjá àtúnṣe? (b) Ìrànlọ́wọ́ wo ni oníwà àìtọ́ lè rí gbà?

22 Nítorí pé a jẹ́ aláìpé, gbogbo wa là ń tiraka láti má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ ti ẹran ara dí wa lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run. (Róòmù 7:21-25) Jèhófà mọ̀ pé bọ́rọ̀ wa ṣe rí nìyí, “ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:14) Àmọ́ nígbà míì, Kristẹni kan lè dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì. Ṣé ọ̀ràn rẹ̀ ti wá kọjá àtúnṣe nìyẹn? Rárá o! Ohun tó kàn wà níbẹ̀ ni pé oníwà àìtọ́ náà lè kórè àbájáde kíkorò, bíi ti Dáfídì Ọba. Síbẹ̀, Ọlọ́run máa ń “ṣe tán [nígbà gbogbo] láti dárí” ji àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn tí wọ́n bá “jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀” wọn “ní gbangba.”—Sáàmù 86:5; Jákọ́bù 5:16; ka Òwe 28:13.

23 Ní àfikún, ìfẹ́ ti mú kí Ọlọ́run fi ìjọ Kristẹni jíǹkí wa, ó sì tún fún wa ní “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn,” àwọn olùṣọ́ àgùntàn tẹ̀mí tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, tí wọ́n kúnjú ìwọ̀n tí wọ́n sì tún múra tán láti ràn wá lọ́wọ́. (Éfésù 4:8, 12; Jákọ́bù 5:14, 15) Àfojúsùn wọn ni pé kí wọ́n lè ran oníwà àìtọ́ lọ́wọ́ kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run lè padà bọ̀ sípò, àti pé, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n náà ṣe sọ, kó lè “jèrè ọkàn-àyà” kó má bàa tún ẹ̀ṣẹ̀ náà dá.—Òwe 15:32.

“JÈRÈ ỌKÀN-ÀYÀ”

24, 25. (a) Báwo ni ọ̀dọ́mọkùnrin tá a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Òwe 7:6-23 ṣe fi hàn pé òun jẹ́ ẹni “tí ọkàn-àyà kù fún”? (b) Báwo la ṣe lè “jèrè ọkàn-àyà”?

24 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn “tí ọkàn-àyà kù fún” àti àwọn tí wọ́n “ń jèrè ọkàn-àyà.” (Òwe 7:7) Ẹni “tí ọkàn-àyà kù fún” torí pé kò lóye tó jinlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí kò sì tíì pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, lè má mọ béèyàn ṣe ń fòye àti làákàyè ṣe nǹkan. Bíi ti ọ̀dọ́kùnrin tá a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Òwe 7:6-23, ó lè rọrùn fún un láti máa dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì. Àmọ́, ẹni tó bá “ń jèrè ọkàn-àyà” máa ń yẹ irú ẹni tóun jẹ́ nínú wò nípa gbígbàdúrà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Níbi tí agbára rẹ̀ bá sì gbé e dé gẹ́gẹ́ bí aláìpé, á máa mú èrò rẹ̀, ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ìmọ̀lára rẹ̀ àti àfojúsùn rẹ̀ bá ohun tí Ọlọ́run fẹ́ mu. Nípa bẹ́ẹ̀, á máa “nífẹ̀ẹ́ ọkàn ara rẹ̀,” ìyẹn ni pé á máa ṣojúure síra ẹ̀, á sì “rí ire.”—Òwe 19:8.

25 Bi ara rẹ pé: ‘Ṣó dá mi lójú lóòótọ́ pé àwọn ìlànà Ọlọ́run ló yẹ kí n máa tẹ̀ lé? Ǹjẹ́ ó dá mi lójú gbangba pé gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run ló máa mú mi láyọ̀ jù lọ?’ (Sáàmù 19:7-10; Aísáyà 48:17, 18) Bó o bá ń ṣiyè méjì, yáa tètè wá nǹkan ṣe sí i. Ṣàṣàrò lórí ohun tó máa ń yọrí sí béèyàn ò bá fi àwọn òfin Ọlọ́run sílò. Láfikún sí ìyẹn, “tọ́ ọ wò, kí [o] sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere” nípa fífi òtítọ́ tí Bíbélì kọ́ni ṣèwà hù àti nípa fífi àwọn èrò tó gbámúṣé kún ọkàn rẹ, ìyẹn àwọn èrò tó jẹ́ òótọ́, tó jẹ́ òdodo, tó jẹ́ mímọ́ níwà, tó dára ní fífẹ́, tó sì jẹ́ oníwà funfun. (Sáàmù 34:8; Fílípì 4:8, 9) Wàá wá rí i pé bó o bá ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run á túbọ̀ máa pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni wàá sì máa kórìíra ohun tó bá kórìíra. Jósẹ́fù kì í ṣe ẹni pípé. Síbẹ̀, ó “sá fún àgbèrè” torí pé fún ọ̀pọ̀ ọdún ló fi jẹ́ kí Jèhófà mọ òun, kóun bàa lè jẹ́ ẹni tó ń fẹ́ láti máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run. Ǹjẹ́ kí Jèhófà fún ìwọ náà ní irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀.—Aísáyà 64:8.

26. Kókó pàtàkì wo ló kàn tá a máa jíròrò?

26 Torí ká lè mú irú ọmọ jáde ká sì lè gbádùn ìfararora tímọ́tímọ́ nínú ìgbéyàwó ni Ọlọ́run ṣe fún wa ní ẹ̀yà ìbímọ, kì í ṣe ohun ìṣeré. (Òwe 5:18) A máa jíròrò ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìgbéyàwó nínú orí méjì tó tẹ̀ lé èyí.

^ ìpínrọ̀ 4 Gbogbo àwọn “olórí nínú àwọn ènìyàn náà,” tó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọkùnrin [1,000], táwọn onídàájọ́ pa àtàwọn tí Jèhófà fúnra rẹ̀ pa, wà lára àwọn tí ìwé Númérì sọ pé wọ́n bá ẹ̀ṣẹ̀ náà rìn.—Númérì 25:4, 5.

^ ìpínrọ̀ 7 Bó o bá fẹ́ ka ohun tá a sọ nípa ìwà àìmọ́ àti ìwà àìníjàánu, ka “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 2006.

^ ìpínrọ̀ 9 “Àwọn ohun tó ń mọ́kàn fà sí ìṣekúṣe” tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbí yìí túmọ̀ sí àwòrán, ìwé, ọ̀rọ̀ orin, tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu tó máa ń mú kéèyàn fẹ́ láti ní ìbálòpọ̀. Ó sì tún lè jẹ́ àwòrán tó ń fàwọn kọ́lọ́fín ara hàn, tàbí ti àwọn èèyàn tó ń bára wọn lò pọ̀ bí ajá.

^ ìpínrọ̀ 9 Àlàyé tó dá lórí fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni wà nínú “Jáwọ́ Nínú Fífọwọ́ Pa Ẹ̀yà Ìbímọ Rẹ.”