Apá 12
Ọgbọ́n Ọlọ́run Tó Ń Mú Ká Wà Láàyè
Ìwé Òwe jẹ́ àkójọ àwọn ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí, èyí tó máa ń pèsè ìtọ́sọ́nà téèyàn nílò láti máa gbé ìgbé ayé ojoojúmọ́. Sólómọ́nì ló kọ èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn
ṢÉ OLÙṢÀKÓSO tó gbọ́n ni Jèhófà? Ọ̀nà tó ṣe tààràtà jù lọ tá a lè gbà dáhùn ìbéèrè yẹn ni pé ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìmọ̀ràn tó máa ń fúnni. Ṣé àwọn ìmọ̀ràn náà máa ń ranni lọ́wọ́? Ṣé bá a bá fàwọn ìmọ̀ràn náà sílò, ó máa mú kí ìgbé ayé wá dára sí i kó sì túbọ̀ nítumọ̀? Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì kọ ọgọ́rọ̀ọ̀rún òwe. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun téèyàn ń gbélé ayé ṣe táwọn òwe náà ò sọ̀rọ̀ bá. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
Bá a ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Ìgbẹ́kẹ̀lé ṣe kókó béèyàn bá máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Bá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nípa wíwá ìtọ́sọ́nà rẹ̀ tá a sì ń ṣègbọràn sí i, ó máa mú kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀ gan-an. Irú ìgbé ayé bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ ká múnú Ọlọ́run dùn, ìyẹn á sì mú kí Jèhófà lè pèsè ìdáhùn sáwọn ìpèníjà Sátánì, tó jẹ́ alátakò Rẹ̀.—Òwe 27:11.
Bá a ṣe lè máa fọgbọ́n báni lò. Ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run fún àwọn ọkọ, àwọn aya, àtàwọn ọmọ bọ́ sí i gẹ́lẹ́ lákòókò yìí ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Nígbà tí Ọlọ́run ń fáwọn ọkọ ní ìtọ́sọ́nà pé kí wọ́n má ṣe dalẹ̀ àwọn aya wọn, ó gbà wọ́n níyànjú pé: “Máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ.” (Òwe 5:18-20) Nínú ìwé Òwe, àwọn obìnrin tó ti lọ́kọ lè rí àpèjúwe tó jíire nípa obìnrin tó dáńgájíá, ẹni tí ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ ń kan sáárá sí. (Òwe, orí 31) Ìtọ́ni sì tún wà níbẹ̀ fáwọn ọmọ pé kí wọ́n máa ṣègbọràn sáwọn òbí wọn. (Òwe 6:20) Ìwé Òwe tún fi hàn pé ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ dára, torí pé ẹni tó bá ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ á máa lépa ìmọtara-ẹni-nìkan. (Òwe 18:1) Àwọn ọ̀rẹ́ lè nípa rere tàbí ipa búburú lórí wa, torí náà ó yẹ ká fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ wa.—Òwe 13:20; 17:17.
Bá a ṣe lè máa fọgbọ́n gbé ìgbé ayé wa. Ìwé Òwe ní ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn ṣíṣeyebíye tó dá lórí yíyẹra fún ọtí àmujù, béèyàn ṣe lè máa ní èrò rere, béèyàn ṣe lè máa mú èrò búburú kúrò lọ́kàn àti béèyàn ṣe lè jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn. (Òwe 6:6; 14:30; 20:1) Ó kìlọ̀ pé ká má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé èrò èèyàn tí kò bá ti Ọlọ́run dọ́gba torí pé ó máa ń yọrí sí ìjábá. (Òwe 14:12) Ó rọ̀ wá pé ká pa ọkàn-àyà wa, ìyẹn ẹni tá a jẹ́ ní inú, mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ohun tó lè sọ ọ́ dìbàjẹ́, ó sì rán wa létí pé “láti inú [ọkàn-àyà] ni àwọn orísun ìyè ti wá.”—Òwe 4:23.
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kárí ayé ti rí i pé béèyàn bá ń tẹ̀ lé irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ó máa mú kí ìgbésí ayé ẹni sunwọ̀n. Nítorí èyí, wọ́n ní ìdí tó pọ̀ láti tẹ́wọ́ gba Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olùṣàkóso wọn.