Kikẹkọọ Lati Inu Awọn Ìdẹwò Jesu
Orí 13
Kikẹkọọ Lati Inu Awọn Ìdẹwò Jesu
KETE lẹhin baptisi rẹ̀, ẹmi Ọlọrun dari Jesu lọ sí aginjú Judia. Oun ni ọpọlọpọ nǹkan lati ronu le lori, nitori nigba baptism rẹ̀ “ọrun ṣí sílẹ̀” ki oun baa lè wòyemọ̀ awọn nǹkan ti ọrun. Nitootọ, pupọ wà fun un lati ṣe àṣàrò lé lori!
Jesu lò 40 ọjọ́ ati 40 òru ninu aginju, kò sì jẹ ohunkohun laaarin akoko yii. Lẹhin naa, nigba ti ebi npa Jesu gidigidi, Eṣu tọ̀ ọ́ wá lati dẹ ẹ́ wò, ni wiwi pe: “Bi iwọ ba nṣe ọmọ Ọlọrun, pàṣẹ ki òkúta wọnyi di àkàrà.” Ṣugbọn Jesu mọ̀ pe kò tọna lati lo awọn agbara iṣẹ iyanu rẹ̀ lati tẹ́ ifẹ-ọkan ara ẹni tirẹ̀ lọ́rùn. Nitori naa kò jẹ ki a dẹ oun wò.
Ṣugbọn Eṣu kò juwọsilẹ. Oun gbiyanju ọna ìyọsíni miiran. O pè Jesu níjà lati bẹ́ lati orí ògiri tẹmpili kí awọn angẹli Ọlọrun lè yọ ọ́ ninu ewu. Ṣugbọn Jesu ni a kò dẹwò lati ṣe iru àṣehàn oníran àpéwò bẹẹ. Ní fifa ọ̀rọ̀ yọ lati inu Iwe Mimọ, Jesu fihan pe kò tọna lati dán Ọlọrun wò lọna yii.
Ninu ìdẹwò kẹta, Eṣu fi gbogbo ijọba aye hàn Jesu lọna iyanu kan ó sì wipe: “Gbogbo nǹkan wọnyi ni emi yoo fifun ọ, bi iwọ ba wolẹ, ti o sì foribalẹ fun mi.” Ṣugbọn lẹẹkan sii Jesu kọ̀ lati juwọsilẹ fun ìdẹwò lati ṣe ohun tí kò tọ̀nà, ó yàn lati duro bi oloootọ sí Ọlọrun.
Awa lè kẹ́kọ̀ọ́ lati inú awọn ìdẹwò Jesu wọnyi. Wọn fihan, fun apẹẹrẹ, pe Eṣu kii wulẹ ṣe animọ iwa ibi lasan kan, gẹgẹ bi awọn eniyan kan ṣe sọ, ṣugbọn pe oun jẹ́ ẹni gidi kan tí kò ṣee fi oju rí. Ìdẹwò Jesu tún fihan pe gbogbo awọn ijọba ayé jẹ́ ohun ini Eṣu. Nitori bawo ni fífi tí Eṣu fi wọn lọ Jesu ti lè jẹ́ ìdẹwò gidi kan bí wọn kò ba jẹ tirẹ niti gidi?
Sì ro eyi wò ná: Eṣu sọ pe oun ṣetan lati san ẹsan fun Jesu fun iṣe ijọsin kanṣoṣo, àní kí ó tilẹ fun un ní gbogbo ijọba aye. Eṣu lè gbiyanju bakan naa lati dẹ wá wò lọna ti o jọra pẹlu eyi, boya kí ó gbé awọn ire anfaani ti a fi ńyánni lójú wá siwaju wa lati ni ọrọ̀, agbára, tabi ipò ti ayé. Ṣugbọn ẹ wo bi a o ti jẹ́ ọlọgbọ́n tó lati tẹle apẹẹrẹ Jesu nipa diduro bii oloootọ sí Ọlọrun laika ohun yoowu tí ìdẹwò naa lè jẹ́ sí! Matiu 3:16; 4:1-11; Maaku 1:12, 13; Luuku 4:1-13.
▪ Awọn ohun wo ni o farahan gbangba pe Jesu ṣàṣàrò lé lori nigba ti o fi wà ní aginju fun 40 ọjọ́?
▪ Bawo ni Eṣu ṣe gbiyanju lati dẹ Jesu wò?
▪ Ki ni a lè kẹkọọ lati inú awọn ìdẹwò Jesu?