Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 100

Pọ́ọ̀lù àti Tímótì

Pọ́ọ̀lù àti Tímótì

Ọ̀dọ́kùnrin kan wà ní ìjọ Lísírà tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Tímótì. Gíríìkì ni bàbá ẹ̀, màmá ẹ̀ sì jẹ́ Júù. Láti kékeré ni màmá ẹ̀ tó ń jẹ́ Yùníìsì àti màmá ẹ̀ àgbà tó ń jẹ́ Lọ́ìsì ti kọ́ ọ nípa Jèhófà.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń rìnrìn àjò kejì láti lọ wàásù, ó lọ sí ìjọ Lísírà. Ó wá kíyè sí i pé Tímótì nífẹ̀ẹ́ àwọn ará gan-an, ó sì máa ń fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù wá ní kí Tímótì tẹ̀ lé òun káwọn lè jọ máa rìnrìn àjò. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Pọ́ọ̀lù kọ́ Tímótì láti di oníwàásù ìhìn rere àti olùkọ́ tó já fáfá.

Ẹ̀mí mímọ́ ló máa ń darí Pọ́ọ̀lù àti Tímótì síbi tí wọ́n máa ń lọ. Lálẹ́ ọjọ́ kan, Pọ́ọ̀lù rí ìran kan. Nínú ìran yẹn, ọkùnrin kan sọ fún Pọ́ọ̀lù pé kó wá sí Makedóníà láti wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Torí náà, Pọ́ọ̀lù, Tímótì, Sílà àti Lúùkù lọ sí Makedóníà láti lọ wàásù, wọ́n sì dá ọ̀pọ̀ ìjọ sílẹ̀.

Ìlú kan wà lágbègbè Makedóníà tó ń jẹ́ Tẹsalóníkà, ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló di Kristẹni níbẹ̀. Àmọ́ àwọn Júù kan bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Pọ́ọ̀lù àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀. Ni wọ́n bá kó èrò rẹpẹtẹ, wọ́n sì mú àwọn Kristẹni kan lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ, wọ́n wá ń pariwo pé: ‘Ọ̀tá ìjọba Róòmù làwọn ọkùnrin yìí!’ Torí pé ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù àti Tímótì ti wà nínú ewu báyìí, nígbà tó dalẹ́ wọ́n sá lọ sílùú Bèróà.

Inú àwọn tó wà nílùú Bèróà dùn gan-an láti gbọ́ ìhìn rere, torí náà ọ̀pọ̀ àwọn Júù àti Gíríìkì ló di Kristẹni. Àmọ́ àwọn Júù kan wá láti ìlú Tẹsalóníkà kí wọ́n lè dá wàhálà sílẹ̀, torí náà Pọ́ọ̀lù kúrò ní Bèróà, ó sì lọ sí Áténì. Àmọ́, Tímótì àti Sílà dúró ní Bèróà kí wọ́n lè ran àwọn ará lọ́wọ́. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, Pọ́ọ̀lù ní kí Tímótì pa dà sí Tẹsalóníkà kó lè ran àwọn ará lọ́wọ́ torí pé àwọn èèyàn ń ta kò wọ́n gan-an. Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù rán Tímótì lọ sí ọ̀pọ̀ ìjọ kó lè lọ ran àwọn ará lọ́wọ́.

Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: ‘Àwọn èèyàn máa ta ko àwọn tó bá fẹ́ jọ́sìn Jèhófà.’ Wọ́n sì ta ko Tímótì, kódà wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n torí ìgbàgbọ́ ẹ̀. Àmọ́ inú ẹ̀ dùn pé òun láǹfààní láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará nílùú Fílípì pé: ‘Màá rán Tímótì sí yín. Ó máa kọ́ yín bẹ́ ẹ ṣe lè jẹ́ olóòótọ́, á sì kọ́ yín bẹ́ ẹ ṣe máa wàásù.’ Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé Tímótì ṣeé fọkàn tán. Torí náà, wọ́n jọ ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.

“Nítorí mi ò ní ẹlòmíì tó níwà bíi tirẹ̀ tó máa fi òótọ́ inú bójú tó ọ̀rọ̀ yín. Torí gbogbo àwọn yòókù ń wá ire ara wọn, kì í ṣe ti Jésù Kristi.”​—Fílípì 2:20, 21