Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 6
Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àgọ́ ìjọsìn ni wọ́n ti máa ń jọ́sìn Jèhófà. Àwọn àlùfáà máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Ọlọ́run, àwọn onídàájọ́ sì máa ń darí wọn. Apá yìí máa jẹ́ ká rí i pé ohun tí ẹnì kan bá ṣe lè ṣàkóbá fáwọn míì tàbí kó ṣe wọ́n láǹfààní. Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ló gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì tún nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn. Kọ́ ọmọ rẹ nípa Dèbórà, Náómì, Jóṣúà, Hánà, ọmọbìnrin Jẹ́fútà àti Sámúẹ́lì. Jẹ́ kó rí i pé àwọn ìpinnu tí wọ́n ṣe nípa lórí àwọn míì. Tẹnu mọ́ ọn pé àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì pàápàá irú bíi Ráhábù, Rúùtù, Jáẹ́lì àtàwọn ará Gíbéónì pinnu láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí wọ́n rí i pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn.
NÍ APÁ YÌÍ
Ẹ̀KỌ́ 30
Ráhábù Fi Àwọn Amí Pa Mọ́
Ògiri Jẹ́ríkò wó lulẹ̀. Àmọ́ ilé Ráhábù dúró bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara ògiri yẹn ni wọ́n kọ́ ọ mọ́.
Ẹ̀KỌ́ 31
Jóṣúà àti Àwọn Ará Gíbíónì
Jóṣúà gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí “oòrùn, dúró sójú kan.” Ṣé Ọlọ́run gbọ́ àdúrà ẹ̀?
Ẹ̀KỌ́ 32
Aṣáájú Tuntun àti Obìnrin Onígboyà Méjì
Lẹ́yìn tí Jóṣúà kú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn òrìṣà. Àwọn ọ̀tá wá ń ni wọ́n lára, àmọ́ Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́ nípasẹ̀ Bárákì, wòlí ì Dèbórà àti Jáẹ́lì tó lo ìṣó tó fi ń kan àgọ́.
Ẹ̀KỌ́ 33
Rúùtù àti Náómì
Àwọn obìnrin méjì tí ọkọ wọn ti kú pa dà sí Ísírélì. Èyí tó ń jẹ́ Rúùtù lọ ṣiṣẹ́ lóko, Bóásì sì kíyè sí i.
Ẹ̀KỌ́ 34
Gídíónì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Mídíánì
Nígbà táwọn ará Mídíánì fòòró ẹ̀mí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Báwo làwọn ọmọ ogun Gídíónì ṣe ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún márùnléláàádóje (135,000) ọ̀tá?
Ẹ̀KỌ́ 35
Hánà Gbàdúrà Pé Kí Ọlọ́run Fún Òun ní Ọmọkùnrin
Ẹlikénà mú Hánà, Pẹ̀nínà àtàwọn ọmọ ẹ̀ lọ jọ́sìn ní àgọ́ ìjọsìn ní Ṣílò. Níbẹ̀, Hánà gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún òun ní ọmọkùnrin. Lẹ́yìn ọdún kan, ó bí Sámúẹ́lì.
Ẹ̀KỌ́ 36
Ìlérí Tí Jẹ́fútà Ṣe
Ìlérí wo ni Jẹ́fútà ṣe, kí sì nìdí? Kí ni ọmọbìnrin Jẹ́fútà ṣe nígbà tó gbọ́ nípa ìlérí bàbá ẹ̀?
Ẹ̀KỌ́ 37
Jèhófà Bá Sámúẹ́lì Sọ̀rọ̀
Élì Àlùfáà Àgbà ní ọmọkùnrin méjì tó ń sìn ní àgọ́ ìjọsìn, àmọ́ wọn ò pa òfin Ọlọ́run mọ́. Sámúẹ́lì yàtọ̀ ní tiẹ̀. Lálẹ́ ọjọ́ kan, Jèhófà bá Sámúẹ́lì sọ̀rọ̀.
Ẹ̀KỌ́ 38
Jèhófà Sọ Sámúsìn Di Alágbára
Ọlọ́run mú kí Sámúsìn lágbára láti bá àwọn Filísínì jà. Àmọ́ nígbà tí Sámúsìn ṣèpinnu tí ò dáa, àwọn Filísínì sì mú un.