Ẹ̀KỌ́ 72
Ìgbà Tí Jésù Wà Lọ́mọdé
Jósẹ́fù àti Màríà ń gbé nílùú Násárẹ́tì pẹ̀lú Jésù àtàwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn tó kù. Iṣẹ́ káfíńtà ni Jósẹ́fù ń ṣe láti fi gbọ́ bùkátà ìdílé ẹ̀, ó sì kọ́ wọn nípa Jèhófà àti Òfin ẹ̀. Ìdílé Jósẹ́fù máa ń lọ sí sínágọ́gù láti lọ jọ́sìn, wọ́n sì máa ń lọ sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọọdún láti ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá.
Nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá (12), ìdílé ẹ̀ rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù bí wọ́n ṣe máa ń ṣe. Àwọn tó wá ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá pọ̀ gan-an nínú ìlú yìí. Nígbà tí wọ́n ṣe tán, Jósẹ́fù àti Màríà bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn pa dà sílé, wọ́n rò pé Jésù wà pẹ̀lú àwọn èèyàn tó kù tí wọ́n jọ ń lọ. Àmọ́ nígbà tí wọ́n wá Jésù láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí wọn, wọn ò rí i.
Ni wọ́n bá pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Ọjọ́ mẹ́ta gbáko ni wọ́n fi wá Jésù kiri. Nígbà tó yá, wọ́n lọ sí tẹ́ńpìlì. Ibẹ̀ sì ni wọ́n ti rí Jésù, tó jókòó sáàárín àwọn olùkọ́, tó ń tẹ́tí sí wọn, tó sì ń béèrè àwọn ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání. Èyí wú àwọn olùkọ́ náà lórí débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè
ọ̀pọ̀ ìbéèrè lọ́wọ́ Jésù. Àwọn ìdáhùn tí Jésù ń fún wọn sì ń yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n rí i pé ó mọ Òfin Jèhófà dáadáa.Jósẹ́fù àti Màríà ti dààmú gan-an. Màríà sọ pé: ‘Ọmọ mi, a ti ń wá ẹ káàkiri! Ibo lo wà látọjọ́ yìí?’ Jésù sọ pé: ‘Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ilé Bàbá mi ni mo máa wà ni?’
Jésù tẹ̀ lé àwọn òbí ẹ̀ pa dà sílé wọn ní Násárẹ́tì. Jósẹ́fù kọ́ Jésù ní iṣẹ́ káfíńtà. Irú èèyàn wo lo rò pé Jésù jẹ́ nígbà tó wà lọ́mọdé? Bí Jésù ṣe ń dàgbà, ọgbọ́n ẹ̀ ń pọ̀ sí i. Ó sì ń rí ojú rere Ọlọ́run àti tàwọn èèyàn.
“Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run mi, ni inú mi dùn sí, òfin rẹ sì wà nínú mi lọ́hùn-ún.”—Sáàmù 40:8