Apá 25
Ìmọ̀ràn Lórí Ìgbàgbọ́, Ìwà àti Ìfẹ́
Jákọ́bù, Pétérù, Jòhánù àti Júúdà kọ àwọn lẹ́tà láti fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ níṣìírí
IYÈKAN Jésù ni Jákọ́bù àti Júúdà. Pétérù àti Jòhánù wà lára àwọn àpọ́sítélì Jésù méjìlá. Lẹ́tà méje làwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin kọ, wọ́n sì wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Orúkọ wọn ni wọ́n fi sọ lẹ́tà tí wọ́n kọ. Àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Ọlọ́run mí sí, èyí tó wà nínú àwọn lẹ́tà wọ̀nyí, wà fún ríran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti máa pa ìwà títọ́ wọn sí Jèhófà mọ́ kí ìrètí Ìjọba Ọlọ́run sì máa wà lọ́kàn wọn digbí.
Fi ìgbàgbọ́ hàn. Fífi ẹnu lásán sọ pé èèyàn ní ìgbàgbọ́ kò tó. Ìgbàgbọ́ tòótọ́ máa ń mú iṣẹ́ dání. Jákọ́bù tiẹ̀ kọ̀wé pé: “Ní tòótọ́ . . . ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.” (Jákọ́bù 2:26) Bá a bá ń lo ìgbàgbọ́ nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro, ó máa jẹ́ ká ní ìfaradà. Kí Kristẹni kan tó lè ṣàṣeyọrí, ó gbọ́dọ̀ máa béèrè fún ọgbọ́n Ọlọ́run, kó sì ní ìdánilójú pé òun máa rí ọgbọ́n náà gbà. Ìfaradà máa ń mú kéèyàn rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run. (Jákọ́bù 1:2-6, 12) Bí ìgbàgbọ́ tí ẹni tó ń sin Ọlọ́run ní bá ń mú kó pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́, Jèhófà á máa gbọ́ tiẹ̀. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.
Ìgbàgbọ́ tí Kristẹni kan ní gbọ́dọ̀ lágbára tó láti ràn án lọ́wọ́ kó bàa lè dènà ìdẹwò àtàwọn ohun tó lè mú kó lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe. Nígbà tí Júúdà rí i pé ipò tó yí àwọn èèyàn ká ń mú kí ìwà ìṣekúṣe gbilẹ̀, ó di dandan fún un láti kọ̀wé pé káwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ “máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́.”—Júúdà 3.
Máa hùwà mímọ́. Jèhófà fẹ́ kí gbogbo àwọn tó ń sin Òun jẹ́ mímọ́, ìyẹn ni pé kí wọ́n wà ní mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà. Pétérù kọ̀wé pé: “Kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín, nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi [Jèhófà] jẹ́ mímọ́.’” (1 Pétérù 1:15, 16) Àwọn Kristẹni lẹ́ni tó yẹ kí wọ́n máa wò bí àwòkọ́ṣe. Pétérù sọ pé: “Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni lè máa jìyà nítorí pé wọ́n ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run, wọ́n ní “ẹ̀rí-ọkàn rere.” (1 Pétérù 3:16, 17) Pétérù rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa pọ̀ sí i nínú ìwà mímọ́ àti àwọn ìṣe tó ń fi ìfọkànsìn Ọlọ́run hàn bí wọ́n ṣe ń dúró de ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run àti ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, nínú èyí tí “òdodo yóò . . . máa gbé.”—2 Pétérù 3:11-13.
“Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” —Jákọ́bù 4:8
Máa fi ìfẹ́ hàn. Jòhánù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Àpọ́sítélì náà ṣàlàyé pé Ọlọ́run fi ìfẹ́ ńlá tó ní sí wa hàn nípa rírán Jésù wá gẹ́gẹ́ bí “ẹbọ . . . fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” Kí ló wá yẹ káwa Kristẹni ṣe? Jòhánù ṣàlàyé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, nígbà náà àwa fúnra wa wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Jòhánù 4:8-11) Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn ni pé ká jẹ́ ọ̀làwọ́ sáwọn Kristẹni bíi tiwa.—3 Jòhánù 5-8.
Àmọ́, báwo làwọn olùjọsìn Jèhófà ṣe lè fi ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Ọlọ́run hàn? Jòhánù dáhùn pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3; 2 Jòhánù 6) Nípa báyìí, a mú kó dá àwọn tó bá ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run lójú pé Ọlọ́run á máa bá a nìṣó láti nífẹ̀ẹ́ wọn “pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.”—Júúdà 21.