ORÍ KẸFÀ
Ibo Làwọn Òkú Wà?
-
Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tá a bá kú?
-
Kí ló dé tá a fi ń kú?
-
Ǹjẹ́ ó máa tu èèyàn nínú téèyàn bá mọ òtítọ́ nípa ipò táwọn òkú wà?
1-3. Àwọn ìbéèrè wo làwọn èèyàn ń béèrè nípa ikú, kí sì ni ìdáhùn tí onírúurú ẹ̀sìn ń pèsè?
ÌWỌ̀NYÍ làwọn ìbéèrè táwọn èèyàn ti ń ronú nípa rẹ̀ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Àwọn ìbéèrè ọ̀hún sì ṣe pàtàkì. Irú ẹni tó wù ká jẹ́ tàbí ibi tó wù ka máa gbé, gbogbo wa pátá làwọn ìbéèrè náà kàn.
2 Ní Orí Karùn-ún, a jíròrò bí ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ṣe mú kí ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe. A tún kẹ́kọ̀ọ́ pé Bíbélì sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí “ikú [kò ní] sí mọ́.” (Ìṣípayá 21:4) Àmọ́ ní báyìí, gbogbo wa là ń kú. Ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì sọ pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú.” (Oníwàásù 9:5) A máa ń sa gbogbo ipá wa pé kí ẹ̀mí wa lè gùn. Síbẹ̀, a tún máa ń ronú nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá kú.
3 Inú wa máa ń bà jẹ́ gidigidi táwọn èèyàn wa bá kú. A tiẹ̀ máa ń béèrè pé: ‘Kí ló dé tí wọ́n fi ní láti kú? Ṣé wọ́n ń jìyà níbi tí wọ́n wà? Ṣé wọ́n ń rí wa? Ǹjẹ́ a lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Ǹjẹ́ a óò tún padà rí wọn?’ Onírúurú ìdáhùn làwọn ẹ̀sìn ayé yìí ń fún àwọn tó ń béèrè ìbéèrè wọ̀nyí. Àwọn ẹ̀sìn kan ń kọ́ni pé téèyàn bá hùwà rere, ọ̀run lèèyàn ń lọ tó bá kú; ṣùgbọ́n téèyàn bá hùwà burúkú, inú iná lonítọ̀hún á ti lọ máa joró tó bá kú. Àwọn ẹ̀sìn kan tún ń kọ́ni pé téèyàn bá kú, yóò lọ sí ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí láti
máa gbé pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ tó ti kú. Ní tàwọn ẹ̀sìn mìíràn ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni ni pé téèyàn bá kú, á lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ìyẹn ibi tí wọ́n gbà pé àwọn tó ti kú lọ. Wọn sọ pé yóò gba ìdájọ́ níbẹ̀, lẹ́yìn náà, yóò tún ayé wá nínú ara mìíràn.4. Èrò wo ni ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ní nípa ikú?
4 Gbogbo irú àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn wọ̀nyí ló ní èrò kan, èrò náà sì ni pé ohun kan wà nínú àwa èèyàn tí kì í kú, pé ara lásán tá à ń fojú rí yìí ló máa ń kú. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè jẹ́ pé gbogbo ẹ̀sìn táwọn èèyàn ṣe láyé àtijọ́ àtèyí tí wọ́n ń ṣe lóde ìwòyí ló fi ń kọ́ni pé, téèyàn bá kú, yóò ṣì máa wà láàyè lọ bákan ṣá, yóò sì ní agbára láti máa ríran, láti máa gbọ́ràn àti agbára láti máa ronú. Ṣùgbọ́n báwo ló ṣe lè rí bẹ́ẹ̀? Ṣebí ọpọlọ ló ń darí agbára ìríran, agbára ìgbọ́ràn àti bá a ṣe ń ronú. Téèyàn bá sì kú, ọpọlọ ò ní ṣiṣẹ́ mọ́. Agbára ìrántí wa, ìmọ̀lára wa, agbára ìríran wa, àti agbára ìgbọ́ràn wa kì í báṣẹ́ lọ láwọn nìkan lọ́nà àdììtú. Wọn kì í ṣiṣẹ́ mọ́ tí ọpọlọ wa bá ti kú.
KÍ LÓ Ń ṢẸLẸ̀ GÁN-AN TÉÈYÀN BÁ KÚ?
5, 6. Kí ni Bíbélì fi kọ́ni nípa ipò táwọn òkú wà?
5 Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ téèyàn bá kú kì í ṣe àdììtú sí Jèhófà, ẹni tó ṣẹ̀dá ọpọlọ. Ó mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa ikú, ó sì ṣàlàyé ipò táwọn òkú wà nínú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ṣe kedere, pé: Téèyàn bá ti kú, ó ti di aláìsí nìyẹn. Ikú ni òdìkejì ìwàláàyè. Àwọn òkú ò lè ríran, wọn ò lè gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò lè ronú. Kódà, kò sí ohun kan nínú ara wa tó tún máa ń wà láàyè nìṣó téèyàn bá ti kú. A ò ní ọkàn tàbí ẹ̀mí tí kì í kú. *
6 Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì sọ pé àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú, ó kọ̀wé pé: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” Ó tún wá ṣàlàyé síwájú sí i nípa òtítọ́ yẹn nígbà tó Oníwàásù 9:5, 6, 10) Lọ́nà kan náà, Sáàmù 146:4 sọ pé nígbà téèyàn bá kú, “àwọn ìrònú rẹ̀ [á] ṣègbé.” Ẹni kíkú ni wá, kò sí ohun kankan nínú ara wa tó máa ń wà láàyè nìṣó téèyàn bá ti kú. Bí iná àbẹ́là ni ẹ̀mí wa ṣe rí. Bí wọ́n bá fẹ́ iná àbẹ́là kan pa, èèyàn ò lè rí iná tí wọ́n fẹ́ pa yẹn gan-an níbòmíràn. Ó ti kú, kò sí níbì kankan mọ́.
sọ pé àwọn òkú ò lè nífẹ̀ẹ́, wọn ò lè kórìíra, bẹ́ẹ̀ sì ni “kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n [nínú sàréè].” (KaOHUN TÍ JÉSÙ SỌ NÍPA IKÚ
7. Báwo ni Jésù ṣe ṣàlàyé ohun tí ikú jọ?
7 Jésù Kristi sọ̀rọ̀ nípa ipò táwọn òkú wà. Ó sọ bẹ́ẹ̀ nígbà kan tí Lásárù tó jẹ́ ẹnì kan tó mọ̀ dáadáa kú. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi.” Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rò pé ohun tó ní lọ́kàn ni pé Lásárù ń rẹjú, pé ó ń sùn kí ara rẹ̀ lè yá. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ò rí bí wọ́n ṣe rò ó yìí, ni Jésù bá kúkú là á mọ́lẹ̀ pé: “Lásárù ti kú.” (Ka Jòhánù 11:11-14) Kíyè sí i pé Jésù fi ikú wé ìsinmi àti oorun. Ọ̀run kọ́ ni Lásárù lọ o, bẹ́ẹ̀ sì ni kò lọ sínú hẹ́ẹ̀lì tí wọ́n sọ pé iná ti ń jó. Kò lọ pàdé àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn baba ńlá. Wọn ò tún Lásárù bí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tuntun. Ńṣe ló ń sinmi nínú ikú, bíi kéèyàn sun oorun àsùnwọra kó má sì lá àlá. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn pẹ̀lú fi ikú wé oorun. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n sọ Sítéfánù ọmọ ẹ̀yìn lókùúta pa, Bíbélì sọ pé ó “sùn nínú ikú.” (Ìṣe 7:60) Nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, òun pẹ̀lú sọ nípa àwọn kan tí wọ́n ti “sùn nínú ikú.”—1 Kọ́ríńtì 15:6.
8. Báwo la ṣe mọ̀ pé kì í ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kéèyàn máa kú?
8 Nígbà tí Ọlọ́run dá èèyàn, ṣé ìfẹ́ rẹ̀ ni pé kéèyàn máa Oníwàásù 3:11) Nígbà tí Ọlọ́run dá wa, ó fi ìfẹ́ láti wà láàyè títí láé sínú wa. Ó sì ti ṣètò bá a ṣe máa rí ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí yìí gbà.
kú? Rárá o! Jèhófà dá èèyàn pé kó máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé ni. A ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ kọjá nínú ìwé yìí pé, inú Párádísè aláyọ̀ ni Ọlọ́run fi tọkọtaya ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ sí. Ó fi ìlera pípé jíǹkí wọn. Ohun tó dára nìkan ni Jèhófà fẹ́ fún wọn. Ǹjẹ́ òbí kan tó nífẹ̀ẹ́ máa fẹ́ kọ́mọ rẹ̀ jìyà ìrora ọjọ́ ogbó kó sì kú? Ó dájú pé kò ní fẹ́ bẹ́ẹ̀! Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ó sì fẹ́ kí wọ́n ní ayọ̀ tí ò lópin lórí ilẹ̀ ayé. Ohun tí Bíbélì sọ nípa ọmọ èèyàn ni pé: “Àkókò tí ó lọ kánrin ni [Jèhófà] ti fi sínú ọkàn-àyà wọn.” (ÌDÍ TÉÈYÀN FI Ń KÚ
9. Kí ni Ọlọ́run kà léèwọ̀ fún Ádámù, kí sì nìdí tí òfin yẹn ò fi ṣòroó pa mọ́?
9 Kí wá ló dé téèyàn fi ń kú? Ká tó lè rí ìdáhùn, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọkùnrin kan àtobìnrin kan péré wà lórí ilẹ̀ ayé. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Jèhófà Ọlọ́run mú kí olúkúlùkù igi tí ó fani mọ́ra ní wíwò, tí ó sì dára fún oúnjẹ hù láti inú ilẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:9) Ṣùgbọ́n, ìkàléèwọ̀ kan wà o. Jèhófà sọ fún Ádámù pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Òfin yìí ò ṣòroó pa mọ́. Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ igi mìíràn wà nínú ọgbà náà tí Ádámù àti Éfà lè jẹ èso wọn. Ńṣe ni òfin yẹn fún wọn láǹfààní láti fi hàn pé wọ́n mọrírì gbogbo ohun tí Ọlọ́run fún wọn, títí kan ìwàláàyè pípé. Ṣíṣe tí wọ́n bá ṣègbọràn sí òfin yẹn yóò fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún àṣẹ Bàbá wọn ọ̀run, wọ́n sì fẹ́ kó máa darí àwọn.
10, 11. (a) Báwo ni tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ ṣe ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run? (b) Kì nìdí tí àìgbọràn Ádámù àti Éfà kì í fi ṣe ọ̀ràn kékeré?
10 Ó bani nínú jẹ́ pé tọkọtaya ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ pinnu láti ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Sátánì gba ẹnu ejò kan sọ̀rọ̀, ó sì bi Éfà pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?” Éfà dáhùn pé: “Àwa lè jẹ nínú àwọn èso igi ọgbà. Ṣùgbọ́n ní ti jíjẹ èso igi tí ó wà ní àárín ọgbà, Ọlọ́run ti sọ pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, rárá, ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án, kí ẹ má bàa kú.’”—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-3.
11 Sátánì sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. . . . Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti Jẹ́nẹ́sísì 3:4, 5) Sátánì fẹ́ kí Éfà gbà gbọ́ pé yóò rí àǹfààní nínú jíjẹ tó bá jẹ èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ náà. Ó sọ pé yóò lè máa pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fúnra rẹ̀; yóò lè máa ṣe ohun tó bá fẹ́. Sátánì tún fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé irọ́ ló ń pa nígbà tó sọ pé wọ́n á kú tí wọ́n bá jẹ èso náà. Éfà gbà Sátánì gbọ́. Ló bá já díẹ̀ lára èso náà, ó sì jẹ ẹ́. Ó tún fún ọkọ rẹ̀ náà, òun náà sì jẹ ẹ́. Wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tí wọ́n ṣe yìí ni o. Nígbà tí wọ́n ń jẹ èso náà, wọ́n mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run sọ pé àwọn kò gbọ́dọ̀ ṣe làwọ́n ń ṣe. Bí wọ́n ṣe jẹ èso yẹn, ńṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí òfin tí kò ṣòro láti pa mọ́ tó sì mọ́gbọ́n dání. Wọn ò bọ̀wọ̀ fún Bàbá wọn ọ̀run wọn ò sì pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Kò sí àwíjàre kankan tí wọ́n lè wí bí wọn ò ṣe bọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wọn onífẹ̀ẹ́ yìí!
búburú.” (12. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí Ádámù àti Éfà mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí i?
12 Àpèjúwe kan rèé: Tó o bá mójú tó ọmọ kan dáadáa, tó o forí ṣe tó o fọrùn ṣe láti tọ́ ọ dàgbà, tọ́mọ ọ̀hún sì wá dàgbà tán, tó wá ṣàìgbọràn sí ọ lọ́nà to fi hàn pé kò bọ̀wọ̀ fún ọ kò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ? Ó máa bà ọ́ nínú jẹ gan-an ni, àbí? Wá fojú inú wo bó ṣe dun Jèhófà tó nígbà tí Ádámù àti Éfà mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí i.
13. Kí ni Jèhófà sọ pé yóò ṣẹlẹ̀ sí Ádámù tó bá kú, kí sì ni ìyẹn túmọ̀ sí?
13 Kò sídìí tó fi yẹ kí Jèhófà jẹ́ kí Ádámù àti Éfà aláìgbọràn wà láàyè títí láé. Nítorí náà, bó ṣe sọ fún wọn tẹ́lẹ̀, wọ́n kú. Ádámù àti Éfà di aláìsí. Ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí kọ́ ni wọ́n lọ. Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ lohun tí Jèhófà sọ fún Ádámù nígbà tó pè é wá jẹ́jọ́ ìwà àìgbọràn tó hù. Ọlọ́run sọ pé: “Ìwọ yóò . . . padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde. Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Erùpẹ̀ ilẹ̀ ni Ọlọ́run fi dá Ádámù. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Ṣáájú ìgbà yẹn, Ádámù ò sí níbì kankan. Nítorí náà, nígbà tí Jèhófà sọ fún Ádámù pé yóò padà sínú erùpẹ̀, ohun tó ní lọ́kàn ni pé Ádámù yóò padà sí ipò àìsí níbikíbi. Ádámù yóò di aláìlẹ́mìí bí erùpẹ̀ tí Ọlọ́run fi dá a.
14. Kí nìdí tá a fi ń kú?
14 Ká ní Ádámù àti Éfà ò bá ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ ni, wọ́n ì bá wà láàyè lónìí. Ìdí tá a fi ń kú ni pé ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù àti ikú rẹ̀ ran gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀. (Ka Róòmù 5:12) A lè fí ẹ̀ṣẹ̀ yẹn wé àrùn burúkú kan táwọn èèyàn ń jogún tí kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀. Àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ ni ikú, ègún sì ló jẹ́. Ọ̀tá ni ikú jẹ́, kì í ṣe ọ̀rẹ́. (1 Kọ́ríńtì 15:26) A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà pèsè ìràpadà ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ọ̀tá yìí!
ÀǸFÀÀNÍ WÀ NÍNÚ KÉÈYÀN MỌ ÒTÍTỌ́ NÍPA IPÒ TÁWỌN ÒKÚ WÀ
15. Kí nìdí tí mímọ òtítọ́ nípa ipò táwọn òkú wà fi ń tuni nínú?
15 Ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ipò táwọn òkú wà ń tuni nínú. Bá a ti ṣe rí i, ara kì í ro àwọn òkú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í banú jẹ́. Kò sídìí tó fi yẹ ká máa bẹ̀rù wọn nítorí pé wọn ò lè pa wá lára. A ò lè ràn wọ́n lọ́wọ́, àwọn náà ò sì lè ràn wá lọ́wọ́. A ò lè bá wọn sọ̀rọ̀, àwọn náà ò sì lè bá wa sọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ló ń sọ pé àwọn lè ran àwọn tó ti kú lọ́wọ́, àwọn tó sì gbà pé wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ ń fún wọn lówó. Ṣùgbọ́n téèyàn bá mọ òtítọ́ nípa ipò táwọn òkú wà, àwọn tó ń fi irú irọ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ni ò ní lè tanni jẹ.
16. Ẹ̀kọ́ ta ni ọ̀pọ̀ ìsìn ti mú mọ́ ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni, kí sì ni èrò tó ń jẹ́ kí wọ́n ní?
16 Ǹjẹ́ ìsìn rẹ gba ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ipò táwọn òkú wà gbọ́? Ọ̀pọ̀ ni ò gbà á gbọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ti mú ohun tí Sátánì sọ wọnú ẹ̀kọ́ wọn. Sátánì ń lo ìsìn èké láti fi mú káwọn èèyàn máa rò pé tí wọ́n bá kú, ara wọn nìkan ló kú, pé wọ́n á tún máa wà láàyè nìṣó ní ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí. Irọ́ yìí àtàwọn irọ́ mìíràn ni Sátánì ń lò láti fi mú káwọn èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?
17. Kí nìdí tí ẹ̀kọ́ ìdálóró ayérayé fi tàbùkù sí Jèhófà?
17 Bá a ṣe rí i ní ìpínrọ̀ kẹta, àwọn ẹ̀sìn kan ń kọ́ni pé tẹ́nì kan bá gbé ìgbé ayé olubi, tó bá kú, inú iná tí yóò ti máa joró títí láé ló ń lọ. Ẹ̀kọ́ yìí tàbùkù sí Ọlọ́run. Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà kò sì ní fìyà jẹ èèyàn lọ́nà yìí láéláé. (Ka 1 Jòhánù 4:8) Kí lo máa rò nípa ọkùnrin kan tó fẹ́ fìyà jẹ ọmọ rẹ̀ tó wá jẹ́ pé ńṣe ló ki ọwọ́ rẹ̀ bọ iná, tó sì dì í mú síbẹ̀? Ṣé wàá fojú èèyàn rere wo onítọ̀hún? Ǹjẹ́ wàá tiẹ̀ fẹ́ sún mọ́ irú ẹni yẹn? Ó dájú pé o ò ní fẹ́ sún mọ́ ọn! Ìkà ẹ̀dá lo máa ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ sí. Bẹ́ẹ̀ ohun tí Sátánì ń wá nìyẹn, ó fẹ́ ká gbà pé Jèhófà yóò dá àwọn èèyàn lóró nínú iná fún ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún!
18. Orí ẹ̀kọ́ èké wo ni ìjọsìn àwọn òkú dá lé?
18 Sátánì tún ń lo àwọn ìsìn kan láti kọ́ àwọn èèyàn pé téèyàn bá kú, ńṣe ni yóò di ẹni ẹ̀mí tó yẹ káwọn èèyàn máa bu ọ̀wọ̀ àti ọlá fún. Ẹ̀kọ́ yìí sọ pé, ẹ̀mí àwọn òkú lè di ọ̀rẹ́ tó ń ranni lọ́wọ́ tàbí ọ̀tá tí ń dẹ́rù bani. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì gbà irọ́ yìí gbọ́. Wọ́n máa ń bẹ̀rù àwọn òkú wọ́n sì máa ń bu ọlá fún wọn. Wọ́n tún máa ń jọ́sìn wọn. Àmọ́ o, Bíbélì fi kọ́ni ni pé ńṣe làwọn òkú ń sùn, àti pé Jèhófà, tí í ṣe Ọlọ́run tòótọ́, Ẹlẹ́dàá wa tó ń pèsè fún wa nìkan la gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn.—19. Ẹ̀kọ́ Bíbélì mìíràn wo ni a ó mọ̀ tá a bá mọ òtítọ́ nípa ipò tí àwọn òkú wà?
19 Tó o bá mọ òtítọ́ nípa ipò tí àwọn òkú wà, ẹnì kankan ò ní lè fi ẹ̀kọ́ èké ṣì ọ́ lọ́nà. Á tún jẹ́ kó o mọ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá mọ̀ pé àwọn èèyàn kì í lọ sí ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí tí wọ́n bá kú, ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé yóò túbọ̀ jẹ́ ohun gidi sí ọ.
20. Ìbéèrè wo lá óò gbé yẹ̀ wò nínú orí tó kàn?
20 Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ọkùnrin olódodo nì, Jóòbù, béèrè ìbéèrè kan pé: “Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?” (Jóòbù 14:14) Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí èèyàn tí ò lẹ́mìí mọ́, tó ń sùn nínú ikú tún padà wá sí ìyè? Ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa èyí ń tu èèyàn nínú, bí orí tó tẹ̀ lé e yóò ṣe fi hàn.
^ ìpínrọ̀ 5 Wo àlàyé lórí àwọn ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn” àti “ẹ̀mí” nínú Àfikún, “Kí Ni “Ọkàn” àti “Ẹ̀mí” Jẹ́ Gan-an?”.