Ọkàn
Báwo la ṣe mọ̀ pé tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “ọkàn,” ó túmọ̀ sí ẹni tá a jẹ́ nínú ìyẹn àwọn nǹkan tá à ń rò, ìwà àti ìṣe wa, àwọn nǹkan tá a fẹ́ ṣe àti bí nǹkan ṣe rí lára wa?
Sm 49:3; Owe 16:9; Lk 5:22; Iṣe 2:26
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Lk 9:46-48—Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wí torí ó rí i nínú ọ̀kan wọn pé wọ́n ń fẹ́ ipò ọlá
-
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa dáàbò bo ọkàn wa?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Jẹ 6:5-7—Jèhófà rí i pé ohun búburú nìkan làwọn èèyàn ń rò lọ́kàn tíyẹn sì ń mú kí wọ́n máa hùwà ipá, torí náà Jèhófà fi Ìkún Omi pa wọ́n run
-
1Ọb 11:1-10—Ọba Sólómọ́nì ò dáàbò bo ọkàn rẹ̀, ó fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì, wọ́n sì mú kí ọkàn rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà
-
Mk 7:18-23—Jésù ṣàlàyé pé látinú ọkàn ni gbogbo nǹkan burúkú tó lè sọ èèyàn di aláìmọ́ ti ń wá
-
Báwo la ṣe lè dáàbò bo ọkàn wa?
Sm 19:14; Owe 3:3-6; Lk 21:34; Flp 4:8
Tún wo Ẹsr 7:8-10; Sm 119:11
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Ef 6:14-18; 1Tẹ 5:8—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé bí àwo ìgbàyà ṣe máa ń dáàbò bo ọkàn ọmọ ogun kan, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìlànà òdodo Jèhófà, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ ṣe máa ń dáàbò bo èrò inú wa, ìyẹn ẹni tá a jẹ́ gan-an.
-
Kí ló máa jẹ́ ká mọ̀ pé ọkàn wa ti ń kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà?
Tún wo Owe 6:12-14
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
2Kr 25:1, 2, 17-27—Ọba Amasááyà ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run fúngbà díẹ̀, àmọ́ kì í ṣe pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀; nígbà tó yá ó di agbéraga, ó ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó sì jìyà àwọn nǹkan tó ṣe
-
Mt 7:17-20—Jésù jẹ́ ká rí i pé bí igi tó ti jẹrà ṣe máa ń so èso tí kò ní láárí, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé téèyàn bá ti ń ní èrò burúkú nínú ọkàn rẹ̀, á máa ṣe nǹkan burúkú
-
Kí nìdí tó fi yẹ ká gbìyànjú láti ní ọkàn tó dáa, báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
Tún wo Sm 119:97, 104; Ro 12:9-16; 1Ti 1:5
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
2Ọb 20:1-6—Ọba Hẹsikáyà jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ó sì fi gbogbo ọkàn ẹ̀ sìn ín, torí náà nígbà tó ṣàìsàn tó sì fẹ́ kú, ó bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́
-
Mt 21:28-32—Jésù lo àpèjúwe kan láti jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá fẹ́ mọ nǹkan tó wà nínú ọkàn ẹnì kan, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni àwọn nǹkan tẹ́ni náà ń ṣe, kì í ṣe àwọn nǹkan tó sọ pé òun máa ṣe
-
Kí nìdí tọ́kàn wa fi balẹ̀ pé Jèhófà mọ ohun tó wà lọ́kàn wa?
Tún wo 1Sa 2:3
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
1Sa 16:1-13—Wòlíì Sámúẹ́lì rí i pé kì í ṣe bá a ṣe rí ló ṣe pàtàkì sí Jèhófà; dípò ìyẹn, ohun tó wà nínú ọkàn wa ló ń wò
-
2Kr 6:28-31—Àdúrà tí Ọba Sólómọ́nì gbà nígbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń gba tiwa rò torí pé ó mọ ohun tó wà lọ́kàn wa, ọ̀rọ̀ wa sì yé e
-