Máa Ka Bíbélì Lójoojúmọ́
Tó o bá ń ka Bíbélì, wàá gbádùn ẹ̀ gan-an! Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nìyí. Yan àkòrí kan tó o fẹ́ràn, kó o sì ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀.
Ìtàn Àwọn Èèyàn Tó Gbajúmọ̀
-
Nóà àti Ìkún Omi: Jẹ́nẹ́sísì 6:9–9:19
-
Mósè àti Òkun Pupa: Ẹ́kísódù 13:17–14:31
-
Rúùtù àti Náómì: Rúùtù orí 1 sí 4
-
Dáfídì àti Gòláyátì: 1 Sámúẹ́lì orí 17
-
Ábígẹ́lì: 1 Sámúẹ́lì 25:2-35
-
Dáníẹ́lì nínú ihò kìnnìún: Dáníẹ́lì orí 6
-
Èlísábẹ́tì àti Màríà: Lúùkù orí 1-2
Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Tó Wúlò fún Wa Lójoojúmọ́
-
Ìdílé: Éfésù 5:28, 29, 33; 6:1-4
-
Yíyan ọ̀rẹ́: Òwe 13:20; 17:17; 27:17
-
Àdúrà: Sáàmù 55:22; 62:8; 1 Jòhánù 5:14
-
Ìwàásù Orí Òkè: Mátíù orí 5-7
-
Iṣẹ́: Òwe 14:23; Oníwàásù 3:12, 13; 4:6
Ohun Tó Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ . . .
-
Tó o bá rẹ̀wẹ̀sì: Sáàmù 23; Àìsáyà 41:10
-
Tí èèyàn ẹ bá kú: 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4; 1 Pétérù 5:7
-
Tí ọkàn ẹ bá ń dá ẹ lẹ́bi: Sáàmù 86:5; Ìsíkíẹ́lì 18:21, 22
Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa . . .
-
Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn: Mátíù 24:3-14; 2 Tímótì 3:1-5
-
Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú: Sáàmù 37:10, 11, 29; Ìfihàn 21:3, 4
ÀBÁ: Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà lókè yìí, ka àwọn orí Bíbélì náà látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Bó o ṣe ń ka orí kọ̀ọ̀kan nínú Bíbélì, lo àtẹ náà “Sàmì sí Ibi Tó O Ka Bíbélì Dé” tó wà níparí ìwé yìí láti sàmì sí ibi tó o kà á dé. Gbìyànjú kó o máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ì báà tiẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lo lè kà.