Bá A Ṣe Lè Yanjú Èdèkòyédè
Tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá, kí nìdí tí kò fi yẹ ká bínú jù tàbí ká gbẹ̀san?
Owe 20:22; 24:29; Ro 12:17, 18; Jem 1:19, 20; 1Pe 3:8, 9
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
1Sa 25:9-13, 23-35—Nígbà tí Nábálì fàbùkù kan Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀, tí kò sì fún wọn láwọn nǹkan tó yẹ kó fún wọn, ńṣe ni Dáfídì sọ pé òun máa pa Nábálì àti gbogbo ọkùnrin tó wà nílé ẹ̀, àmọ́ Ábígẹ́lì fún un ní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí kò jẹ́ kó di apààyàn
Owe 24:17-20—Jèhófà mí sí Ọba Sólómọ́nì láti kìlọ̀ fáwa èèyàn Ọlọ́run pé Jèhófà ò fẹ́ ká máa dunnú tí ọ̀tá wa bá ṣubú; ńṣe ló yẹ ká fi ìdájọ́ àwọn ẹni ibi lé Jèhófà lọ́wọ́
Táwọn Kristẹni kan bá ṣẹ ara wọn, ṣó yẹ kí wọ́n di ara wọn sínú tàbí kí wọ́n má ṣe kí ara wọn mọ́?
Le 19:17, 18; 1Kọ 13:4, 5; Ef 4:26
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Mt 5:23, 24—Jésù sọ pé tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ní ohun kan lòdì sí wa, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ láti yanjú ọ̀rọ̀ náà kí àlàáfíà lè jọba
Kí ló yẹ ká ṣe tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá?
Tẹ́nì kan bá tiẹ̀ ṣẹ̀ wá léraléra, kí nìdí tó fi yẹ ká dárí jì í tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn?
Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣe ohun tó dùn wá kọjá ohun tá a lè mú mọ́ra, bóyá ńṣe ló bà wá lórúkọ jẹ́ tàbí ó lù wá ní jìbìtì, ta ló yẹ kó bá a sọ̀rọ̀, kí sì nìdí?
Tí ẹni tó bà wá lórúkọ jẹ́ tàbí tó lù wá ní jìbìtì kò bá ronú pìwà dà nígbà táwa nìkan bá a sọ̀rọ̀, kí ló yẹ ká ṣe?