Ohun Tó O Kọ́ Ní Apá 1
Kí ìwọ àti ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí:
Àwọn nǹkan wo ló wù ẹ́ jù nínú àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la?
(Wo Ẹ̀kọ́ 02.)
Kí nìdí tó o fi gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì?
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà?
(Wo Ẹ̀kọ́ 04.)
Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ni “orísun ìyè.” (Sáàmù 36:9) Ṣó o gbà pé òótọ́ ni?
(Wo Ẹ̀kọ́ 06.)
Ka Òwe 3:32.
Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ Ọ̀rẹ́ tó dáa jù lọ?
Kí ni Jèhófà ń retí pé káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ṣe? Ṣó o rò pé ó bọ́gbọ́n mu?
Ka Sáàmù 62:8.
Àwọn nǹkan wo lo ti torí ẹ̀ gbàdúrà sí Jèhófà? Àwọn nǹkan míì wo lo tún lè bá Jèhófà sọ nínú àdúrà rẹ?
Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àdúrà?
(Wo Ẹ̀kọ́ 09.)
Ka Hébérù 10:24, 25.
Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ń wá sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
Ṣó o rò pé ó yẹ kó o máa lọ sípàdé kódà láwọn ìgbà tí kò bá rọrùn?
(Wo Ẹ̀kọ́ 10.)
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ka Bíbélì déédéé? Ìgbà wo lo máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́?
(Wo Ẹ̀kọ́ 11.)
Àwọn nǹkan wo lo gbádùn jù lọ látìgbà tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Látìgbà tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ìṣòro wo lo ti dojú kọ tó lè mú kó o dá ẹ̀kọ́ Bíbélì rẹ dúró? Kí lo lè ṣe kó o lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó?
(Wo Ẹ̀kọ́ 12.)