Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Mọ Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì?
Ṣó o mọ ìwé tó ń jẹ́ Bíbélì? Òun ni ìwé tí kò tíì sírú ẹ̀ rí tí ìpínkiri ẹ̀ tíì pọ̀ jù lọ látọjọ́ táláyé ti dáyé. Àwọn èèyàn tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn yàtọ̀ síra ti rí i pé ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹ̀ máa ń tuni nínú, ó máa ń fini lọ́kàn balẹ̀, àti pé ìmọ̀ràn tó wà nínú ẹ̀ ṣeé wá ojútùú sáwọn ipò téèyàn ń bá pàdé lójoojúmọ́. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Bíbélì lóde òní. Yálà ọ̀ràn ẹ̀sìn jẹ ẹ́ lógún tàbí kò jẹ ẹ́ lógún, ó ṣeé ṣe kó ti máa wu ìwọ náà láti mọ ohun tó wà nínú Bíbélì. A ṣe ìwé pẹlẹbẹ yìí kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti wo Bíbélì gààràgà, kó o lè mọ ohun tó wà nínú ẹ̀.
KÓ O tó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, ó máa dáa kó o mọ díẹ̀ lára ohun tó wà nínú ẹ̀. Bíbélì náà la tún ń pè ní Ìwé Mímọ́, apá tó pín sí tàbí iye ìwé tó wà nínú ẹ̀ jẹ́ mẹ́rìndínláàádọ́rin [66], èyí tó bẹ̀rẹ̀ látorí Jẹ́nẹ́sísì tó sì parí sí ìwé Ìṣípayá, tàbí Àpókálíìsì.
Ta ló ni Bíbélì? Ìbéèrè tó fani mọ́ra lèyí. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ogójì [40] èèyàn ni Ọlọ́run lò láti kọ ọ́, ó sì gbà wọ́n tó nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún. Síbẹ̀, àwọn èèyàn wọ̀nyẹn ò sọ pé àwọn làwọ́n ni Bíbélì. Ọ̀kan lára wọn tiẹ̀ sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Òmíràn lára wọn sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ni ó sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ mi, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì wà lórí ahọ́n mi.” (2 Sámúẹ́lì 23:2) Nípa báyìí, wọ́n fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni Gíga Jù Lọ tó ń ṣàkóso ayé àtọ̀run, ló ni Bíbélì. Wọ́n sì tún jẹ́ kó ṣe kedere pé Ọlọ́run fẹ́ káwa ẹ̀dá mọ òun.
Ohun pàtàkì míì wà tó tún yẹ ká mọ̀ bá a bá fẹ́ lóye Bíbélì. Ìyẹn ni pé ẹṣin ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ni Ìwé Mímọ́ ní látòkèdélẹ̀, ìyẹn ni, ìdáláre ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run ní láti ṣàkóso aráyé nípasẹ̀ Ìjọba tó gbé kalẹ̀ lókè ọ̀run. Ní àwọn ojú ewé tó tẹ̀ lé èyí, wàá rí bí ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí ṣe fara hàn nínú Bíbélì láti Jẹ́nẹ́sísì dé Ìṣípayá.
Pẹ̀lú gbogbo èyí lọ́kàn ẹ, o lè wá ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì, ìwé tó gbajúmọ̀ jù lọ.
^ ìpínrọ̀ 9 Onírúurú ọ̀nà lèèyàn lè gbà sọ̀rọ̀ nípa déètì tàbí àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀. Nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí, S.K. dúró fún “Sànmánì Kristẹni,” Ṣ.S.K sì dúró fún “Ṣáájú Sànmánì Kristẹni.” Ẹ máa ríbi tá a kọ wọ́n sí nísàlẹ̀ àwọn ojú ewé ìwé yìí.