Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 4

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 4

Apá yìí máa jẹ́ ká mọ̀ nípa Jósẹ́fù, Jóòbù, Mósè àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Gbogbo wọn fara da àwọn ìṣòro tí Èṣù gbé kò wọ́n. Wọ́n fìyà jẹ àwọn kan, wọ́n sì sọ àwọn míì sẹ́wọ̀n. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n sọ àwọn kan di ẹrú, àwọn míì sì pàdánù àwọn èèyàn wọn. Síbẹ̀, Jèhófà dáàbò bò wọ́n ní onírúurú ọ̀nà. Tó o bá jẹ́ òbí, ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kó lè rí báwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yẹn ṣe jẹ́ olóòótọ́ láìka ìyà tí wọ́n jẹ.

Jèhófà lo ìyọnu mẹ́wàá (10) láti fi hàn pé òun lágbára ju àwọn òrìṣà táwọn ọmọ Íjíbítì ń bọ. Jẹ́ káwọn ọmọ ẹ rí bí Jèhófà ṣe dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ láyé àtijọ́ àti bó ṣe ń dáàbò bò wọ́n lónìí.

NÍ APÁ YÌÍ

Ẹ̀KỌ́ 14

Ẹrú Tó Ṣègbọràn sí Ọlọ́run

Jósẹ́fù ṣe ohun tó tọ́ ṣùgbọ́n ó jìyà gan an. Kí ló dé?

Ẹ̀KỌ́ 15

Jèhófà Ò Gbàgbé Jósẹ́fù

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jósẹ́fù jìnnà sáwọn ẹbí ẹ̀, Jèhófà dúró tì í.

Ẹ̀KỌ́ 16

Ta Ni Jóòbù?

Ó ṣègbọràn sí Jèhófà kódà nígbà tó níṣòro.

Ẹ̀KỌ́ 17

Mósè Pinnu Láti Jọ́sìn Jèhófà

Ohun tí màmá Mósè ṣe ló gba ẹ̀mí Mósè là ní kékeré.

Ẹ̀KỌ́ 18

Iná Ń Jó Lára Igi Kékeré Kan

Kí nìdí tí iná yẹn ò fi jó igi náà run?

Ẹ̀KỌ́ 19

Àwọn Ìyọnu Mẹ́ta Àkọ́kọ́

Fáráò fa àjálù bá àwọn èèyàn ẹ̀ torí pé ó jẹ́ agbéraga.

Ẹ̀KỌ́ 20

Àwọn Ìyọnu Mẹ́fà Tó Tẹ̀ Lé E

Báwo làwọn ìyọnu mẹ́fà yìí ṣe yàtọ̀ sí mẹ́ta àkọ́kọ́?

Ẹ̀KỌ́ 21

Ìyọnu Kẹwàá

Ìyonu yìí burú débi pé ara Fáráò ò lè gbà á, ó sì dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀.

Ẹ̀KỌ́ 22

Iṣẹ́ Ìyanu ní Òkun Pupa

Fáráò la àwọn ìyọnu mẹ́wàá já, àmọ́ ṣé ó ye iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run ṣe yìí?