Ẹ̀KỌ́ 9
Sárá Bímọ Nígbà Tó Di Arúgbó!
Ọjọ́ pẹ́ tí Ábúráhámù àti Sárà ti jẹ́ tọkọtaya. Ní ìlú Úrì tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀, àwọn nǹkan tó lẹ́wà wà nílé wọn, àmọ́ ní báyìí, inú àgọ́ ni wọ́n ń gbé. Síbẹ̀, Sárà kò ráhùn, ìdí sì ni pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.
Ó wu Sárà gan-an pé kí òun náà bímọ. Lọ́jọ́ kan, ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé: ‘Mo máa fún ẹ ní Hágárì ìránṣẹ́ mi kí o fi ṣe ìyàwó, tó bá sì bímọ, mo máa tọ́jú ọmọ náà bíi pé ọmọ mi ni.’ Nígbà tó yá, Hágárì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Orúkọ ọmọ náà ni Íṣímáẹ́lì.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn àlejò mẹ́ta kan wá sílé wọn. Nígbà yẹn, Ábúráhámù jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [99] Sárà sì jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún [89]. Ábúráhámù ní kí wọ́n wá sinmi díẹ̀ lábẹ́ igi kí wọ́n sì jẹun. Ǹjẹ́ o mọ àwọn àlejò tó wá sílé wọn? Àwọn áńgẹ́lì ni! Wọ́n sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Ní àsìkò yìí ní ọdún tó ń bọ̀, Sárà ìyàwó rẹ máa bí ọmọkùnrin fún ẹ.’ Sárà ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nínú àgọ́ tó wà. Ó rọra rẹ́rìn-ín, ó sì sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé: ‘Ṣé èmi arúgbó yìí tún lè bímọ ṣá?’
Ọdún kan lẹ́yìn náà, ọ̀rọ̀ áńgẹ́lì Jèhófà ṣẹ, Sárà bí ọmọkùnrin kan. Ábúráhámù sọ ọmọ náà ní Ísákì. Ìtumọ̀ orúkọ ọmọ náà ni “Ẹ̀rín.”
Nígbà kan tí Ísákì jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún márùn-ún [5], Sárà kíyè sí i pé Íṣímáẹ́lì ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́. Torí pé Sárà fẹ́ dáàbò bo Ísákì, ó lọ bá ọkọ rẹ̀, ó sì sọ fún un pé kó lé Hágárì àti Íṣímáẹ́lì lọ. Ábúráhámù kò kọ́kọ́ gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Tẹ́tí sí ohun ti Sárà sọ. Mo máa tọ́jú Íṣímáẹ́lì. Àmọ́, nípasẹ̀ Ísákì ni mo máa gbà mú àwọn ìlérí mi ṣẹ.’
“Nípa ìgbàgbọ́ ni Sárà fúnra rẹ̀ pẹ̀lú gba agbára láti lóyún irú-ọmọ, . . . níwọ̀n bí ó ti ka ẹni tí ó ṣèlérí sí olùṣòtítọ́.” —Hébérù 11:11