Ẹ̀ṣẹ̀
Kí ni ẹ̀ṣẹ̀, kí sì nìdí tó fi jẹ́ pé gbogbo wa ni ẹlẹ́ṣẹ̀?
Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó máa ń mú ká dẹ́ṣẹ̀?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
2Sa 11:2-5, 14, 15, 26, 27; 12:1-13—Ọba Dáfídì dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, Ọlọ́run bá a wí, ó sì ṣiṣẹ́ kára kó lè ṣàtúnṣe
-
Ro 7:15-24—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù nígbàgbọ́ tó lágbára, tó sì ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, ó ṣì ní láti máa ṣiṣẹ́ kára kó lè borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́
-
Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń dẹ́ṣẹ̀?
Kí nìdí tí kò fi yẹ kéèyàn máa mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tí kò dáa?
Àwọn nǹkan wo ni Sátánì lè fi dẹkùn mú àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run?
Owe 1:10, 11, 15; Mt 5:28; Jem 1:14, 15
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Jẹ 3:1-6—Sátánì lo ejò kan láti bá Éfà sọ̀rọ̀, ohun tí ejò náà sọ mú kó wu Éfà láti tẹ́ ara ẹ̀ lọ́rùn, ìyẹn ò sì jẹ́ kó fọkàn tán Jèhófà mọ́
-
Owe 7:6-10, 21-23—Ọba Sólómọ́nì sọ̀rọ̀ nípa bí ọ̀dọ́kùnrin kan tí kò ní làákàyè ṣe kó sọ́wọ́ obìnrin oníwàkiwà kan
-
Kí la lè ṣe tá ò fi ní kó sínú ìdẹwò Sátánì?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Owe 5:1-14—Jèhófà mí sí Ọba Sólómọ́nì pé kó fún wa nímọ̀ràn ọlọ́gbọ́n nípa ìdí tó fi yẹ ká sá fún ìṣekúṣe àti bá a ṣe lè sá fún un
-
Mt 4:1-11—Jésù gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn sì mú kó borí ìdẹwò Sátánì
-
Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an tó yẹ káwa Kristẹni sá fún?
Wo “Àṣà Burúkú”
Ó yẹ ká jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká bo ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀?
Ta ló yẹ ká jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún?
Ta ni “olùrànlọ́wọ́” tó ń bá wa bẹ̀bẹ̀ níwájú Jèhófà?
Báwo ni ẹlẹ́ṣẹ̀ kan ṣe lè fi hàn pé òun ti ronú pìwà dà lóòótọ́?
Tún wo “Ìrònúpìwàdà”
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Ẹk 22:1-12—Òfin Mósè sọ pé tẹ́nì kan bá jalè, ó gbọ́dọ̀ san àwọn nǹkan kan láti fi dípò ohun tó jí náà
-
Lk 19:8, 9—Sákéù tó jẹ́ olórí àwọn agbowó orí fi hàn pé òun ronú pìwà dà nígbà tó ṣe àwọn àtúnṣe kan, tó sì dá ohun tó fipá gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn pa dà fún wọn
-
Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà máa dárí jì wá?
Wo “Ìdáríjì”
Àwọn wo ni Jèhófà sọ pé kí wọ́n máa ran àwọn tó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an lọ́wọ́ kí wọ́n sì dáàbò bo ìjọ?
Tún wo Iṣe 20:28; Ga 6:1
Tẹ́nì kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, àkóbá wo ló lè ṣe fún ìdílé ẹ̀ àti ìjọ?
Tún wo Di 29:18
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Joṣ 7:1-13, 20-26—Nígbà tí Ákánì dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, ó gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀, ó sì fi tiẹ̀ kó bá gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù
-
Jon 1:1-16—Torí pé wòlíì Jónà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó fi ẹ̀mí òun àtàwọn tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀ òkun sínú ewu
-
1Kọ 5:1-7—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa arákùnrin kan tó dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an ní ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì, tíyẹn sì ṣàkóbá fún gbogbo ìjọ
-
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà lè bá wa wí tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù láti lọ bá wọn pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́?
Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ pé Ọlọ́run ti dárí jì wá, dípò ká máa banú jẹ́ torí ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn?
Wo “Ìdáríjì”
Tá a bá mọ̀ pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, kí nìdí tó fi yẹ ká rí i pé onítọ̀hún lọ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn alàgbà?
-
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
-
Di 13:6-9; 21:18-20—Òfin Mósè sọ pé tí mọ̀lẹ́bí ẹnì kan tàbí ẹlòmíì tó sún mọ́ ọn bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, ẹni náà gbọ́dọ̀ lọ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn àgbààgbà
-