Ẹ̀KỌ́ 99
Ẹ̀ṣọ́ Ọgbà Ẹ̀wọ̀n kan Gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ní Fílípì, ọmọbìnrin kan wà tí ẹ̀mí èṣù ń dà láàmú. Ńṣe ni ẹ̀mí èṣù náà máa ń jẹ́ kí ọmọbìnrin náà máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, èyí sì máa ń pa owó wọlé fún ọ̀gá ọmọbìnrin náà. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dé Fílípì, ọmọbìnrin yìí ń tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù àti Sílà kiri fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́. Ẹ̀mí èṣù yẹn mú kí ọmọbìnrin náà máa pariwo pé: “Àwọn ọkùnrin yìí ni ẹrú Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ.” Níkẹyìn, ó sú Pọ́ọ̀lù, ó sì yí pa dà, ó wá pàṣẹ fún ẹ̀mí èṣù náà pé: ‘Ní orúkọ Jésù Kristi, jáde kúrò nínú rẹ̀.’ Ni ẹ̀mí èṣù yẹn bá jáde kúrò nínú ọmọbìnrin yẹn.
Nígbà tí àwọn ọ̀gá ọmọbìnrin náà rí i pé ọmọbìnrin náà kò ní máa pa owó fún àwọn mọ́, inú bí wọn gan-an. Wọ́n wá mú Pọ́ọ̀lù àti Sílà lọ sí ilé ẹjọ́, wọ́n sì sọ fún adájọ́ pé: ‘Àwọn ọkùnrin yìí ń da ìlú wa rú!’ Ni adájọ́ bá pàṣẹ pé kí wọ́n na Pọ́ọ̀lù àti Sílà lẹ́gba, kí wọ́n sì jù wọ́n sínú ẹ̀wọ̀n. Wọ́n wá sọ Pọ́ọ̀lù àti Sílà sínú ẹ̀wọ̀n tó jìn jù, tó sì ṣókùnkùn. Wọ́n tún fi pákó de ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn.
Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù àti Sílà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orin sí Jèhófà, àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù sì ń gbọ́. Nígbà tó di òru, ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í mì nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Ṣàdédé ni àwọn ilẹ̀kùn ṣí sílẹ̀, gbogbo ohun tí wọ́n fi de àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà sì já. Nígbà tí ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn rí i pé ilẹ̀kùn ti ṣí, ẹ̀rù bà á, ó rò pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ti sá lọ, ló bá fa idà yọ láti pa ara rẹ̀.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí i pé ọkùnrin náà fẹ́ pa ara rẹ̀, ó pariwo pé: ‘Má pa ara rẹ o! Gbogbo wa wà níbí!’ Ọkùnrin náà sáré wá sọ́dọ̀ Pọ́ọ̀lù àti Sílà, ó dojú bolẹ̀, ó sì sọ pé: “Kí ni kí n ṣe láti rí ìgbàlà?” Wọ́n sọ fún un pé: ‘Ìwọ àti ìdílé rẹ gbọ́dọ̀ gba Jésù gbọ́.’ Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù àti Sílà kọ́ ọkùnrin náà àti ìdílé rẹ̀ ní ọ̀rọ̀ Jèhófà, gbogbo wọn sì ṣe batisí.
“Àwọn ènìyàn yóò gbé ọwọ́ wọn lé yín, wọn yóò sì ṣe inúnibíni sí yín, ní fífà yín lé àwọn sínágọ́gù àti ẹ̀wọ̀n lọ́wọ́, tí a ó fà yín lọ síwájú àwọn ọba àti àwọn gómìnà nítorí orúkọ mi. Yóò já sí ẹ̀rí fún yín.”—Lúùkù 21:12, 13