Ẹ̀KỌ́ 15
Ta Ni Jésù?
Jésù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó lókìkí jù lọ nínú ìtàn aráyé. Ọ̀pọ̀ ló mọ orúkọ ẹ̀, àmọ́ wọn ò mọ òun fúnra ẹ̀ dáadáa. Oríṣiríṣi nǹkan lọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ nípa Jésù. Àmọ́, kí ni Bíbélì sọ nípa ẹ̀?
1. Ta ni Jésù?
Áńgẹ́lì alágbára ni Jésù, ọ̀run ló sì ń gbé. Òun ni Jèhófà Ọlọ́run kọ́kọ́ dá kó tó dá àwọn nǹkan tó kù. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Jésù ní “àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Bíbélì tún pe Jésù ní ‘Ọmọ bíbí kan ṣoṣo’ Ọlọ́run, torí pé Jésù nìkan ṣoṣo ni Jèhófà fúnra ẹ̀ dá ní tààràtà. (Jòhánù 3:16) Jésù bá Jèhófà Bàbá rẹ̀ ṣiṣẹ́ láti dá gbogbo nǹkan yòókù. (Ka Òwe 8:30.) Àjọṣe àárín Jésù àti Jèhófà ṣì dáa gan-an títí dòní. Jésù jẹ́ olóòótọ́ tó ń gbẹnu sọ fún Ọlọ́run, òun sì ni Bíbélì pè ní “Ọ̀rọ̀” tó ń jíṣẹ́ Ọlọ́run.—Jòhánù 1:14.
2. Kí nìdí tí Jésù fi wá sáyé?
Ní ohun to lé díẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn, Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lọ́nà ìyanu láti fi ẹ̀mí Jésù sínú wúńdíá kan tó ń jẹ́ Màríà. Bó ṣe di pé wọ́n bí Jésù sáyé nìyẹn. (Ka Lúùkù 1:34, 35.) Jésù ni Mèsáyà tàbí Kristi tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa rán wá sáyé kó lè gba aráyé là. a Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa Mèsáyà ló ṣẹ sí Jésù lára, ìyẹn ló sì mú káwọn èèyàn dá a mọ̀ pé òun ni “Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”—Mátíù 16:16.
3. Ibo ni Jésù wà báyìí?
Lẹ́yìn tí Jésù kú, Ọlọ́run jí i dìde ní ẹni ẹ̀mí, ó sì pa dà sí ọ̀run. Nígbà tó dé ọ̀run, ‘Ọlọ́run gbé e sí ipò gíga.’ (Fílípì 2:9) Ní báyìí, aláṣẹ ńlá ni Jésù, ipò Jèhófà nìkan ló sì ju tiẹ̀ lọ.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Kẹ́kọ̀ọ́ sí i kó o lè túbọ̀ mọ Jésù àti ìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé kó o mọ̀ ọ́n dáadáa.
4. Jésù kọ́ ni Ọlọ́run Olódùmarè
Bíbélì kọ́ni pé áńgẹ́lì alágbára ni Jésù, ọ̀run ló sì ń gbé. Àmọ́, ó máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà tó jẹ́ Bàbá àti Ọlọ́run rẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Wo FÍDÍÒ yìí kó o lè rí ohun tí Bíbélì sọ nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín Ọlọ́run Olódùmarè àti Jésù.
Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín Jèhófà àti Jésù. Ka ẹsẹ Bíbélì kọ̀ọ̀kan, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Ka Lúùkù 1:30-32.
-
Kí ni áńgẹ́lì kan sọ nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín Jésù àti Jèhófà Ọlọ́run, “Ẹni Gíga Jù Lọ”?
Ka Mátíù 3:16, 17.
-
Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, kí ni ohùn tó dún látọ̀run sọ?
-
Ta lo rò pé ó sọ̀rọ̀ yẹn?
Ka Jòhánù 14:28.
-
Nínú ọmọ àti bàbá, ta ló dàgbà jù, tó sì láṣẹ jù?
-
Kí ni Jésù fẹ́ ká mọ̀ nígbà tó pe Jèhófà ní Bàbá?
Ka Jòhánù 12:49.
-
Ṣé Jésù gbà pé ẹnì kan náà ni òun àti Bàbá òun? Kí lèrò tìẹ?
5. Ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù ni Mèsáyà
Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ló wà nínú Bíbélì tó jẹ́ káwọn èèyàn dá Mèsáyà mọ̀, ìyẹn ẹni tí Ọlọ́run yàn láti gba aráyé là. Wo FÍDÍÒ yìí kó o lè mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ṣẹ sí Jésù lára nígbà tó wá sáyé.
Ka àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e:
Ka Míkà 5:2 kó o lè mọ ibi tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé wọ́n máa bí Mèsáyà sí. b
-
Ṣé ibi tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ ni wọ́n bí Jésù sí lóòótọ́?—Mátíù 2:1.
Ka Sáàmù 34:20 àti Sekaráyà 12:10 kó o lè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa ikú Mèsáyà.
-
Ṣé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ?—Jòhánù 19:33-37.
-
Ṣé o rò pé Jésù fúnra ẹ̀ ló dọ́gbọ́n sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà kó lè ṣẹ?
-
Lérò tìẹ, báwo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ yìí ṣe jẹ́ ká mọ ẹni tí Jésù jẹ́?
6. A máa jàǹfààní púpọ̀ tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù àti iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un. Ka Jòhánù 14:6 àti 17:3, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
-
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká kékọ̀ọ́ nípa Jésù?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò gba Jésù gbọ́.”
-
Kí lèrò tìẹ?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Áńgẹ́lì alágbára ni Jésù. Òun ni Ọmọ Ọlọ́run, òun sì ni Mèsáyà.
Kí lo rí kọ́?
-
Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Jésù ní “àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá”?
-
Kí ni Jésù ń ṣe kó tó wá sáyé?
-
Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà?
ṢÈWÁDÌÍ
Kẹ́kọ̀ọ́ sí i kó o lè rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù ni Mèsáyà.
“Ṣé Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà Fẹ̀rí Hàn Pé Jésù Ni Mèsáyà Náà?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
Wádìí kó o lè mọ bóyá Bíbélì kọ́ni pé bí èèyàn ṣe máa ń bímọ ni Ọlọ́run ṣe bí Jésù.
“Kí Nìdí Tí A Fi Pe Jésù Ní Ọmọ Ọlọ́run?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ìdí tí Mẹ́talọ́kan kì í fi í ṣe ẹ̀kọ́ Bíbélì.
Ka ìwé yìí kó o lè mọ bí ìgbésí ayé obìnrin kan ṣe yí pa dà lẹ́yìn tó wádìí ohun tí Bíbélì sọ nípa Jésù.
“Obìnrin Júù Kan Sọ Ìdí Tó Fi Yí Ẹ̀sìn Rẹ̀ Pa Dà” (Jí!, July-August 2013)
a Ní ẹ̀kọ́ 26 àti 27, a máa mọ ìdí tó fi pọn dandan pé kí ẹnì kan gba aráyé là àti bí Jésù ṣe gbà wá là.
b Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 2 kó o lè rí àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ ìgbà tí Mèsáyà máa fara hàn gangan.