Ẹ̀KỌ́ 78
Jésù Wàásù Nípa Ìjọba Ọlọ́run
Kò pẹ́ tí Jésù ṣe ìrìbọmi ló bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù pé: ‘Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé.’ Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń tẹ̀ lé e bó ṣe ń wàásù ní ìlú Gálílì àti Jùdíà. Nígbà tí Jésù pa dà sí ìlú Násárétì tí wọ́n bí i sí, ó lọ sínú sínágọ́gù, ó ṣí àkájọ ìwé Aísáyà, ó sì kà á sókè, ó ní: ‘Jèhófà ti fún mi ní ẹ̀mí mímọ́ kí n lè wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn.’ Àmọ́, kí ni ìyẹn túmọ̀ sí? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn fẹ́ kí Jésù máa ṣe iṣẹ́ ìyanu, ìdí tí Jèhófà fi fún un ní ẹ̀mí mímọ́ ni pé kó lè máa wàásù ìhìn rere. Ó wá sọ fún àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: ‘Lónìí, àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ.’
Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù lọ sí Òkun Gálílì, ibẹ̀ ló ti rí mẹ́rin lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, apẹja ni wọ́n. Ó wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ tẹ̀ lé mi, màá sọ yín di apẹja èèyàn.’ Orúkọ àwọn mẹ́rin náà ni Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù àti Jòhánù. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí Jésù pè wọ́n ni wọ́n fi iṣẹ́ ẹja pípa sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀ lé e. Wọ́n ń wàásù nípa Ìjọba Jèhófà ní gbogbo ìlú Gálílì. Wọ́n wàásù nínú sínágọ́gù, nínú ọjà àti lójú ọ̀nà. Àmọ́ gbogbo ibi tí wọ́n ń lọ làwọn èrò ti ń tẹ̀ lé wọn. Ibi gbogbo ni àwọn èèyàn ti gbọ́ nípa Jésù kódà wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀ ní ìlú Síríà.
Nígbà tó yá, Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn kan ní agbára láti wo àwọn èèyàn sàn kí wọ́n sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Àwọn míì sì wà pẹ̀lú rẹ̀ bó ti ń wàásù láti ìlú kan sí ìlú míì, àti láti abúlé kan sí òmíì. Àwọn obìnrin olóòótọ́ kan máa ń ran Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́. Lára wọn ni Màríà Magidalénì, Jòánà, Súsánà àti àwọn míì.
Lẹ́yìn tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dáadáa, ó rán wọn jáde láti lọ wàásù. Bí wọ́n ṣe ń wàásù ní gbogbo ìlú Gálílì, ọ̀pọ̀ ló di ọmọlẹ́yìn wọ́n sì ṣe ìrìbọmi. Àwọn tó fẹ́ di ọmọlẹ́yìn pọ̀ débi pé Jésù fi wọ́n wé àwọn èso tó ti pọ́n tó yẹ kí wọ́n ká. Ó wá sọ pé: ‘Ẹ gbàdúrà sí Jèhófà pé kó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde kí wọ́n lè kórè oko náà.’ Nígbà tó yá, ó yan àádọ́rìn [70] lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó sì rán wọn jáde ní méjì méjì kí wọ́n lè wàásù ní gbogbo àgbègbè Jùdíà. Wọ́n ń wàásù nípa Ìjọba
Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn. Nígbà tí wọ́n pa dà dé, inú wọn dùn láti sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Jésù. Ẹ ò rí i pé kò sí ohun tí Èṣù lè ṣe láti dá iṣẹ́ ìwàásù náà dúró.Jésù rí i dájú pé òun kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn òun dáadáa kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ lẹ́yìn tí òun bá pa dà sí ọ̀run. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ wàásù ìhìn rere náà kárí ayé. Ẹ máa kọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí ẹ sì máa batisí wọn.’
“Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.”—Lúùkù 4:43