ORÍ KEJÌDÍNLÓGÚN
Ṣé Ó Yẹ Kí N Ya Ìgbésí Ayé Mi Sí Mímọ́ fún Ọlọ́run, Kí N sì Ṣe Ìrìbọmi?
1. Lẹ́yìn tó o ti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí, kí ló yẹ kó o bi ara rẹ?
Ọ̀PỌ̀ ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì lo ti kọ́ nínú ìwé yìí, irú bí ìyè ayérayé tí Ọlọ́run ṣèlérí, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú àti ìrètí àjíǹde. (Oníwàásù 9:5; Lúùkù 23:43; Jòhánù 5:28, 29; Ìfihàn 21:3, 4) Ó ṣeé ṣe kó o ti máa lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó o sì gbà pé ìjọsìn tòótọ́ ni wọ́n ń ṣe. (Jòhánù 13:35) Ó ṣeé ṣe kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í lágbára sí i, ó sì lè jẹ́ pé o ti ń ronú pé o fẹ́ máa jọ́sìn rẹ̀. Torí náà, èyí lè mú kó o béèrè pé, ‘Ní báyìí, kí ló yẹ kí n ṣe láti máa sin Ọlọ́run?’
2. Kí nìdí tí ọkùnrin ará Etíópíà kan fi fẹ́ ṣèrìbọmi?
2 Ohun tí ọkùnrin ará Etíópíà kan tó gbé ayé ní àkókò Jésù béèrè nìyẹn. Kò pẹ́ sígbà tí Ọlọ́run jí Jésù dìde ni Fílípì ọmọ ẹ̀yìn Jésù wàásù fún ọkùnrin náà. Fílípì jẹ́ kó mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà náà. Ohun tí ọkùnrin ará Etíópíà náà kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an tó fi sọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé: “Wò ó! Omi rèé; kí ló ń dá mi dúró láti ṣèrìbọmi?”—Ìṣe 8:26-36.
3. (a) Àṣẹ wo ni Jésù pa fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? (b) Báwo ló ṣe yẹ kéèyàn ṣèrìbọmi?
3 Bíbélì ṣàlàyé tó ṣe kedere pé, tó o bá fẹ́ sin Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.” (Mátíù 28:19) Jésù náà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ torí pé òun náà ṣèrìbọmi. Ńṣe la rì í bọmi pátápátá kì í ṣe pé a kàn wọ́n omi sí i lórí. (Mátíù 3:16) Lónìí náà, tí Kristẹni kan bá fẹ́ ṣèrìbọmi, a gbọ́dọ̀ ri òun náà bọmi pátápátá.
4. Kí ni ìrìbọmi rẹ ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀?
4 Nígbà tó o bá ṣèrìbọmi, ńṣe lò ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o fẹ́ di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run lóòótọ́ àti pé o fẹ́ máa jọ́sìn rẹ̀. (Sáàmù 40:7, 8) Torí náà, o lè máa rò pé, ‘Kí ló yẹ kí n ṣe láti ṣèrìbọmi?’
ÌMỌ̀ ÀTI ÌGBÀGBỌ́
5. (a) Kí ló yẹ kó o kọ́kọ́ ṣe kó o tó lè ṣèrìbọmi? (b) Kí nìdí táwọn ìpàdé Kristẹni fi ṣe pàtàkì?
5 Kó o tó lè ṣèrìbọmi, o gbọ́dọ̀ wá mọ Jèhófà àti Jòhánù 17:3.) Àmọ́ ìyẹn nìkan kò tó. Bíbélì sọ pé, o gbọ́dọ̀ “ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀ tó péye” nípa ìfẹ́ Jèhófà. (Kólósè 1:9) Àwọn ìpàdé tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Ìdí pàtàkì kan nìyẹn tó fi yẹ kó o máa lọ sí àwọn ìpàdé yẹn déédéé.—Hébérù 10:24, 25.
Jésù. O ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bẹ́ẹ̀ bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Ka6. Báwo lohun tó o mọ̀ nínú Bíbélì ṣe yẹ kó pọ̀ tó kó o tó lè ṣèrìbọmi?
6 Ká sòótọ́, Jèhófà ò retí pé kó o mọ gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì kó o tó ṣèrìbọmi. Kò retí pé kí ọkùnrin ará Etíópíà yẹn mọ gbogbo nǹkan kó tó ṣèrìbọmi. (Ìṣe 8:30, 31) Torí pé títí láé la ó máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. (Oníwàásù 3:11) Àmọ́ kó o tó lè ṣèrìbọmi, ó kéré tán, ó yẹ kó o mọ àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ Bíbélì kó o sì gbà wọ́n gbọ́.—Hébérù 5:12.
7. Báwo ni ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o kọ́ ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́?
7 Bíbélì sọ pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run” (Hébérù 11:6) Torí náà, ó yẹ kó o ní ìgbàgbọ́ kó o tó lè ṣèrìbọmi. Bíbélì sọ fún wa pé, nígbà tí àwọn kan ní ìlú Kọ́ríńtì àtijọ́ gbọ́ ohun tí àwọn ọmọlẹ́yìn ń kọ́ àwọn èèyàn, wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí í gbà gbọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi.” (Ìṣe 18:8) Lọ́nà kan náà, ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o kọ́ ti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run, ó sì tún jẹ́ kó o gbà pé ìrúbọ tí Jésù fi ara rẹ̀ ṣe lágbára láti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Jóṣúà 23:14; Ìṣe 4:12; 2 Tímótì 3:16, 17.
SỌ ÒTÍTỌ́ BÍBÉLÌ FÚN ÀWỌN ÈÈYÀN
8. Kí ló máa mú kó o sọ àwọn ohun tó o ti kọ́ fún àwọn èèyàn?
8 Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nínú Bíbélì tó o sì ń rí bó ṣe Jeremáyà 20:9; 2 Kọ́ríńtì 4:13) Àmọ́, àwọn wo ló yẹ kó o sọ fún?
ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ, ìgbàgbọ́ rẹ á máa lágbára sí i. Wàá sì fẹ́ máa sọ àwọn ohun tó ò ń kọ́ fún àwọn èèyàn. (9, 10. (a) Àwọn wo lo lè máa sọ àwọn ohun tó o ti kọ́ fún? (b) Kí lo yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ máa wàásù pẹ̀lú ìjọ?
9 O lè sọ àwọn ohun tó ò ń kọ́ fún ìdílé rẹ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, àwọn aládùúgbò rẹ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ́ ń ṣiṣẹ́. Ìyẹn dáa, àmọ́ máa ṣe é pẹ̀lú inú rere àti ìfẹ́ nígbà gbogbo. Tó bá yá, wàá bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù pẹ̀lú ìjọ. Tó o bá ti ṣe tán láti ṣe bẹ́ẹ̀, o lè bá Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ̀rọ̀, kó o sì sọ fún un pé wàá fẹ́ láti máa wàásù pẹ̀lú ìjọ. Tí ẹni yẹn bá rí i pé o ti múra tán, tó o sì tí ń gbé ìgbé ayé tó bá ìlànà Bíbélì mu, ẹ̀yin méjèèjì a wá lọ bá alàgbà méjì nínú ìjọ yín sọ̀rọ̀.
10 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ níbi ìpàdé náà? Àwọn alàgbà náà máa bá ẹ sọ̀rọ̀ láti mọ̀ bóyá o lóye àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ Bíbélì àti bóyá o gbà wọ́n gbọ́, wọ́n á tún mọ̀ bóyá ò ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì nígbèésí ayé rẹ àti bóyá o fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóòótọ́. Rántí pé àwọn alàgbà ló ń bójú tó gbogbo ará ìjọ, títí kan ìwọ náà, torí náà, má ṣe bẹ̀rù láti bá wọn sọ̀rọ̀. (Ìṣe 20:28; 1 Pétérù 5:2, 3) Lẹ́yìn ìjíròrò yẹn, àwọn alàgbà náà á jẹ́ kó o mọ̀ bóyá o lè bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù pẹ̀lú ìjọ.
11. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti ṣe àwọn àtúnṣe kan, kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù pẹ̀lú ìjọ?
11 Àwọn alàgbà náà lè ṣàlàyé fún ẹ pé, o ṣì ní láti ṣe àwọn àtúnṣe kan kó o to lè bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù pẹ̀lú ìjọ. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti ṣe àwọn àtúnṣe yẹn? Ìdí ni pé bá a ṣe ń wàásù fún àwọn èèyàn, Jèhófà 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Gálátíà 5:19-21.
là ń ṣojú fún, a sì gbọ́dọ̀ máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bọlá fún un.—RONÚ PÌWÀ DÀ KÓ O SÌ YÍ PA DÀ
12. Kí nìdí tó fi yẹ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà?
12 Ó tún ku ohun kan tó o gbọ́dọ̀ ṣe kó o tó lè ṣe ìrìbọmi. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí pa dà, kí Ọlọ́run lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́.” (Ìṣe 3:19) Kí ló túmọ̀ sí láti ronú pìwà dà? Ó túmọ̀ sí pé kí inú èèyàn bà jẹ́ torí ohun tó ṣe tí kò dáa. Bí àpẹẹrẹ, tó o ba jẹ́ oníṣekúṣe, ó ní láti ronú pìwà dà. Tó o bá tiẹ gbà pé gbogbo ìgbésí ayé rẹ lo fi ń ṣe ohun tó tọ́, o ṣì ní láti ronú pìwà dà, torí pé gbogbo wa ni a máa ń ṣẹ̀, tó sì yẹ ká máa tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Ọlọ́run.—Róòmù 3:23; 5:12.
13. Kí ló túmọ̀ sí pé kí èèyàn “yí pa dà”?
13 Ṣé kí inú rẹ kàn bà jẹ́ lórí ohun tó o ṣe ti tó? Rárá o. Pétérù sọ pé, ó tún yẹ kó o “yí pa dà.” Èyí túmọ̀ sí pé, kó o kọ ìwà tí kò dáa tó o tí ń hù tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó tọ́. Wo àpèjúwe yìí ná, ká sọ pé ìgbà àkọ́kọ́ rèé tó ò ń rìnrìn àjò lọ síbì kan. Nígbà tó yá, o wá rí i pé, ọ̀nà yẹn kọ́ ló yẹ kó o gbà. Kí ni wàá ṣe? Ó dájú pé wàá dẹ ìrìn rẹ, wàá dúró, wàá sí yí pa dà, lẹ́yìn náa wàá kọ́rí sójú ọ̀nà tó yẹ kó o gbà. Bákan náà ló ṣe rí tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o lè wá rí i pé àwọn ìwà kan tàbí ohun kan wà nínú ìgbésí ayé rẹ tó yẹ kó o yí pa dà. Múra tán láti “yí pa dà,” ìyẹn ni pé kó o ṣe àwọn àtúnṣe tó pọn dandan, kó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó tọ́.
YA ARA RẸ SÍ MÍMỌ́
14. Kí ni ohun tó o máa ṣe láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run?
14 Ohun pàtàkì míì tó yẹ kó o ṣe kó o tó ṣèrìbọmi ni pé, kó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Bó ṣe máa ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà ni pé, wàá gbàdúrà sí Jèhófà láti ṣèlérí fún un pé òun nìkan ṣoṣo ni wàá máa jọ́sìn àti pé ìfẹ́ rẹ̀ ló máa jẹ́ ohun pàtàkì jù lọ́ ní ìgbésí ayé rẹ.—Diutarónómì 6:15.
15, 16. Kí ló máa mú kí ẹnì kan ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run?
15 Ìlérí tó o ṣe pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ni wàá máa jọ́sìn dà bí ìlérí tó o ṣe fún ẹnì tó o nífẹ̀ẹ́ pé wàá lo gbogbo ìgbésí ayé rẹ tó kù pẹ̀lú rẹ̀. Wo ọkùnrin àti obìnrin kan tí wọ́n ń fẹ́ra wọn sọ́nà. Bí ọkùnrin náà ṣe ń mọ obìnrin náa sí i láá máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí i, á sì fẹ́ fi ṣe ìyàwó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìpinnu yẹn gba kéèyàn ronú jinlẹ̀, síbẹ̀ ọkùnrin náà ṣe tán láti fẹ́ obìnrin náà, torí pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an.
16 Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, wàá máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí i, wàá sì fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa sìn ín. Èyí á mú kó o ṣèlérí fún un nínú àdúrà pé o fẹ́ sìn ín. Bíbélì sọ pé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ tẹ̀ lé Jésù gbọ́dọ̀ “sẹ́ ara rẹ̀.” (Máàkù 8:34) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé ṣíṣe ìgbọràn sí Jèhófà ni ohun àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ. Ohun tí Jèhófà fẹ́ ló ṣe pàtàkì ju ìfẹ́ ọkàn rẹ àtàwọn àfojúsùn rẹ lọ.—Ka 1 Pétérù 4:2.
MÁ BẸ̀RÙ PÉ O LÈ ṢÀṢÌṢE
17. Kí nìdí tí àwọn kan ò fi ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà?
17 Àwọn kan ò ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, torí wọ́n ń bẹ̀rù pé àwọn ò ní lè mú ìlérí àwọn ṣẹ pé
àwọn á máa sìn ín. Wọn ò fẹ́ já Jèhófà kulẹ̀, tàbí kí wọ́n máa ronú pé táwọn ò bá ṣáà ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún un, Jèhófà ò ní dá àwọn lẹ́jọ́ ohunkohun táwọn bá ṣe.18. Kí ló máa jẹ́ kó o borí ìbẹ̀rù tó o ní pé wàá já Jèhófà kulẹ̀?
18 Ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù tó o ní pé wàá já a kulẹ̀. Torí pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wàá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti mú ìlérí rẹ ṣẹ. (Oníwàásù 5:4; Kólósè 1:10) O ò ní máa rò pé ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà ti nira jù. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pe: “Torí ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí nìyí, pé ká pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kò nira.”—1 Jòhánù 5:3.
19. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o bẹ̀rù láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà?
19 Kò dìgbà tó o bá jẹ́ ẹni pípé kó o tó lè ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Kò fìgbà kan retí pé ká ṣe ju ohun tí agbára wa gbé lọ. (Sáàmù 103:14) Ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́. (Àìsáyà 41:10) Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, “á sì mú kí àwọn ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6.
ÌKÉDE NÍ GBANGBA LÁTI RÍ ÌGBÀLÀ
20. Lẹ́yìn tó o bá ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, kí lohun tó kàn?
20 Ṣé o rò pé o ti múra tán láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà? Lẹ́yìn tó o bá ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, o ti múra tán láti ṣe ohun tó kàn. Ó yẹ kó o ṣe ìrìbọmi.
21, 22. Báwo lo ṣe máa “kéde” ìgbàgbọ́ rẹ “ní gbangba”?
21 Jẹ́ kí olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ rẹ mọ̀ pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà àti pé o fẹ́ ṣèrìbọmi. Ó máa wá ṣètò bí àwọn alàgbà kan ṣe máa ṣe àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ agbègbè àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a máa ṣe tẹ̀ lé e. Ní àpéjọ yẹn, àsọyé kan máa wáyé tó máa ṣàlàyé ohun tí ìrìbọmi jẹ́. Lẹ́yìn náà, olùbánisọ̀rọ̀ tó sọ àsọyé náà máa béèrè ìbéèrè méjì tó rọrùn lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi. Tó o bá dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn, o fi hàn pé o ti “kéde” ìgbàgbọ́ rẹ “ní gbangba.”—Róòmù 10:10.
àtúnyẹ̀wò àwọn àkọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ. Tí wọ́n bá rí i pé o ti kúnjú ìwọ̀n, wọ́n á sọ fún ẹ pé o lè ṣèrìbọmi ní22 Lẹ́yìn náà, wàá ṣe ìrìbọmi. A máa rì ẹ́ bọmi pátápátá. Ìrìbọmi rẹ máa jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé o
ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà àti pé ní báyìí, o ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.OHUN TÍ ÌRÌBỌMI RẸ TÚMỌ̀ SÍ
23. Kí ló túmọ̀ sí láti ṣe ìrìbọmi “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́”?
23 Jésù sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun á ṣèrìbọmi “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.” (Ka Mátíù 28:19.) Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé o gbà pé Jèhófà ni aláṣẹ àti pé o mọ ipa tí Jésù ń kó láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ, o sì tún mọ bí Ọlọ́run ṣe ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.—Sáàmù 83:18; Mátíù 28:18; Gálátíà 5:22, 23; 2 Pétérù 1:21.
24, 25. (a) Kí ni ìrìbọmi ń ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí la máa jíròrò nínú orí tó kẹ́yìn?
24 Ìrìbọmi ń ṣàpẹẹrẹ ohun pàtàkì kan. Nígbà tí a bá rì ẹ́ bọmi, ó túmọ̀ sí pé o ti di òkú ní ti ìgbésí ayé tó ò ń gbé tẹ́lẹ̀ tàbí o ti fi í sílẹ̀. Nígbà tó o bá sì jáde nínú omi, ó túmọ̀ sí pé o ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó fi hàn pé wàá máa sin Jèhófà lati ìgbà yẹn lọ. Rántí pé kì í ṣe èèyàn, ẹgbẹ́ kan tàbí iṣẹ́ kan lo ya ara rẹ sí mímọ́ fún. Jèhófà lo ya ìgbésí ayé rẹ sí mímọ́ fún.
25 Ìyàsímímọ́ rẹ á jẹ́ kó o ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. (Sáàmù 25:14) Èyí kò túmọ̀ sí pé èèyàn máa rí ìgbàlà kìkì nítorí pé ó ti ṣèrìbọmi. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.” (Fílípì 2:12) Ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni ìrìbọmi jẹ́. Àmọ́, báwo lo ṣe máa dúró sọ́dọ̀ Jèhófà? Orí tó kẹ́yìn nínú ìwé yìí máa dáhùn ìbéèrè yẹn.