Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àlàyé Ìparí Ìwé

Àlàyé Ìparí Ìwé
  1.  Bí A Ṣe Dá Bábílónì Ńlá Mọ̀

  2.  Ìgbà Wo Ni Mèsáyà Máa Fara Hàn?

  3.  Ohun Tó Yẹ Kó O Fi Sọ́kàn Tó O Bá Fẹ́ Gba Ìtọ́jú Tó Jẹ Mọ́ Lílo Ẹ̀jẹ̀

  4.  Ohun Tó Lè Mú Kí Tọkọtaya Pínyà

  5.  Àwọn Ayẹyẹ Tí Inú Ọlọ́run Ò Dùn Sí

  6.  Àrùn Tó Ń Ranni

  7.  Ọ̀rọ̀ Ìṣòwò àti Ọ̀rọ̀ Tó Jẹ Mọ́ Òfin

 1. Bí A Ṣe Dá Bábílónì Ńlá Mọ̀

Báwo la ṣe mọ̀ pé gbogbo ẹ̀sìn èké pátá ni “Bábílónì Ńlá” ń ṣàpẹẹrẹ? (Ìfihàn 17:5) Jẹ́ ká wo ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀:

  • Gbogbo ayé pátá ni agbára ẹ̀ dé. Bíbélì sọ pé Bábílónì Ńlá jókòó sórí “èrò rẹpẹtẹ àti àwọn orílẹ̀-èdè.” Ó ń “jọba lórí àwọn ọba ayé.”​—Ìfihàn 17:15, 18.

  • Bábílónì Ńlá kì í ṣe ètò ìṣèlú tàbí ètò ìṣòwò. “Àwọn ọba ayé” àtàwọn “oníṣòwò” máa rí Bábílónì Ńlá nígbà tó bá pa run.​—Ìfihàn 18:9, 15.

  • Bábílónì Ńlá kò ṣojú fún Ọlọ́run. Ìdí tí Bíbélì fi pe Bábílónì Ńlá ní aṣẹ́wó ni pé ó sún mọ́ àwọn olóṣèlú àtàwọn ìjọba ayé kó lè máa rí owó àtàwọn nǹkan míì gbà lọ́wọ́ wọn. (Ìfihàn 17:1, 2) Ó ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Ó sì ti fa ikú ọ̀pọ̀ èèyàn.​—Ìfihàn 18:23, 24.

Pa dà sí ẹ̀kọ́ 13 kókó 6

 2. Ìgbà Wo Ni Mèsáyà Máa Fara Hàn?

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin (69) ni Mèsáyà máa dé.​—Ka Dáníẹ́lì 9:25.

  • Ìgbà wo ni ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin yẹn bẹ̀rẹ̀? Ọdún 455 Ṣ.S.K. ni ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin yẹn bẹ̀rẹ̀. Ọdún yẹn ni Gómìnà Nehemáyà lọ sí Jerúsálẹ́mù láti ‘dá ìlú náà pa dà sí bó ṣe wà, kí wọ́n sì tún un kọ́.’​—Dáníẹ́lì 9:25; Nehemáyà 2:1, 5-8.

  • Báwo ni ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin náà ṣe gùn tó? Nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan, ọjọ́ kan máa ń ṣàpẹẹrẹ ọdún kan. (Nọ́ńbà 14:34; Ìsíkíẹ́lì 4:6) Èyí fi hàn pé ọ̀sẹ̀ kan jẹ́ ọdún méje. Torí náà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin (69) jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti ọgọ́rin ó lé mẹ́ta (483) ọdún, (ìyẹn 69 ọ̀sẹ̀ ní ìlọ́po 7 ọjọ́).

  • Ìgbà wo ni ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin náà parí? Tá a bá ka ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti ọgọ́rin ó lé mẹ́ta (483) ọdún láti ọdún 455 Ṣ.S.K, ó máa gbé wa dé ọdún 29 S.K. a Ọdún yẹn gangan ni Jésù ṣèrìbọmi tó sì di Mèsáyà!​—Lúùkù 3:1, 2, 21, 22.

Pa dà sí ẹ̀kọ́ 15 kókó 5

 3. Ohun Tó Yẹ Kó O Fi Sọ́kàn Tó O Bá Fẹ́ Gba Ìtọ́jú Tó Jẹ Mọ́ Lílo Ẹ̀jẹ̀

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà táwọn dókítà máa ń gbà tọ́jú aláìsàn ni pé kí wọ́n lo ẹ̀jẹ̀ aláìsàn fúnra ẹ̀. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo irú ìtọ́jú yẹn làwa Kristẹni máa ń gbà. Bí àpẹẹrẹ, a kì í jẹ́ káwọn dókítà gba ẹ̀jẹ̀ wa sílẹ̀, kí wọ́n wá fà á pa dà sí wa lára nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ fún wa tàbí tí wọ́n bá fẹ́ tọ́jú wa láwọn ọ̀nà míì. Bákan náà, a kì í fi ẹ̀jẹ̀ tọrẹ kí wọ́n lè fi tọ́jú aláìsàn míì.​—Diutarónómì 15:23.

Àmọ́, àwọn ìtọ́jú míì wà tó lè gba pé kí dókítà lo ẹ̀jẹ̀, síbẹ̀ tó lè má burú fún Kristẹni kan láti gbà. Lára wọn ni àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀, kí wọ́n fi ẹ̀rọ sẹ́ ẹ̀jẹ̀ ẹnì kan, kí wọ́n sì dá a pa dà sí i lára, kí wọ́n da oògùn tó ń mẹ́jẹ̀ pọ̀ sí i mọ́ ẹ̀jẹ̀ ẹnì kan, kí wọ́n gbe ẹ̀jẹ̀ aláìsàn tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ abẹ fún un lọ́wọ́, kí wọ́n lè dá a pa dà sí i lára lẹ́yìn tí wọ́n bá parí iṣẹ́ abẹ tàbí kí wọ́n lo ẹ̀rọ tó ń fa ẹ̀jẹ̀ jáde, táá jẹ́ kí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn wọnú ẹ̀ táá sì tún dá a pa dà sínú ara. Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bó ṣe fẹ́ kí wọ́n lo ẹ̀jẹ̀ òun tí wọ́n bá fẹ́ tọ́jú òun, tí wọ́n bá fẹ́ ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ òun tàbí tí wọ́n bá fẹ́ fọ ẹ̀jẹ̀ òun. Ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ máa ń wà nínú ọ̀nà tí dókítà kọ̀ọ̀kan máa ń gbà ṣe ìtọ́jú yìí. Torí náà, kí Kristẹni kan tó gbà kí dókítà ṣiṣẹ́ abẹ, ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ tàbí bẹ̀rẹ̀ ìtọ́jú èyíkéyìí fún òun, ó gbọ́dọ̀ béèrè ọ̀nà tí dókítà náà fẹ́ gbà lo ẹ̀jẹ̀ òun. Á dáa kó ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ṣé wọ́n máa fà lára ẹ̀jẹ̀ mi, tí wọ́n á sì tọ́jú ẹ̀ pa mọ́, fún àkókò díẹ̀? Ṣé mo máa gbà pé ẹ̀jẹ̀ mi náà ṣì ni, àbí ẹ̀rí ọkàn á máa sọ fún mi pé ńṣe ló yẹ kí n “dà á sórí ilẹ̀ bí omi”?​—Diutarónómì 12:23, 24.

  • Kí ni màá ṣe tí ìtọ́jú tí wọ́n fẹ́ fún mi bá gba pé kí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ mi jáde kí wọ́n lè fi ẹ̀rọ sẹ́ ẹ tàbí da oògùn mọ́ ọn kí wọ́n tó dá a pa dà sínú ara mi? Ṣé mo máa fara mọ́ irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ àbí ó máa da ẹ̀rí ọkàn mi láàmú?

Pa dà sí ẹ̀kọ́ 39 kókó 3

 4. Ohun Tó Lè Mú Kí Tọkọtaya Pínyà

Bíbélì ò fọwọ́ sí i pé kí tọkọtaya pínyà, tí wọ́n bá sì pínyà Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé wọn ò lómìnira láti fẹ́ ẹlòmíì. (1 Kọ́ríńtì 7:10, 11) Àmọ́, àwọn nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ tó máa mú kí Kristẹni kan pinnu pé á dáa kóun àti ọkọ tàbí aya òun pínyà.

  • Tẹ́nì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ láti pèsè fún ìdílé rẹ̀: Tí ọkọ kan bá kọ̀ láti pèsè ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò, tí ọ̀rọ̀ náà sì le débi pé ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀ ò ní àwọn nǹkan pàtàkì tí wọ́n nílò.​—1 Tímótì 5:8.

  • Tẹ́nì kan bá ń lu ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ nílùkulù: Ẹnì kan lè máa lu ọkọ tàbí ìyàwó ẹ̀ tàbí kó máa hùwà ìkà sí i débi pé ẹ̀mí onítọ̀hún wà nínú ewu tàbí kó ṣàkóbá fún ìlera ẹ̀.​—Gálátíà 5:19-21.

  • Tẹ́nì kan bá ń ta ko ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ débi tí ò fi ní lè sin Jèhófà tàbí tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì: Tí ọkọ tàbí aya kan bá ń ṣe àwọn nǹkan tí ò ní jẹ́ kí ẹnìkejì ẹ̀ sin Jèhófà tàbí pa òfin Ọlọ́run mọ́.​—Ìṣe 5:29.

Pa dà sí ẹ̀kọ́ 42 kókó 3

 5. Àwọn Ayẹyẹ Tí Inú Ọlọ́run Ò Dùn Sí

Àwa Kristẹni kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tínú Jèhófà ò dùn sí. Àmọ́, Kristẹni kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tó bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu tó bá fẹ́ pinnu ohun tó máa ṣe nígbà táwọn èèyàn bá ń ṣe ayẹyẹ. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀.

  • Tẹ́nì kan bá kí ẹ kú ọdún. O lè sọ pé, “Ẹ ṣeun.” Tẹ́ni náà bá fẹ́, o lè jẹ́ kó mọ ìdí tí o ò fi ń lọ́wọ́ sí ayẹyẹ náà.

  • Tí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá pè ẹ́ síbi àpèjẹ tí òun àtàwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ fẹ́ ṣe nígbà ayẹyẹ kan. Tí ẹ̀rí ọkàn ẹ bá gbà ẹ́ láyè láti lọ, kó o tó lọ síbẹ̀ o lè ṣàlàyé fún ẹnìkejì rẹ pé o ò ní bá wọn lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà tàbí ààtò ẹ̀sìn tí wọ́n bá ṣe níbi àpèjẹ náà.

  • Tẹ́ni tó gbà ẹ́ síṣẹ́ bá fún ẹ ní àjẹmọ́nú lásìkò ọdún. Ṣé ó yẹ kó o kọ àjẹmọ́nú náà? Kò pọn dandan kó o kọ̀ ọ́. Ṣé torí ọdún ló ṣe fún ẹ ní àjẹmọ́nú yẹn àbí torí kó lè dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ torí gbogbo ohun tó ò ń ṣe fún ilé iṣẹ́ náà?

  • Tẹ́nì kan bá fún ẹ lẹ́bùn lásìkò ọdún. Ẹni náà lè sọ fún ẹ pé: “Mo mọ̀ pé o kì í bá wa ṣọdún, àmọ́ ó kàn wù mí kí ń fún ẹ lẹ́bùn yìí.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe lẹni náà kàn ń fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn sí ẹ. Àmọ́, á dáa kó o tún wò ó bóyá ṣe lẹni náà ń gbìyànjú láti dán ẹ wò bóyá ohun tó o gbà gbọ́ dá ẹ lójú àbí kó tiẹ̀ fẹ́ dọ́gbọ́n mú kó o bá wọn lọ́wọ́ sí ayẹyẹ náà? Lẹ́yìn tó o bá ti ronú lórí àwọn nǹkan yìí, ìwọ lo máa pinnu bóyá wàá gba ẹ̀bùn náà àbí o ò ní gbà á. Nínú gbogbo ìpinnu tá a bá ń ṣe, ó yẹ ká rí i pé a ṣe ohun táá jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa mọ́, táá sí fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.​—Ìṣe 23:1.

Pa dà sí ẹ̀kọ́ 44 kókó 1

 6. Àrùn Tó Ń Ranni

Torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, a máa ń ṣe gbogbo ohun tó yẹ ká ṣe ká má bàa kó àrùn ràn wọ́n. A máa ń kíyè sára tá a bá rí i pé a ní àrùn tó lè ranni tàbí tá a bá rí i pé ó ṣeé ṣe ká ti kó àrùn tó lè ranni. Ìdí tá a sì fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a fẹ́ tẹ̀ lé àṣẹ Bíbélì tó sọ pé: “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”​—Róòmù 13:8-10.

Báwo lẹnì kan tó kó àrùn tó ń ranni ṣe lè fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn? Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò ní máa bọ àwọn èèyàn lọ́wọ́, kò ní máa gbá wọn mọ́ra tàbí fẹnu kò wọ́n lẹ́nu láti fìfẹ́ hàn sí wọn. Kò sì ní máa bínú táwọn kan ò bá fẹ́ kó wá sílé wọn torí kí wọ́n lè dáàbò bo ìdílé wọn. Bákan náà, kó tó ṣèrìbọmi á jẹ́ kí olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà mọ̀ nípa àrùn tó ní, kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe máa dáàbò bo àwọn tí wọ́n jọ fẹ́ ṣèrìbọmi lọ́jọ́ kan náà. Yàtọ̀ síyẹn, tẹ́nì kan bá mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kóun ti kó àrùn tó ń ranni, ó yẹ kẹ́ni náà ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹnì kan sọ́nà. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, àá fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ wá lógún, ìyẹn á sì fi hàn pé à ‘ń wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiwa nìkan.’​—Fílípì 2:4.

Pa dà sí ẹ̀kọ́ 56 kókó 2

 7. Ọ̀rọ̀ Ìṣòwò àti Ọ̀rọ̀ Tó Jẹ Mọ́ Òfin

A lè yẹra fún ìṣòro tá a bá rí i pé a ṣe ìwé àdéhùn lórí ọ̀rọ̀ okòwò tó pa àwa àti ẹlòmíì pọ̀, kódà tí ẹni náà bá jẹ́ Kristẹni. (Jeremáyà 32:9-12) Àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ọ̀rọ̀ nípa owó tàbí àwọn nǹkan míì lè fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwa àti Kristẹni kan. Ó yẹ ká tètè wá bá a ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà, ká sì ṣe bẹ́ẹ̀ láìsí ìjà.

Àmọ́, kí la lè ṣe tí ọ̀rọ̀ náà bá nira gan-an, irú bíi kí wọ́n lu Kristẹni kan ní jìbìtì tàbí kí wọ́n bà á lórúkọ jẹ́? Báwo la ṣe lè yanjú ọ̀rọ̀ náà? (Ka Mátíù 18:15-17.) Jésù sọ àwọn nǹkan mẹ́ta tá a lè ṣe:

  1. Gbìyànjú láti lọ bá ẹni yẹn kẹ́ ẹ lè yanjú ọ̀rọ̀ náà láàárín ara yín.​—Wo ẹsẹ 15.

  2. Tọ́rọ̀ náà ò bá yanjú, ní kí Kristẹni kan tàbí méjì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn bá ẹ lọ síbẹ̀.​—Wo ẹsẹ 16.

  3. Tọ́rọ̀ náà ò bá tíì yanjú, o lè ní kí àwọn alàgbà ràn ẹ́ lọ́wọ́.​—Wo ẹsẹ 17.

Ohun tó dáa jù ni pé ká má ṣe máa gbé arákùnrin tàbí arábìnrin wa lọ sílé ẹjọ́ torí ìyẹn lè mú káwọn èèyàn máa sọ ohun tí ò dáa nípa Jèhófà àti ìjọ Kristẹni. (1 Kọ́ríńtì 6:1-8) Àmọ́, àwọn nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé kí Kristẹni kan gbé ọ̀rọ̀ lọ sílé ẹjọ́. Lára irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ nípa ìkọ̀sílẹ̀, ọ̀dọ̀ ẹni tí ọmọ máa wà lẹ́yìn tí tọkọtaya kọ ara wọn sílẹ̀, owó tí ọkọ tàbí ìyàwó kan á máa fi ṣètìlẹyìn fún ẹnìkejì rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀, bí ẹnì kan ṣe máa gba owó ìbánigbófò, bí ẹnì kan ṣe máa rí owó ẹ̀ gbà lọ́wọ́ báǹkì tó wọko gbèsè tàbí ọ̀rọ̀ nípa ìwé ìhágún. Tí Kristẹni kan bá pinnu láti gbé irú ọ̀rọ̀ yìí lọ sílé ẹjọ́ láìsí ìjà, kò ṣe ohun tó ta ko ìlànà Bíbélì.

Kristẹni kan lè pinnu láti gbé ọ̀rọ̀ ìwà ọ̀daràn lọ sọ́dọ̀ àwọn agbófinró, irú bí ìfipábánilòpọ̀, bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe, kéèyàn jí nǹkan ńlá, kẹ́nì kan pa èèyàn tàbí kí wọ́n hu ìwà ìkà míì sí ẹnì kan. Nírú ipò yìí, ohun tí Kristẹni náà ṣe ò ta ko ìlànà Bíbélì.

Pa dà sí ẹ̀kọ́ 56 kókó 3

a Ọdún 455 Ṣ.S.K. sí ọdún 1 Ṣ.S.K. jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti àádọ́ta ó lé mẹ́rin (454) ọdún. Ọdún 1 Ṣ.S.K. sí 1 S.K. jẹ́ ọdún kan (kò sí ọdún òfo). Bákan náà ọdún 1 S.K. sí 29 S.K. jẹ́ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n (28). Àròpọ̀ gbogbo ẹ̀ wá jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti ọgọ́rin ó lé mẹ́ta (483) ọdún.